Àwọn Ìwé Mímọ́
Ojú Ewé Àkòrí ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì


Ìwé ti Mọ́mọ́nì

Ìwé Ìtàn Tí A Kọ Láti
Ọwọ́ Mọ́mọ́nì Sí Órí
Àwọn Àwo Tí A Mú Kúrò
Nínú Àwọn Àwo Ti Nífáì

Nítorínã, ó jẹ́ ìkékúrú ìwé ìrántí ti àwọn ènìyàn Nífáì, àti pẹ̀lú ti àwọn ará Lámánì—A kọ ọ́ sí àwọn ará Lámánì, tí wọ́n jẹ́ ìyókù idile Isráẹ́lì; áti pẹ̀lú sí àwọn Jũ àti Kèfèrí—A kọ ọ́ nípa ọ̀nà àṣẹ, àti pẹ̀lú nípasẹ̀ ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ti ìfihàn—A kọ ọ́ a sì fi èdídì dì í, a sì pa á mọ́ sí Olúwa, kí á má bà lè run wọ́n—Láti jáde wá nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run sí ìtumọ̀ ti èyí nã—A fi èdídì dì í nípa ọwọ́ Mórónì, a sì pa á mọ́ sí Olúwa, láti jáde wá nígbàtí àkókò bá tó nípasẹ̀ Kèfèrí—Ìtumọ̀ ti èyí nã nípasẹ̀ ẹ̀bùn Ọlọ́run.

Ìkékúrú tí a mú láti inú Ìwé Étérì pẹ̀lú, èyí tí ó jẹ́ ìwé ìrántí àwọn ènìyàn Járẹ́dì, àwọn tí a túká ní àkókò tí Olúwa da èdè àwọn ènìyan nã rú, nígbàtí wọ́n nkọ́ ilé ìṣọ́ gíga láti dé ọ̀run—Èyí jẹ́ láti fi hàn sí ìyókù ará ilé Isráẹ́lì àwọn ohun nlá èyí tí Olúwa ti ṣe fún àwọn bàbá wọn; àti pé kí wọ́n lè mọ́ àwọn májẹ̀mú Olúwa, pé kí a o má sọ wọ́n kuro títí láé—Àti pẹ̀lú sí yíyí lọ́kàn padà Jũ àti Kèfèrí pé Jésù ni Krístì, Ọlọ́run Ayérayé, tí nfi ara rẹ̀ hàn sí gbogbo orílẹ̀-èdè—Àti nísisìyí, bí àbùkù bá wà, wọ́n jẹ́ àṣìṣe àwọn ènìyàn; nítorínã, ẹ máṣe dá àwọn ohun Ọlọ́run lẹ́bi, kí a lè rí yín láìlábàwọ́n ní ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì.

Ìyírọ̀padà sí èdè míràn tí a kọ́ ṣe láti àwọn àwo sí Gẹ̃sì
láti ọwọ́ Joseph Smith, Kékeré

Ṣíṣe èkíní ní Gẹ̃sì ni a tẹ̀ ní ìlú
Palmyra, New York, ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ní ọdún 1830

Tẹ̀