Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 29


Orí 29

Álmà fẹ́ láti kígbe ìpè ìrònúpìwàdà pẹ̀lú ìtara bí ti ángẹ́lì—Olúwa fún gbogbo orílẹ̀-èdè ní àwọn olùkọ́ni—Álmà ṣògo nínú iṣẹ́ Olúwa àti nínú àṣeyọrí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 76 kí a tó bí Olúwa wa.

1 A! báwo ni ó ti wù mí tó kí èmi jẹ́ ángẹ́lì, ìba sì bá ìfẹ ọkàn mi mu kí èmi lè kọjá lọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú fèrè Ọlọ́run, àti ohùn tí yíò mi gbogbo ayé, kí èmi kí ó sì kígbe ìpè ìrònúpìwàdà sí ènìyàn gbogbo!

2 Bẹ̃ni, èmi yíò kéde ìrònúpìwàdà àti ìlànà ìràpadà sí gbogbo ọkàn, bí sísán àrá, pé kí nwọ́n ronúpìwàdà, kí nwọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí ìbànújẹ́ má lè wà mọ́ ní orí ilẹ̀ àgbáyé.

3 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ènìyàn ni èmi í ṣe, èmi sì ndẹ́ṣẹ̀ nínú ìfẹ́-inú mi; nítorípé ó yẹ kí èmi ní ìtẹ́lọ́rùn nínú àwọn ohun ti Olúwa ti ṣe fún mi.

4 Kò tọ́ fún mi láti gbèrò nínú ìfẹ́-inú mi fún ìyípadà òfin Ọlọ́run tí ó tọ́, nítorítí èmi mọ̀ pé òun a máa ṣe fún ènìyàn gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú wọn yálà sí ti ikú tàbí ti ìyè; bẹ̃ ni, èmi mọ̀ pé òun a máa ṣe fún ènìyàn, bẹ̃ni, ó fún nwọn ní àwọn òfin tí a kò le yípadà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-inú nwọn, yálà sí ti ìgbàlà, tàbí sí ti ìparun.

5 Bẹ̃ni, èmi mọ̀ wípé ohun dáradára àti ohun búburú ti wá níwájú gbogbo ènìyàn; ẹnití kò bá dá èyítí ó dára mọ̀ kúrò lára èyítí ó burú kò lẹ́bi; ṣùgbọ́n ẹnití ó bá mọ́ èyítí ó dára àti èyítí ó burú, òun ni a ó fun gẹ́gẹ́bí ìfẹ́-inú rẹ̀, bóyá ó fẹ́ dáradára tàbí búburú, ìyè tàbí ikú, ayọ̀ tàbí ẹ̀dùn ọkàn.

6 Nísisìyí, nígbàtí èmi sì ti mọ́ ohun wọ̀nyí, kíni èmi ṣe tún fẹ́ láti ṣe ju iṣẹ́ èyítí a ti pè mí fún?

7 Kíni èmi ṣe fẹ́ láti jẹ́ ángẹ́lì, kí èmi lè sọ̀rọ̀ dé gbogbo ikangun áyé?

8 Nítorí kíyèsĩ, Olúwa a máa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, ní ti orílẹ̀-èdè ati èdè tiwọn, fún kíkọ́ni ní ọ̀rọ̀ rẹ̀, bẹ̃ni, nínú ọgbọ́n, gbogbo àwọn ohun èyítí ó ríi pé ó tọ́ kí nwọn ní; nítorínã àwa ríi pé Olúwa a máa gbani níyànjú nínú ọgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú èyítí ó tọ́ tí ó sì jẹ́ òtítọ́.

9 Èmi mọ́ ohun èyítí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi, èmi sì ṣògo nínú rẹ̀. Èmi kò ṣògo nínú ara mi, ṣùgbọ́n èmi ṣògo nínú ohun èyítí Olúwa ti pa láṣẹ fún mi; bẹ̃ni, èyí sì ni ògo mi, pé bóyá èmi lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti mú ọkàn àwọn díẹ̀ wá sí ìrònúpìwàdà; èyí sì ni ayọ̀ mi.

10 Sì kíyèsĩ, nígbàtí mo bá rí púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin mi pé nwọ́n ti ronúpìwàdà nítoótọ́, tí nwọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, ìgbàyĩ ni ọkàn mi kún fún ayọ̀; tí èmi sì rántí ohun tí Olúwa ti ṣe fún mi, bẹ̃ni, àní tí ó ti gbọ́ àdúrà mi, bẹ̃ni, ìgbànã ni èmi rántí ọwọ́ ãnú rẹ̀ èyítí ó ti nà sí mi.

11 Bẹ̃ni, èmi sì tún rántí ìgbèkùn àwọn bàbá mi; nítorítí èmi mọ̀ dájú pé Olúwa ni ó gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú, nípa èyí ni ó sì ṣe dá ìjọ rẹ̀ sílẹ̀; bẹ̃ni, Olúwa Ọlọ́run, Ọlọ́run Ábráhámù, Ọlọ́run Ísãkì, àti Ọlọ́run Jákọ́bù, tí ó sì gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú.

12 Bẹ̃ni, gbogbo ìgbà ni èmi a máa rántí ìgbèkùn àwọn bàbá mi àti pẹ̀lú pé Ọlọ́run yĩ kannã tí ó gbà wọn lọ́wọ́ àwọn ará Égíptì, ni ó gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú.

13 Bẹ̃ni, Ọlọ́run yĩ kannã ni ó sì dá ìjọ rẹ̀ sílẹ̀ lãrín nwọn; bẹ̃ni, Ọlọ́run yĩ kannã sì ni ó pè mí nípa ìpè mímọ́, láti kéde ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn yĩ, tí ó sì ti fún mi ní àṣeyọrí púpọ̀, nínú èyítí ayọ̀ mi kún.

14 Ṣùgbọ́n, èmi kò yọ̀ nínú àṣeyọrí mi nìkan, ṣùgbọ́n ayọ̀ mi kún síi nítorí àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi, tí nwọ́n ti lọ sí ilẹ̀ Nífáì.

15 Kíyèsĩ, nwọ́n ti ṣiṣẹ́ púpọ̀, nwọ́n sì ti mú èso púpọ̀ jáde wá; báwo sì ni èrè nwọn yíò ti pọ̀ tó!

16 Nísisìyí, nígbàtí mo bá ro ti àṣeyọrí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, a mu ọkan mi fo lọ ani bi i pe a pin niya kuro ní ara mi, bi o ti ri, bee si ni ayọ mí tobi to.

17 Àti nísisìyí, kí Ọlọ́run kí ó sì jẹ́ kí àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí ní ànfàní láti jókõ nínú ìjọba Ọlọ́run; bẹ̃ni, àti gbogbo àwọn tí nwọ́n jẹ́ èrè iṣẹ́ nwọn pẹ̀lú, pé kí nwọ́n má bã bọ́ sí ìta mọ́, ṣùgbọ́n kí nwọn máa yìn ín títí láéláé. Kí Ọlọ́run sì jẹ́ kí ó ṣẽṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, àní gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ. Àmín.