“Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ Dà Bí àwọn Olùṣọ́-àgùtàn,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022
Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ Dà Bí àwọn Olùṣọ́-àgùtàn
Ní òru dídákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn, àwọn olùṣọ́-àgùtàn nfi taratara ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn.
Àwọn olùṣọ́-àgùtàn ní iṣẹ́ kan pàtàkì. Àgùtàn nílò oúnjẹ, omi, àti ààbò kúrò nínú ewu.
Lójijì, ángẹ́lì kan farahàn!
“Má bẹ̀rù, nítorí kíyèsi, mo mú ihìnrere ayọ nlá wá fún yín. … Nítorí a bí Olùgbàlà … fún yín lóní, èyí tíí ṣe Krístì Olúwa.”
Ángẹ́lì náà wí fún àwọn olùṣọ́-àgùtàn náà pé wọn yíò rí ọmọ náà tí a fi ọ̀já wé, tí ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran ní Bẹ́tlẹ́hẹ́mù.
àwọn akọrin kan bí ti-ángẹ́lì kún òfúrufú wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àngẹ́lì náà ní yíyin Ọlọ́run.
“Ògo fún Ọlọ́run lóke, àti àláfíà ní aye, ìfẹ́-inú rere sí ènìyàn.”
“Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù kí a sì rí ohun tí Olúwa ti sọ di mímọ̀ sí wa.”
Àwọn olùṣọ-àgùtàn kò dúró. Èyí ṣe pàtàkì púpọ̀! Wọ́n “wá pẹ̀lú ìyára” sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù.
Àwọn olùṣọ́-àgùtàn rí Jésù tí a fi ọ̀já wé, tí ó dùbúlẹ̀ sí ibùjẹ́ ẹran, gẹ́gẹ́bí ángẹ́lì náà ti wí.
Èyí ni Mèssíàh tí a ṣe ìlérí ẹni tí ó wá láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé àti láti mú ayọ̀ òtítọ́ wá fún wa!
Inú àwọn olùṣọ́-àgùtàn dùn jọjọ! Wọ́n pín ohun tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí.
“A bí Olùgbàlà aráyé!”
“Mèssíàh ti wá ní ìgbẹ̀hìn!”
Àwọn olùṣọ́-àgùtàn “wá pẹ̀lú ìyára” sọ́dọ̀ Jésù. Ẹ lè ṣeé bákannáà!
Ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Rẹ̀.
Ẹ lè sìn Ín nípa sísin àwọn ẹlòmíràn.
Ẹ lè jẹ́ ẹ̀rí nípa Rẹ̀.
© 2022 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022. Yoruba. 18318 779