Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 44


Orí 44

Mórónì pàṣẹ fún àwọn ará Lámánì láti dá májẹ̀mú wíwà lálãfíà tàbí kí a pa nwọ́n run—Sẹrahẹ́múnà kọ àbá nã, ìjà nã sì tún bẹ̀rẹ̀—Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mórónì ṣẹgun àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 74 sí 73 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí nwọ́n dáwọ́dúró tí nwọ́n sì fà sẹ́hìn díẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ nwọn. Mórónì sì wí fún Sẹrahẹ́múnà: Kíyèsĩ, Sẹrahẹ́múnà, pé àwa kò ní ìfẹ́ láti jẹ́ ẹni tíi tàjẹ̀ ènìyàn sílẹ̀. Ẹ̀yin mọ̀ pé ẹ̀yin ti bọ́ sí wa lọ́wọ́, síbẹ̀ àwa kò ní ìfẹ́ láti pa nyín.

2 Kíyèsĩ, àwa kò jáde wá láti dojú ìjà kọ nyín láti ta ẹ̀jẹ̀ nyín sílẹ̀ láti pàṣẹ lórí nyín; bẹ̃ sì ni àwa kò ní ìfẹ́ láti mú ẹnìkẹ́ni ní ìgbèkùn. Ṣùgbọ́n eleyĩ ni ìdí tí ẹ̀yin fi jáde wá dojú kọ wá; bẹ̃ni, ẹ̀yin sì nbínú sí wa nítorí ẹ̀sìn wa.

3 Ṣùgbọ́n nísisìyí, ìwọ ríi pé Olúwa wà pẹ̀lú wa; ìwọ sì ríi pé ó ti fi yín lé wa lọ́wọ́. Àti nísisìyí èmi fẹ́ kí ó yé ọ pé a ṣe eleyĩ fún wa nítorí ti ẹ̀sìn wa àti ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Krístì. Àti nísisìyí ìwọ ríi pé ẹ̀yìn kò lè pa ìgbàgbọ́ wa yĩ run.

4 Nísisìyí ìwọ ríi pé eleyĩ ni í ṣe ìgbàgbọ́ òtítọ́ ti Ọlọ́run; bẹ̃ni, ìwọ ríi pé Ọlọ́run yíò ṣe àtìlẹhìn, yíò sì ṣe ìtọ́jú, yíò sì pa wá mọ́, ní ìwọ̀n ìgbà tí àwa bá jẹ́ olódodo síi, àti sí ìgbàgbọ́ wa, àti ẹ̀sìn wa; láé ni Olúwa kò sì ní jẹ́ kí ẹnìkẹ́ni ó pa wá run àfi tí àwa bá ṣubú sínú ìrékọjá tí àwa sì sẹ́ ìgbàgbọ́ wa.

5 Àti nísisìyí, Sẹrahẹ́múnà, mo pàṣẹ fún ọ, ní orúkọ Ọlọ́run ẹnití ó lágbára jùlọ, ẹnití ó ti fi agbára fún apá wa tí àwa sì ti lágbára jù nyín lọ, nípa ti ìgbàgbọ́ wa, nípa ti ẹ̀sìn wa, àti nípa ìlànà ìsìn wa àti nípa ti ìjọ wa, àti nípa ti ìtọ́jú tí í ṣe ohun ọ̀wọ̀ tí a níláti ṣe fún àwọn ìyàwó wa àti àwọn ọmọ wa, nípa ti ẹ̀tọ́ nnì èyítí ó so wá mọ́ ilẹ̀ wa àti orílẹ̀-èdè wa; bẹ̃ni, àti pẹ̀lú nípa ìpamọ́ ọ̀rọ̀ mímọ́ Ọlọ́run, èyítí a jẹ ní gbèsè fún gbogbo inúdídùn wa; àti nípa ohun gbogbo tí ó ṣọ̀wọ́n fún wa jùlọ—

6 Bẹ̃ni, èyí kĩ sĩ ṣe gbogbo rẹ̀; mo pàṣẹ fún nyín nípa ti gbogbo ìfẹ́ tí ẹ̀yin ní fún ìyè, pé kí ẹ kó àwọn ohun ìjà nyín fún wa, àwa kò sì ní lépa láti ta ẹ̀jẹ nyín sílẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yíò dá ẹ̀mí nyín sí, bí ẹ̀yin yíò bá máa bá tiyín lọ tí ẹ kò sì ní wá mọ́ láti ja ogun pẹ̀lú wa.

7 Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin kò bá ṣe èyí, ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti bọ́ sí wa lọ́wọ́, èmi yíò sì pàṣẹ fún àwọn ará mi pé kí nwọ́n ṣá nyín lọ́gbẹ́ ikú lára nyín kí ẹ̀yin ó sì di aláìsí; nígbànã ni a ó sì rí ẹnití yíò lágbára lórí àwọn ènìyàn yĩ; bẹ̃ni, a ó rí ẹnití a ó mú ní ìgbèkùn.

8 Àti nísisìyí ó sì ṣe pé nígbàtí Sẹrahẹ́múnà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó jáde tí ó sì kó idà rẹ̀ sílẹ̀ àti símẹ́tà rẹ̀, àti ọfà rẹ̀ lé ọwọ́ Mórónì, ó sì wí fún un pé: Kíyèsĩ, àwọn ohun ìjà ogun wa nìyí; àwa yíò kó nwọn lé ọ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n àwa kì yíò gbà láti bá ọ dá májẹ̀mú, èyítí àwa mọ̀ pé àwa kì yíò pa mọ́, àti àwọn ọmọ wa pẹ̀lú; ṣùgbọ́n ẹ kó àwọn ohun ìjà ogun wa, kí ẹ sì jẹ́ kí àwa ó kọjá lọ sínú aginjù; láìjẹ́bẹ̃ àwa yíò kó àwọn idà wa, àwa ó sì parẹ́ tàbí kí a ṣẹ́gun.

9 Ẹ kíyèsĩ, àwa kì í ṣe ìgbàgbọ́ kan nã pẹ̀lú nyín; àwa kò gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ni ó fi wá lé nyín lọ́wọ́; ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé ọgbọ́n àrekérekè nyín ni ó pa nyín mọ́ kúrò lọ́wọ́ idà wa. Ẹ kíyèsĩ, àwọn asà ìgbayà yín àti àwọn asà nyín ni ó pa nyín mọ́.

10 Àti nísisìyí nígbàtí Sẹrahẹ́múnà sì ti parí sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Mórónì dá idà àti àwọn ohun-ìjà ogun, tí ó ti gbà, padà fún Sẹrahẹ́múnà, tí ó sì wípé: Kíyèsĩ, a dá ogun nã dúró.

11 Nísisìyí, èmi kò lè yí ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ padà, nítorínã bí Olúwa ti nbẹ, ẹ̀yin kò ní lọ kúrò afi bí ẹ̀yin ó bá lọ kúrò pẹ̀lú ìbúra pé ẹ̀yin kò ní tún padà wá kọlũ wá láti bá wa jagun. Nísisìyí nítorítí ẹ̀yin wà lọ́wọ́ wa a ó ta ẹ̀jẹ̀ nyín sílẹ̀, tàbí kí ẹ̀yin ó jọ̀wọ́ ara nyín sílẹ̀ sí àwọn àbá tí èmi ti mú wá.

12 Àti nísisìyí nígbàtí Mórónì sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Sẹrahẹ́múnà kó idà rẹ̀, ó sì bínú sí Mórónì, ó sì súré síwájú pé kí òun lè pa Mórónì; ṣùgbọ́n bí ó ti gbé idà rẹ̀ sókè, kíyèsĩ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun Mórónì bẹ̃ àní lulẹ̀, ó sì dá ní ẹ̀gbẹ́ ẽkù rẹ̀; ó sì bẹ Sẹrahẹ́múnà pẹ̀lú tí ó fi ṣí awọ orí rẹ̀ bó tí ó sì bọ́ sílẹ̀. Sẹrahẹ́múnà sì yẹra kúrò lọ́dọ̀ nwọn bọ́ sí ãrin àwọn ọmọ ogun tirẹ̀.

13 Ó sì tún ṣe tí ọmọ ogun nnì èyítí ó wà nítòsí, ẹnití ó ṣí awọ orí Sẹrahẹ́múnà bọ́, mú awọ orí nã kúrò nílẹ̀ ní ibi irun orí, ó sì gbé e lé ṣónṣó ẹnu idà rẹ̀, ó sì nã sí nwọn, tí ó sì sọ fún nwọn ní ohun rara pé:

14 Àní gẹ́gẹ́bí awọ orí yĩ ṣe bọ́ lélẹ̀, èyítí í ṣe awọ orí olórí nyín, bẹ̃ni a ó ṣe ké nyín lulẹ̀ àfi bí ẹ̀yin bá kó àwọn ohun ìjà ogun nyín lélẹ̀ tí ẹ sì lọ kúrò pẹ̀lú májẹ̀mú wíwà lálãfíà.

15 Nísisìyí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà, nígbàtí nwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí nwọ́n sì rí awọ orí nã èyítí ó wà lórí idà, ẹ̀rù bá wọ́n; ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì jáde tí nwọ́n sì ju àwọn ohun ìjà ogun nwọn sílẹ̀ ní ibi ẹsẹ̀ Mórónì, tí nwọ́n sì dá májẹ̀mú wíwà lálãfíà. Gbogbo àwọn tí ó sì dá májẹ̀mú ni nwọ́n gbà kí nwọn lọ kúrò sínú aginjù.

16 Nísisìyí ó sì ṣe tí Sẹrahẹ́múnà bínú gidigidi, tí ó sì rú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ó kù sókè sí ìbínú, láti bá àwọn ará Nífáì jà nínú agbára tí ó pọ̀ síi.

17 Àti nísisìyí Mórónì bínú, nítorí oríkunkun àwọn ará Lámánì; nítorínã ó pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ kọlũ nwọ́n kí nwọ́n sì pa nwọ́n. O sì ṣe tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n; bẹ̃ni, àwọn ará Lámánì sì jà pẹ̀lú idà nwọn àti agbára nwọn.

18 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ìhõhò ara nwọn àti orí nwọn tí nwọn kò dãbò bò fi ara gba idà mímú àwọn ara Nífáì; bẹ̃ni, ẹ kíyèsĩ, a gún nwọn a sì ṣá nwọn, bẹ̃ni, nwọ́n sì ṣubú kánkán lọ́wọ́ idà àwọn ará Nífáì; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbá nwọn kúrò, àní gẹ́gẹ́bí ọmọ ogun Mórónì nnì ti sọtẹ́lẹ̀.

19 Nísisìyí, nígbàtí Sẹrahẹ́múnà rí i pé a ti fẹ́rẹ̀ pa gbogbo nwọn run tán, ó kígbe rara sí Mórónì, ó sì ṣe ìlérí pé òun yíò dá májẹ̀mú àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú nwọn, bí nwọ́n ó bá da ẹ̀mí àwọn tí ó kù sí, pé nwọn kò ní jáde wá bá nwọn jagun mọ́ láé.

20 Ó sì ṣe tí Mórónì mú kí pípa nwọn tún dá dúró lãrín àwọn ènìyàn nã. O sì gba àwọn ohun-ìjà ogun lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì; lẹ́hìn tí nwọ́n sì ti bã dá májẹ̀mú wíwà lálãfíà nwọn jẹ́ kí nwọ́n lọ kúrò sínú aginjù.

21 Nísisìyí iye àwọn tí ó kù nínú nwọn kò lónkà nítorípé iye nã pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, iye àwọn tí ó kú nínú nwọn pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nínú àwọn ará Nífáì àti nínú àwọn ará Lámánì.

22 Ó sì ṣe tí nwọ́n ju àwọn òkú nwọn sínú omi odò Sídónì, ó sì gbé nwọn ṣàn lọ sínú ìsàlẹ̀ òkun.

23 Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, tàbí pé ti Mórónì, padà nwọ́n sì dé ilé nwọn àti ilẹ̀ nwọn.

24 Báyĩ sì ni ọdún kejìdínlógún ti ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin. Báyĩ sì ni àkọsílẹ̀ fún ìrántí ti Álmà ṣe, èyítí ó kọ lé orí àwọn àwo ti Nífáì.

Tẹ̀