“Yàn,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́,Oṣù Kẹfà 2022.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹfà 2022.
Yàn
Jóṣúà rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti yàn èyí tó tọ́, láti máa tẹ̀ lé Olúwa.
yàn
Agbára wa láti yàn àti ṣíṣe fún ara wa ni à npè ní yíyàn. Ó jẹ́ ipa pàtàkì kan ti ètò Bàbá Ọ̀run. Ète kan nínú ìgbésí ayé yìí ni láti fi hàn pé a máa yàn láti ṣègbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run kí a lè túbọ̀ dàbí Rẹ̀. A ó dá wa lẹ́jọ́ nípasẹ̀ ìwé ìyè wa. (Wo 3 Néfì 2:27; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101:78; Ábráhámù 3:25.)
èyí pẹ̀lú:
Jóṣhúà rọ àwọn ènìyàn rẹ̀ láti yan “lọjọ́ òní,” tàbí nísisìyí. A lè ṣe àwọn yíyàn pàtàkì ní èèkàn àti lẹ́hìinnà gbìyànjú láti dúró ní ìfaramọ́ sí wọn. (Wo Orin Dáfídì 37:5.)
sìn
Nínú ẹsẹ yìí, láti sìn túmọ̀ sí láti jọ́sìn, ṣèrànwọ́, gbọràn, àti láti fi ara rẹ fún ẹnìkan. Ó yẹ kí a sin Olúwa Moses 1:15).
Àwọn òrìṣà
A ti pàṣẹ fún Ísráẹ́lì láti sin Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè nìkan, Jésù Krístì (wo Exodus 20:2–5). Jóshúà fún wa ní àpẹrẹ ti àwọn ọlọrun miran ti àwọn ènìyàn rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ sìn. Àwọn ọlọ́run miiràn nínú ìgbésí ayé wa lè pẹ̀lú àwọn ohun-ìní, àwọn èrò ti àwọn ẹlòmíràn, àwọn ire míràn—ohunkóhun tí ó mú wa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.
èmi àti ilé mi
Jóṣhúà sọ fún ara rẹ̀ àti agbo ilé rẹ̀. Ó ní àwon yíò sin Olúwa. Ó fẹ́ darí ìdílé rẹ̀ lọ́nà òdodo kó sì kọ́ wọn láti tẹ̀ lé Olúwa (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93:40).
© 2022 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfa 2022. Yoruba 18315 779