Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 50


Orí 50

Mórónì mọdisí àwọn ilẹ̀ àwọn ará Nífáì—Nwọ́n kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú-nlá titun—Àwọn ogun àti ìparun kọlũ àwọn ará Nífáì ní àwọn ọjọ́ ìwà búburú àti ìwà ìríra nwọn—Mọ́ríátọ́nì àti àwọn olùyapa rẹ̀ ni Tíákúmì borí—Nífáìhà kú, ọmọ rẹ̀ Pahoránì sì bọ́ sí ipò ìtẹ́ ìdájọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 72 sí 67 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Mórónì kò dáwọ́dúró láti ṣe ìmúrasílẹ̀ fún ogun, tàbí láti ṣe ìdábòbò àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì; nítorítí ó mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ kí nwọ́n bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ogún ọdún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, pé kí nwọn ó bẹ̀rẹ̀sí wíwa ilẹ̀ yíká àwọn ìlú-nlá gbogbo, jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ tí àwọn ará Nífáì ní ní ìní.

2 Lórí àwọn òkìtì ilẹ̀ wọ̀nyí ni ó sì ní kí nwọ́n kó àwọn igi lé, bẹ̃ni, àwọn igi nã ni nwọ́n kójọ tó ìwọ̀n gíga ènìyàn, yíká àwọn ìlú-nlá nã.

3 O sì mú kí nwọ́n to àwọn òpó ẹlẹ́nu ṣọ́nṣó lé orí àwọn igi tí nwọ́n tò yíká; nwọn sì ní ágbára nwọ́n sì ga sókè.

4 O sì mú kí nwọ́n kọ́ àwọn ilé ìṣọ́ gíga tí ó dojúkọ àwọn òpó ẹlẹ́nu ṣónṣó nã, ó sì mú kí nwọ́n kọ́ àwọn ibi ãbò lé orí àwọn ilé ìṣọ́ gíga nã, kí àwọn òkúta àti ọfà àwọn ará Lámánì má lè pa nwọ́n lára.

5 Nwọ́n sì ṣe ìmúrasílẹ̀ fún nwọn pé nwọn yíò lè ju òkúta láti orí nwọn, gẹ́gẹ́bí ó bá ti wù nwọ́n àti gẹ́gẹ́bí agbára nwọn, kí nwọn sì pa ẹnití ó bá lèpa láti kọjá sí itòsí àwọn ògiri ìlú-nlá nã.

6 Báyĩ sì ni Mórónì ṣe ìpèsè ibi ãbò ní ìdojúkọ bíbọ̀ àwọn ọ̀tá nwọn, yíká gbogbo ìlú-nlá nínú gbogbo ilẹ̀ nã.

7 O sì ṣe tí Mórónì mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lọ sínú aginjù tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn; bẹ̃ni, nwọ́n sì lọ nwọ́n sì lé gbogbo àwọn ará Lámánì tí ó wà ní aginjù ìhà ìlà-oòrùn sínú ilẹ̀ nwọn, èyítí ó wà ní ìhà gúsù ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.

8 Ilẹ̀ Nífáì sì nà láti apá òkun apá ilà-oòrùn títí dé apá ìwọ̀-oòrùn.

9 O sì ṣe pé nígbàtí Mórónì ti lé gbogbo àwọn ará Lámánì jáde kúrò nínú aginjù ti apá ìlà-oòrùn, tí ó wà ní apá àríwá àwọn ilẹ̀ tĩ ṣe ìní nwọn, ó mú kí àwọn tí ó ngbé inú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà àti nínú ilẹ̀ àyíká lọ sínú aginjù apá ìlà-oòrùn, àní lọ sí ibi ìkángun etí òkun, kí nwọ́n sì ní ilẹ̀ nã ní ìní

10 O sì fi àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sí apá gúsù, ní ibi ìkángun àwọn ìní nwọn, ó sì mú nwọn láti kọ́ àwọn ibi ãbò láti lè fi ãbò bò àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nwọn àti àwọn ènìyàn nwọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn.

11 Báyĩ ni ó sì mú gbogbo àwọn ibi ãbò àwọn ará Lámánì kúrò ní aginjù ti apá ìlà-oòrùn, bẹ̃ni, àti ní apá ìwọ̀-oòrùn, tí ó dábõbò bò ilẹ̀ tí ó wà lãrín àwọn ará Nífáì àti àwọn ará Lámánì, lãrín ilẹ̀ Sarahẹ́múlà àti ilẹ̀ Nífáì, láti òkun apá ìwọ̀-oòrùn, èyítí ó ṣàn láti orí odò Sídónì—tí àwọn ará Nífáì sì ní ní ìní gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, bẹ̃ni, àní gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ nwọ́n.

12 Báyĩ ni Mórónì, pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó npọ̀ síi lójojúmọ́ nítorí ìdánilójú ìdábòbò tí iṣẹ́ rẹ̀ ti mú jáde fún nwọn, ṣe wá ọ̀nà láti ké ipa àti agbára àwọn ará Lámánì kúrò lórí àwọn ilẹ̀ ìní nwọn, pé kí nwọ́n má lè ní agbára rárá lórí àwọn ilẹ̀ ìní nwọn.

13 O sì ṣe tí àwọn ará Nífáì bẹ̀rẹ̀sí kíkọ́ ìpìlẹ̀ ìlú-nlá kan, nwọ́n sì pe orúkọ ìlú nlá nã ní Mórónì; ó sì wà ní ẹ̀gbẹ́ òkun apá ìlà oòrùn; ó sì wà ní apá gúsù ní etí ibi ìní àwọn ará Lámánì.

14 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí kíkọ́ ìpìlẹ̀ fún ìlú kan ní ãrin ìlú-nlá Mórónì àti ìlú-nlá Áárọ́nì, tí ó sì so etí ilẹ̀ Áárọ́nì àti ti Mórónì pọ̀; nwọ́n sì pe orúkọ ìlú-nlá nã, tàbí ilẹ̀ nã, ní Nífáìhà.

15 Nwọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí kíkọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú-nlá ní apá àríwá nínú ọdún kannã, èyítí nwọn npè ní Léhì tí nwọ́n sì kọ́ ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀, tí ó wà ní apá àríwá, ní etí bèbè òkun.

16 Báyĩ sì ni ogún ọdún parí.

17 Nínú ipò ìlọsíwájú yĩ ni àwọn ará Nífáì sì wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kọ́kànlélógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì.

18 Nwọ́n sì ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì ní ọrọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, nwọ́n sì tún bí síi nwọ́n sì lágbára ní ilẹ̀ nã.

19 Báyĩ sì ni a ríi bí gbogbo ìṣesí Olúwa ṣe kún fún ãnú tó tí ó sì tọ́, sí mímú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ sí àwọn ọmọ ènìyàn; bẹ̃ni, a lè ríi pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìjẹ́rìsí, àní ní àkokò yĩ, èyítí ó sọ fún Léhì, wipe:

20 Ìbùkún ni fún ọ àti àwọn ọmọ rẹ; nwọn ó sì jẹ́ alábùkún-fún, níwọ̀n ìgbàtí nwọn yíò bá pa òfin mi mọ́ nwọn yíò ṣe rere lórí ilẹ̀ nã. Ṣùgbọ́n rántí, níwọ̀n ìgbàtí nwọn kò bá pa òfin mi mọ́ a ó ké nwọn kúrò níwájú Olúwa.

21 Àwa sì ríi pé àwọn ìlérí wọ̀nyí ti ní ìjẹ́rìsí fún àwọn ará Nífáì; nítorípé àwọn asọ̀ àti àwọn ìjà nwọn, bẹ̃ni, àwọn ìpànìyàn nwọn, àti àwọn ìkógun nwọn, àwọn ìbọ̀rìṣà nwọn, àwọn ìwà àgbèrè nwọn, àti àwọn ìwà ìríra nwọn, èyítí ó wà lãrín ara nwọn, àwọn ni ó mú ogun àti ìparun bá nwọn.

22 Àwọn tí nwọ́n sì jẹ́ olódodo ní ti pípa òfin Olúwa mọ́ ni a kó yọ ní ìgbà gbogbo, tí ó sì jẹ́ wípé ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àwọn arákùnrin nwọn búburú ni a ti rán sí oko-ẹrú, tàbí sí ti ìparun lọ́wọ́ idà, tàbí sí àjórẹ̀hìn nínú ìgbagbọ́, tí nwọn sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì.

23 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ kò sí irú àkokò tí ayọ̀ tó báyĩ rí lãrín àwọn ènìyàn Nífáì, láti àkokò Nífáì ju àkokò ti Mórónì, bẹ̃ni, àní ní àkokò yĩ, ní ọdún kọkànlélógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́.

24 O sì ṣe tí ọdún kejìlélógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́ nã parí pẹ̀lú àlãfíà; bẹ̃ni, àti ọdún kẹtàlélógún pẹ̀lú.

25 O sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún kẹrìnlélógún nínú ìjọba àwọn onídàjọ́, tí àlãfíà ìbá wà lãrín àwọn ènìyàn Nífáì bíkòbáṣe ti ìjà kan tí ó wà lãrín nwọn lórí ilẹ̀ Léhì, àti ilẹ̀ Mọ́ríátọ́nì, èyítí ó so pọ̀ mọ́ etí ilẹ̀ Léhì; àwọn méjẽjì sì wà ní etí ilẹ̀ tí ó wà ní ibi bèbè òkun.

26 Nítorí kíyèsĩ, àwọn ènìyàn tí ó ní ilẹ̀ Mọ́ríátọ́nì mú apá kan nínú ilẹ̀ Léhì ní ìní; nítorínã ni ìjà líle bẹ̀rẹ̀sí wà lãrín nwọn, tóbẹ̃ tí àwọn ará Mọ́ríátọ́nì gbé ohun ìjà-ogun kọlũ àwọn arákùnrin nwọn, nwọ́n sì pinnu láti pa nwọ́n pẹ̀lú idà.

27 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, àwọn ènìyàn tí ó ni ilẹ̀ Léhì ní ìní sálọ sínú àgọ́ Mórónì, nwọ́n sì ṣìpẹ̀ fún un fún ìrànlọ́wọ́; nítorítí kíyèsĩ nwọ́n ko jẹ̀bi.

28 O sì ṣe pé nígbàtí àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì, àwọn ti ẹnití orúkọ rẹ̀ íṣe Mọ́ríántọ́nì ndarí, rí i pé àwọn ènìyàn Léhì ti sálọ sí ibi àgọ́ Mórónì, ẹ̀rù bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ma wa láti kọlũ nwọ́n kí nwọ́n sì pa nwọ́n run.

29 Nítorínã, Móríántọ́nì tẹ̃ mọ́ nwọn lọ́kàn pé kí nwọ́n sá lọ sínú ilẹ̀ èyítí ó wà ní apá àríwá, èyítí omi nlá bò orí rẹ̀, kí nwọ́n sì ní ilẹ̀ nã èyítí ó wà ní apá àríwá ní ìní.

30 Sì kíyèsĩ, nwọn ìbá ti mú ète yĩ ṣe, (èyítí ìbá jẹ́ ohun àbámọ̀) ṣùgbọ́n kíyèsĩ, Mọ́ríátọ́nì nítorípé ó jẹ́ onínúfùfù ènìyàn, nítorínã ó bínú sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, ó sì kọ lù ú ó sì lù ú lọ́pọ̀lọpọ̀.

31 O sì ṣe tí ó sá, ó sì dé inú àgọ́ Mórónì, ó sì sọ ohun gbogbo nípa ọ̀rọ̀ nã fún Mórónì, àti nípa ète nwọn láti sálọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá.

32 Nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, tàbí kí a sọ wípé Mórónì, ní ìbẹ̀rù pé nwọn yíò gbọ́ran sí Mọ́ríátọ́nì lẹ́nu tíi nwọn ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti pé báyĩ òun yíò ní àwọn ibi apá ilẹ̀ nã ní ìní, èyítí yíò jẹ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ nlá lãrín àwọn ènìyàn Nífáì, bẹ̃ni, ìṣẹ̀lẹ̀ èyítí yíò yọrísí sísọ òmìnira nwọn nù.

33 Nítorínã Mórónì rán ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan lọ, pẹ̀lú àgọ́ nwọn, sí iwájú àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì, láti dènà nwọn lọ́wọ́ sísálọ sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá.

34 O sì ṣe pé nwọn kò bọ́ síwájú nwọn àfi ìgbàtí nwọ́n dé etí ilẹ̀ Ibi-Ahoro; ibẹ̀ sì ni nwọ́n ti ṣíwájú nwọn, ní ibi ọ̀nà tõró èyítí ó kọjá ní ẹ̀gbẹ́ òkun sínú ilẹ̀ tí ó wà ní apá àríwá, bẹ̃ni, ní ẹ̀gbẹ́ òkun, ní apá ìwọ̀-oòrùn àti ní apá ìlà-oòrun.

35 O sì ṣe tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã èyítí Mórónì rán, èyítí ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ í ṣe Tíákúmì darí rẹ̀, bá àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì; àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì sì jẹ́ ọlọ́kàn líle ènìyàn, (nítorítí nwọn ngba àtìlẹhìn nípa ti ìwà búburú rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn rẹ̀) tí ìjà sì bẹ́ sílẹ̀ lãrín nwọn, nínú èyítí Tíákúmì pa Mọ́ríátọ́nì tí ó sì ṣẹ́gun àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, tí ó sì kó nwọn lẹ́rú, tí ó sì padà sí àgọ́ Mórónì. Báyĩ sì ni ọdún kẹrìnlélógún ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin.

36 Báyĩ sì ni a ṣe mú àwọn ènìyàn Mọ́ríátọ́nì padà. Ní kété tí nwọ́n sì ti ṣe májẹ̀mú láti gbé ìgbé ayé àlãfíà ni a sì mú nwọn padà sí ilẹ̀ Mọ́ríátọ́nì, tí ìrẹ́pọ̀ sì wà lãrín nwọn àti àwọn ènìyàn Léhì; a sì mú àwọn nã padà sí órí àwọn ilẹ̀ nwọn.

37 O sì ṣe ni ọdún kannã tí àwọn ènìyàn Nífáì rí àlãfíà gbà padà, tí Nífáìhà, onídàjọ́ àgbà kejì kú, ó sì jẹ́ ìtẹ́ ìdájọ́ pẹ̀lú ìdúróṣinṣin tí ó pé níwájú Ọlọ́run.

38 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ti kọ̀ fún Álmà láti gba àwọn àkọsílẹ̀ nnì àti àwọn ohun wọnnì èyítí Álmà àti àwọn bàbá rẹ̀ kà kún ohun mímọ́ jùlọ; nítorínã Álmà ti gbé nwọn lé ọwọ́ ọmọ rẹ̀, Hẹ́lámánì.

39 Kíyèsĩ, ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã yan ọmọ Nífáìhà sí orí ìtẹ́ ìdájọ́, dípò bàbá rẹ̀; bẹ̃ni, nwọn yàn án gẹ́gẹ́bí adájọ́ àgbà àti olórí lé àwọn ènìyàn nã lórí, pẹ̀lú ìbúra àti ìlànà mímọ́ láti ṣe ìdájọ́ òdodo, àti láti pa àlãfíà àti òmìnira àwọn ènìyàn nã mọ́, àti láti fún nwọn ní àwọn ẹ̀tọ́ mímọ́ nwọn láti sin Olúwa Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, láti ṣe àtìlẹhìn fún àti lati ja ìjà òmìnira ti Ọlọ́run rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àti láti mú àwọn ènìyàn búburú wá sí àìṣègbè ní ìbámu pẹ̀lú ìwà búburú nwọn.

40 Nísisìyí kíyèsĩ, orúkọ rẹ̀ ni í ṣe Pahoránì. Pahoránì sì wà lórí ìtẹ́ ìdájọ́ bàbá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ ní òpin ọdún kẹrìnlélógún, lórí àwọn ènìyàn Nífáì.