Orí 47
Amalikíà fi ìwà àrékérekè, ìpànìyàn, àti rìkíṣí di ọba àwọn ará Lámánì—Àwọn ará Nífáì tí ó yapa jẹ́ oníwà búburú àti ìkà ènìyàn ju àwọn ará Lámánì lọ. Ní ìwọ̀n ọdún 72 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Nísisìyí a ó padà lórí àkọsílẹ̀ wa lọ sí ti Amalikíà àti àwọn tí nwọ́n ti sá pẹ̀lú rẹ̀ wọ inú aginjù lọ; nítorí, ẹ kíyèsĩ, ó ti mú àwọn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀, tí nwọ́n sì kọjá lọ sínú ilẹ̀ Nífáì lãrín àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì rú ìbínú àwọn ará Lámánì sókè sí àwọn ènìyàn Nífáì, tóbẹ̃ tí ọba àwọn ará Lámánì fi ìkéde ránṣẹ́ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí nwọ́n pé jọ pọ̀ láti tún lọ bá àwọn ará Nífáì jagun.
2 Ó sì ṣe nígbàtí ìkéde nã ti lọ sí ãrin nwọn ẹ̀rù bà nwọ́n gidigidi; bẹ̃ni, nwọn bẹ̀rù láti máṣe ti ọba, nwọ́n sì tún bẹ̀rù láti lọ bá àwọn ará Nífáì jagun kí nwọ́n má bã pàdánù ẹ̀mí nwọn. O sì ṣe tí nwọn kò ṣeé, tàbí pé púpọ̀ nínú nwọn kò ṣe ìgbọràn sí òfin ọba nã.
3 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí ọba bínú nítorí ìwà àìgbọràn nwọn; nítorínã ó fún Amalikíà ní àṣẹ lórí apá kan ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ nnì èyítí ó ṣe ìgbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀, ó sì pã láṣẹ fún un pé kí ó lọ fi ipá mú nwọn gbé ohun ìjà ogun.
4 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èyí ni ìfẹ́ inú Amalikíà; nítorípé ènìyàn alárèkérekè ni í ṣe fún ibi ṣíṣe, nítorínã ni ó ṣe pa ète yĩ ní ọkàn rẹ̀ láti yọ ọba àwọn ará Lámánì kúrò lórí oyè.
5 Àti nísisìyí tí ó sì ti gba àṣẹ lórí àwọn ará Lámánì nnì tí nwọ́n nṣe ti ọba nã; ó sì wá ọ̀nà láti rí ojú rere àwọn tí nwọn kò ṣe ìgbọràn; nítorínã ó jáde lọ sí ibi tí à npè ní Onídà, nítorípé nibẹ ni gbogbo àwọn Lámánì ti salọ; nítorípé nwọ́n ríi tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun nbọ̀wá, àti pé nwọ́n rò wípé nwọ́n ntọ̀ nwọ́n wá láti pa nwọ́n run, nítorínã nwọ́n sá lọ sí Onídà, lọ sí ibití nwọ́n kó àwọn ohun ìjà-ogun pamọ́ sí.
6 Nwọ́n sì ti yan ọkùnrin kan láti jẹ́ ọba àti olórí nwọn, nítorítí nwọ́n ti pinnu nínú ọkàn nwọn pé nwọ́n kò ní gbà kí ọba ó mú nwọn lọ kọlũ àwọn ará Nífáì.
7 Ó sì ṣe ti nwọ́n kó ara nwọn jọ lórí òkè gíga nnì èyítí nwọn npè ní Ántípà, ní ìmúrasílẹ̀ fún ogun.
8 Nísisìyí kì í ṣe èrò inú Amalikíà láti bá nwọn jagun gẹ́gẹ́bí ọba ti pã láṣẹ; ṣùgbọ́n, ẹ kíyèsĩ, èrò inú rẹ̀ ni láti rí ojú rere ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì, láti lè di olùdarí nwọn kí òun sì yọ ọba nã kúrò lórí oyè kí ó sì gba ìjọba nã.
9 Ẹ sì kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ó mú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tirẹ̀ pàgọ́ nwọn sínú àfonífojì èyítí ó wà lẹba òkè gíga Ántípà.
10 Ó sì ṣe nígbàtí ó di alẹ́ ni ó rán ikọ̀ oníṣẹ́ ní ìkọ̀kọ̀ lọ sí òkè gíga Ántípà, pé kí olórí àwọn tí ó wà lórí òkè gíga nã, ẹnití orúkọ rẹ̀ í ṣe Léhọ́ntì, pé kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ìsàlẹ̀ òkè gíga nã, nítorítí òun ní ìfẹ́ láti bã sọ̀rọ̀.
11 Ó sì ṣe nígbàtí Léhọ́ntì gbọ́ iṣẹ́ nã òun kò dá àbá láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ òkè gíga nã. O sì ṣe tí Amalikíà tún ránṣẹ́ ní ìgbà kejì, pé òun fẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá. O sì ṣe tí Léhọ́ntì kò ṣe bẹ̃; ó sì tún rán ikọ̀ oníṣẹ́ nã ní ìgbà kẹ́ta.
12 Ó sì ṣe nígbàtí Amalikíà ríi pé òun kò lè mú kí Léhọ́ntì sọ̀kalẹ̀ wá kúrò lórí òkè gíga nã, ni ó kọjá lọ sórí òkè nã, nítòsí ibùdó Léhọ́ntì; ó sì tún ránṣẹ́ ní ìgbà kẹ́rin sí Léhọ́ntì, pé òun fẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá, àti pé kí ó mú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ dání pẹ̀lú rẹ̀.
13 Ó sì ṣe nígbàtí Léhọ́ntì sì ti sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ tọ Amalikíà wá, ni Amalikíà fẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ní òru, kí nwọ́n sì ká àwọn ènìyàn nnì tí ọba ti fún òun láṣẹ lórí nwọn mọ́ àwọn ibùdó nwọn, àti pé òun yíò fi nwọ́n lé ọwọ́ Léhọ́ntì, bí yíò bá fi òun (Amalikíà) ṣe igbá kejì lórí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun nã.
14 Ó sì ṣe tí Léhọ́ntì sọ̀kalẹ̀ wá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ nwọ́n sì yí àwọn ọmọ ogun Amalikíà ká, tí ó jẹ́ wípé kí nwọ́n tó jí ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Léhọ́ntì ti yí nwọn ká.
15 Ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n ríi pé nwọ́n ti yí nwọ́n ká, nwọ́n ṣípẹ̀ pẹ̀lú Amalikíà pé kí ó jẹ́ kí nwọ́n darapọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin nwọn, kí nwọ́n má bã parun. Ní báyĩ eleyĩ ni ohun tí Amalikíà fẹ́.
16 Ó sì ṣe tí ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yọ, ní ìlòdìsí àṣẹ ọba. Nisisinyi èyí sì ni ohun tí Amalikíà fẹ́, kio lè mú rírọ ọba lóyè di ṣíṣe èyítí í ṣe ète rẹ̀.
17 Nísisìyí ó jẹ́ àṣà lãrín àwọn ará Lámánì, bí a bá pa olórí àgbà nwọn, láti yan ẹnití í ṣe igbá kejì láti jẹ́ olórí àgbà nwọn.
18 Ó sì ṣe tí Amalikíà mú kí ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ máa fún Léhọ́ntì ní májèlé jẹ ní dẹ́idíẹ̀, tí ó sì kú.
19 Nísisìyí, nígbàtí Léhọ́ntì ti kú, àwọn ará Lámánì yan Amalikíà láti jẹ́ olórí-ológun àgbà nwọn.
20 Ó sì ṣe tí Amalikíà lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ (nítorítí ó ti rí ìfẹ́-inú rẹ̀ gbà) sí ilẹ̀ Nífáì, sí ìlú-nlá Nífáì, èyítí í ṣe olú-ìlú.
21 Ọba sì jáde wá láti pàdé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ, nítorítí ó rò pé Amalikíà ti jíṣẹ́ tí òun rán an, àti pé Amalikíà ti kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó pọ̀ púpọ̀ jọ láti lọ íkọlu àwọn ará Nífáì nínú ogun.
22 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, bí ọba ṣe jáde wá ípàdé rẹ̀, Amalikíà mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ ípàdé ọba. Nwọ́n sì lọ nwọ́n sì wólẹ̀ níwájú ọba, bí èyítí nwọ́n fẹ́ bọ̀wọ̀ fún un nítorí títóbi rẹ̀.
23 Ó sì ṣe tí ọba na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti gbé nwọn sókè, gẹ́gẹ́bí àṣà àwọn ará Lámánì, fún àmì àlãfíà, àṣà èyítí nwọ́n ti kọ́ lọ́dọ̀ àwọn ará Nífáì.
24 Ó sì ṣe nígbàtí ó ti gbé ẹni àkọ́kọ́ sókè kúrò nílẹ̀, kíyèsĩ ó sì gún ọba nã lọ́bẹ lọ sínú ọkàn rẹ̀, ó sì ṣubú lulẹ̀.
25 Nísisìyí àwọn ìránṣẹ́ ọba sá; àwọn ìránṣẹ́ Amalikíà sì kígbe sókè, wípé:
26 Ẹ kíyèsĩ, àwọn ìránṣẹ́ ọba ti gún un lọ́bẹ lọ sínú ọkàn, ó sì ti ṣubú lulẹ̀ nwọ́n sì ti sá lọ; ẹ kíyèsĩ, ẹ wá wõ.
27 Ó sì ṣe tí Amalikíà pàṣẹ pé kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jáde lọ kí nwọ́n sì wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọba nã; nígbàtí nwọ́n sì ti dé ibẹ̀, tí nwọ́n sì rí ọba nã tí ó dùbúlẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀, Amalikíà ṣe bí èyítí ó bínú, ó sì wípé: Ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn ọba, ẹ jẹ́ kí ó jáde lọ, kí ó sì sá tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kí ó sì pa nwọ́n.
28 Ó sì ṣe ti gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn ọba nã, nígbàtí nwọn gbọ́ ọ̀rọ̀ yĩ, wọ́n jáde lọ nwọ́n sì sá tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ ọba nã.
29 Nísisìyí nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ ọba rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí ó nsá tẹ̀lé nwọn, ẹ̀rù tún bà nwọ́n, nwọ́n sì sá wọ inú aginjù lọ, nwọn sì dé inú ilẹ̀ Sarahẹ́múlà nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Ámọ́nì.
30 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun èyítí ó sá tẹ̀lé nwọn sì padà, lẹ́hìn tí nwọ́n ti sá tẹ̀lé nwọn lórí asán; báyĩ sì ni Amalikíà, nípa ọ̀nà ẹ̀tàn rẹ̀, ṣe rí ìfẹ́ ọkàn àwọn ènìyàn nã gbà.
31 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì ó wọ inú ìlú-nlá Nífáì lọ pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ó sì mú ìlú nã ní ìní.
32 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí ayaba, nígbàtí ó ti gbọ́ pé nwọ́n ti pa ọba—nítorítí Amalikíà ti rán ikọ̀ oníṣẹ́ sí ayaba nã láti sọ fún un pé àwọn ìránṣẹ́ ọba ti pa ọba nã, pé òun ti sá tẹ̀lé nwọn pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọmọ ogun òun, ṣùgbọ́n asán ni èyí já sí, nwọ́n sì ti sálọ—
33 Nítorínã, nígbàtí ayaba nã gbọ́ iṣẹ́ yĩ ó ránṣẹ́ sí Amalikíà, pé òun fẹ́ kí ó dá àwọn ènìyàn ìlú nã sí; àti pé òun tún fẹ́ kí ó wá bẹ òun wò; àti pé òun tún fẹ́ kí ó mú àwọn ẹlẹ́rĩ dání láti ṣe ìjẹ́rĩ nípa ikú ọba nã.
34 Ó sì ṣe tí Amalikíà mú ìránṣẹ́ kan nã èyítí ó pa ọba, àti gbogbo àwọn tí nwọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, nwọ́n sì tọ ayaba nã lọ, sí ibití ó joko sí; gbogbo nwọn sì jẹ́ ẹ̀rí níwájú rẹ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ ọba ni ó pã; nwọ́n sì tún sọ wípé: Nwọ́n ti sálọ; njẹ́ èyí kò ha jẹ́ ẹ̀rí nípà nwọn? Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe tẹ́ ayaba nã lọ́rùn nípa ikú ọba.
35 Ó sì ṣe tí Amalikíà nwá ojú rere ayaba, ó sì fi ṣe aya; báyĩ nìpa ọ̀nà ẹ̀rú rẹ̀, àti nípa ìrànlọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ alarèkérekè rẹ̀, ó gba ìjọba nã; bẹ̃ni, nwọ́n kã kún ọba jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, lãrín gbogbo àwọn ènìyàn àwọn ará Lámánì, tí nwọn í ṣe àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ará Íṣmáẹ́lì, àti gbogbo àwọn tí ó yapa kúrò lára àwọn ará Nífáì, láti ìgbà ìjọba Nífáì títí dé àkokò yĩ.
36 Nísisìyí àwọn olùyapa wọ̀nyí, ní ìkọ́ni àti ìmọ̀ kan nã láti ọwọ́ àwọn ará Nífáì, bẹ̃ni, nwọ́n ní ìkọ́ni nínú ìmọ̀ kannã nípa Olúwa, bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé, láìpẹ́ lẹhin ìyapa wọn nwọ́n sì di líle sii ti nwọ́n sì sé àyà nwọn le, nwọ́n ya ẹ̀hànnà síi, nwọ́n burú síi, nwọ́n sì rorò ju àwọn ará Lámánì lọ—tí nwọn ngbé àṣà àwọn ará Lamánì wọ̀; tí nwọ́n sì nhùwà ọ̀lẹ, àti onírũrú ìwà ìfẹ́kúfẹ; bẹ̃ni, tí nwọ́n sì gbàgbé Olúwa Ọlọ́run nwọn pátápátá.