Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 55


Orí 55

Mórónì kọ̀ láti ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú—Nwọ́n tan àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ará Lámánì láti mu ọtí yó, àwọn ará Nífáì tí a kó lẹ́rú sì di òmìnira—A mú ìlú-nlá Gídì láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 63 sí 62 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti gba ìwé yìi o binu sĩ ju tatẹhínwa, nítorípé ó mọ̀ wípé Ámmórọ́nì ní ìmọ̀ pípé lórí ìwà àrekérekè ara rẹ̀; bẹ̃ni, ó mọ̀ wípé Ámmórọ́nì mọ̀ pé kìi ṣe nípa èyítí ó tọ́ ni, kí ó bá àwọn ènìyàn Nífáì jagun.

2 Ó sì wípé: Kíyèsĩ, èmi kì yíò ṣe pàṣípàrọ̀ àwọn tí a kó lẹ́rú pẹ̀lú Ámmórọ́nì àfi tí ó bá dawọ ète rẹ̀ dúró, gẹ́gẹ́bí èmi ti wí nínú ọ̀rọ̀ mi; nítorítí èmi kò ní gbà fún un láti ní agbára ju èyítí ó ti ní.

3 Kíyèsĩ, èmi mọ́ ibití àwọn ará Lámánì ti nṣọ́ àwọn ènìyàn mi tí nwọ́n ti kó lẹ́rú; nítorípé Ámmórọ́nì kò sì fifúnmi gẹ́gẹ́bí èmi ti bẽrè nínú ọ̀rọ̀ mi, kíyèsĩ, èmi yíò fifún un gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ; bẹ̃ni, èmi yíò lépa ikú lãrín wọn, títí nwọn ó fi bẹ̀bẹ̀ fún àlãfíà.

4 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Mórónì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ, ó mú kí nwọn ṣe ìwákiri lãrín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, pé bóyá òun yíò rí ẹnìkan tĩ ṣe àtẹ̀lé Lámánì lãrín nwọn.

5 Ó sì ṣe tí nwọ́n rí ẹnìkan, tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ Lámánì; ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ ọba tí Amalikíà pa.

6 Nísisìyí Mórónì mú kí Lámánì àti díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tọ àwọn ẹ̀ṣọ́ tí nṣọ́ àwọn ará Nífáì tí a kó lẹ́rú lọ.

7 Ní báyĩ inú ìlú-nlá Gídì ni nwọ́n ti nṣọ́ àwọn ará Nífáì nnì tí a kó lẹ́rú; nítorínã ni Mórónì ṣe yan Lámánì tí ó sì mú kí díẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀.

8 Nígbàtí ó sì di àṣálẹ́ Lámánì tọ àwọn ẹ̀ṣọ́ tí nṣọ́ àwọn ará Nífáì nã lọ, ẹ sì kíyèsĩ, nwọ́n ríi tí ó nbọ̀ nwọ́n sì kíi lókẽrè; ṣùgbọ́n ó wí fún nwọn pé: Ẹ máṣe bẹ̀rù; ẹ kíyèsĩ, ará Lámánì ni èmi í ṣe. Ẹ kíyèsĩ, àwa ti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Nífáì, nwọ́n sì nsùn; ẹ sì kíyèsĩ àwa ti bù nínú ọtí nwọn a sì gbée wá.

9 Nísisìyí nígbàtí àwọn ará Lámánì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nwọ́n gbã pẹ̀lú ayọ̀; nwọ́n sì wí fún un pe: Ẹ fún wa nínú ọtí nyín, kí àwa ó mu; inú wa dùn pé ẹ̀yin gbé ọtí wá lọ́nà yĩ nítorítí àwa nṣe ãrẹ̀.

10 Ṣùgbọ́n Lámánì wí fún nwọn pé: Ẹ jẹ́ kí a fi pamọ́ nínú ọtí wa títí àwa yíò fi kọlũ àwọn ará Nífáì ní ogun. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ yĩ túbọ̀ mú nwọn ní ìfẹ́ síi láti mu nínú ọtí nã.

11 Nítorítí nwọ́n wípé: Àwa nkãrẹ̀, nítorínã ẹ jẹ́ kí a mu nínú ọtí nã, àti pé láìpẹ́ àwa yíò gba ọtí tiwa, èyítí yíò fún wa lágbára láti lọ íkọlu àwọn ará Nífáì.

12 Lámánì sì wí fún nwọn pé: Ẹ̀yin lè ṣe gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nyín.

13 Ó sì ṣe tí nwọ́n mu nínú ọtí nã lọ́pọ̀lọpọ̀; ó sì dùn mọ́ nwọn lẹ́nu, nítorínã ni nwọ́n ṣe mu síi; ọtí lílé sì ni í ṣe, nítorií nwọ́n ṣeé kí ó le.

14 Ó sì ṣe tí nwọ́n mu tí nwọ́n sì nyọ̀, tí gbogbo nwọn sì mutí yó láìpẹ́.

15 Àti nísisìyí nígbàtí Lámánì àti àwọn ará rẹ̀ ríi pé gbogbo nwọn ti mutí yó, tí nwọn sì ti sùn lọ, nwọ́n padà sọ́dọ̀ Mórónì nwọ́n sì sọ gbogbo àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ fun.

16 Àti nísisìyí èyí sì wà ní ìbámu pẹ̀lú èrò Mórónì. Mórónì sì ti ṣe ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun ìjà-ogun; ó sì lọ sí ìlú-nlá Gídì, nígbàtí àwọn ará Lámánì wà nínú orun tí nwọ́n sì ti mutí yó, nwọ́n sì ju àwọn ohun ìjà-ogun sí àwọn ènìyàn tí a kó lẹ́rú, tóbẹ̃ tí gbogbo nwọn fi di ìhámọ́ra ogun;

17 Bẹ̃ni, àní sí àwọn obìnrin nwọn, àti gbogbo àwọn ọmọ nwọn, gbogbo àwọn tí nwọ́n bá lè lo ohun ìjà-ogun, nígbàtí Mórónì ti di ìhámọ́ra ogun fún àwọn tí a kó lẹ́rú nã; gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ni nwọ́n sì ṣe ní ìdákẹ́rọ́rọ́.

18 Ṣùgbọ́n bí nwọn bá tilẹ̀ ta àwọn ará Lámánì nã jí, kíyèsĩ nwọ́n ti mutí yó àwọn ará Nífáì ìbá sì pa nwọ́n.

19 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èyí kì í ṣe ìfẹ́ inú Mórónì; kò dunnú sí ìpànìyàn tàbí ìtàjẹ̀sílẹ̀, ṣùgbọ́n ó dunnú sí gbígba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò nínú ìparun; nítorí kí ó má bã bọ́ sínú ipò àìṣòdodo, oun kò ní kọlũ àwọn ará Lámánì kí ó sì pa nwọ́n run nínú ipò ìmutípara tí nwọ́n wà.

20 Ṣùgbọ́n ó ti rí ìfẹ́ inú rẹ̀ gbà; nítorítí ó ti fi ìhámọ́ra ogun di àwọn ará Nífáì tí nwọ́n kó lẹ́rú tí nwọ́n wà nínú odi ìlú-nlá nã, ó sì ti fún nwọn lágbára láti mú àwọn apá ìlú-nlá nã tí ó wà nínú odi ìlú nã.

21 Nígbànã ni ó sì mú kí àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kí nwọ́n padà sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ nwọn, kí nwọ́n sì ká àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì mọ́.

22 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ nwọ́n ṣe eleyĩ ní òru, tí ó sì jẹ́ wípé nígbàtí àwọn ará Lámánì jí ní òwúrọ̀ nwọ́n ríi pé àwọn ará Nífáì ti ká nwọn mọ́ ní ìta, àti pé àwọn ẹrú nwọn ti di ìhámọ́ra ogun nínú odi ìlú-nlá nã.

23 Báyĩ ni nwọ́n sì ríi pé àwọn ará Nífáì ní agbára lórí nwọn; àti nínú ipò yìi nwọ́n ríi pé kò yẹ kí àwọn ó bá àwọn ará Nífáì jà; nítorínã ni àwọn olórí ológun nwọn ṣe pàṣẹ kí nwọn kó ohun ìjà ogun nwọn lélẹ̀, nwọ́n sì kó nwọn wá síwájú, nwọn si jù nwọn sí ibi ẹsẹ àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì bẹ̀bẹ̀ fún ãnú.

24 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni ìfẹ́ inú Mórónì. Ó kó nwọn lẹ́rú, ó sì mú ìlú-nlá nã, ó sì mú kí a tú àwọn tí a ti kó lẹ́rú sílẹ̀ tí nwọ́n jẹ́ ará Nífáì; nwọ́n sì dàpọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì, nwọ́n sì jẹ́ agbára púpọ̀ fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀.

25 Ó sì ṣe tí ó mú kí àwọn ará Lámánì tí ó kó lẹ́rú bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣíṣe láti fi agbára kún àwọn odi tí nwọ́n ti mọ́ kãkiri ìlú-nlá Gídì.

26 Ó sì ṣe nígbàtí ó ti mọ́ odi yí ìlú-nlá Gídì tán, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú rẹ ó mú kí nwọ́n kó àwọn tí a kó lẹ́rú nã lọ sí ìlú-nlá Ibi-Ọ̀pọ̀; ó sì fi àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó lágbára púpọ̀ ṣọ́ ibẹ̀.

27 Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣe ìpamọ́ atí ìdãbò bò gbogbo àwọn tí a kó lẹ́rú tí nwọ́n ti mú, l’áìṣírò àwọn ará Lámánì ngbìmọ̀, nwọ́n sì tún di gbogbo àwọn ilẹ̀ ati awọn ánfãní nwọn mú èyítí nwọ́n ti gbà padà.

28 Ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì tún bẹ̀rẹ̀sí nṣẹ́gun, àti láti gba ẹ̀tọ́ àti ìní nwọn padà.

29 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn ará Lámánì sì gbìdánwò láti ká nwọ́n mọ́ ní òru, ṣùgbọ́n nínú àwọn àbá wọ̀nyí ni nwọ́n ti pàdánù púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn ti nwọn kólẹ́rú.

30 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni nwọ́n sì gbìdánwò láti fifún àwọn ará Nífáì mu nínú ọtí nwọn, láti lè pa nwọ́n run pẹ̀lú májèlé tàbí pẹ̀lú ìmutípara.

31 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ará Nífáì ṣe kánkán láti rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn ni àkokò ìpọ́njú nwọn yĩ. Nwọn kò rí nwọn mú nínú ìkẹ́kùn nwọn; bẹ̃ni, nwọ́n kọ̀ láti mu nínú ọtí nwọn, àfi bí nwọ́n bá ti kọ́kọ́ fún nínú àwọn ará Lámánì tí a kó lẹ́rú mu nínú rẹ̀.

32 Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe ìjáfáfá pé kí ẹnikẹ́ni máṣe fún nwọn ní májèlé mu lãrín nwọn; nítorípé bí ọtí nwọn bá fi májèlé pa ará Lámánì kan yíò pa ará Nífáì kan pẹ̀lú; báyĩ si ni nwọ́n ndán gbogbo ọtí nwọn wò.

33 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí ó tọ́ fún Mórónì láti ṣe ìmúrasílẹ̀ láti kọlũ ìlú-nlá Móríátọ́nì; nítorí kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì, nípa ipá nwọn, ti dãbò bò ìlú-nlá Mọ́ríátọ́nì títí ó fi di ibi ìsádi tí o lágbára púpọ̀.

34 Nwọ́n sì tẹ̀síwájú nípa kíkó àwọn ọmọ ogun lákọ̀tun wá sínú ìlú-nlá nnì, àti àwọn ìpèsè oúnjẹ lákọ̀tun.

35 Báyĩ sì ni ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n parí nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

Tẹ̀