“Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ Dà Bí àwọn Olùṣọ́-àgùtàn,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022. Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022 Lúkù 2:8-20. Ẹ Máṣe Dúró! Ẹ Dà Bí àwọn Olùṣọ́-àgùtàn Láti ọwọ́ Eric B. Murdock; àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Darren Rawlings Ní òru dídákẹ́ rọ́rọ́ kan ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn, àwọn olùṣọ́-àgùtàn nfi taratara ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn. Àwọn olùṣọ́-àgùtàn ní iṣẹ́ kan pàtàkì. Àgùtàn nílò oúnjẹ, omi, àti ààbò kúrò nínú ewu. Lójijì, ángẹ́lì kan farahàn! “Má bẹ̀rù, nítorí kíyèsi, mo mú ihìnrere ayọ nlá wá fún yín. … Nítorí a bí Olùgbàlà … fún yín lóní, èyí tíí ṣe Krístì Olúwa.” Ángẹ́lì náà wí fún àwọn olùṣọ́-àgùtàn náà pé wọn yíò rí ọmọ náà tí a fi ọ̀já wé, tí ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ́ ẹran ní Bẹ́tlẹ́hẹ́mù. àwọn akọrin kan bí ti-ángẹ́lì kún òfúrufú wọ́n sì darapọ̀ mọ́ àngẹ́lì náà ní yíyin Ọlọ́run. “Ògo fún Ọlọ́run lóke, àti àláfíà ní aye, ìfẹ́-inú rere sí ènìyàn.” “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù kí a sì rí ohun tí Olúwa ti sọ di mímọ̀ sí wa.” Àwọn olùṣọ-àgùtàn kò dúró. Èyí ṣe pàtàkì púpọ̀! Wọ́n “wá pẹ̀lú ìyára” sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù. Àwọn olùṣọ́-àgùtàn rí Jésù tí a fi ọ̀já wé, tí ó dùbúlẹ̀ sí ibùjẹ́ ẹran, gẹ́gẹ́bí ángẹ́lì náà ti wí. Èyí ni Mèssíàh tí a ṣe ìlérí ẹni tí ó wá láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé àti láti mú ayọ̀ òtítọ́ wá fún wa! Inú àwọn olùṣọ́-àgùtàn dùn jọjọ! Wọ́n pín ohun tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí. “A bí Olùgbàlà aráyé!” “Mèssíàh ti wá ní ìgbẹ̀hìn!” Àwọn olùṣọ́-àgùtàn “wá pẹ̀lú ìyára” sọ́dọ̀ Jésù. Ẹ lè ṣeé bákannáà! Ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Rẹ̀. Ẹ lè sìn Ín nípa sísin àwọn ẹlòmíràn. Ẹ lè jẹ́ ẹ̀rí nípa Rẹ̀. © 2022 láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a fipamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà-èdè: 6/19. Ìyírọ̀padà-èdè ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2022. Yoruba. 18318 779