2023
Ṣí Ọkan Rẹ sí Ẹ̀mí Mímọ́
Oṣù Kẹrin 2023


“Ṣí Ọkan Rẹ sí Ẹ̀mí Mímọ́,” Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹ́rin, 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹrin 2023

Ṣí Ọkan Rẹ sí Ẹ̀mí Mímọ́

Láti inú ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò kan ti Oṣù Kẹ́rin 2018.

Ní àkokò Ọdún Àjínde yí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa Ọ̀run fún ẹ̀bùn Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, ẹnití ó wá sí ilẹ̀-ayé ní ìjọ̀wọ́ ararẹ̀ láti jẹ́ Olùràpadà wa. Mo dúpẹ́ láti mọ̀ pé Ó ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ó sì jí dìde nínú Àjínde. Ní ojojúmọ́ mo di alábùkún fún láti mọ pé, nítorí Ètùtù Rẹ̀, mo lè jínde ní ọjọ́kan láti gbé títí láé nínú ẹbí olùfẹ́ni.

Èmi mọ àwọn ohun wọnnì nípa ọ̀nà kanṣoṣo tí ẹnìkẹ́ni lára wa fi lè mọ̀ wọ́n. Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọ̀rọ̀ sí iyè-inú àti ọkàn mi pé wọ́n jẹ́ òtítọ́—kìí ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ṣùgbọ́n nígbà gbogbo.

A ní ìlérí àìdíyelé ti Ẹ̀mí Mímọ́ bí ojúgbà kan. Ojúṣe wa ni láti yàn láti ṣí ọkàn wa láti gba ìdarí ti ẹ̀mí àti ìtùnú títí lọ nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́ ní ìgbà ayé kan.

Àwòrán
òdòdó

Àwọn Ìjúwe láti ọwọ́ Emily E. Jones

Àṣàyàn àkọ́kọ́ ni láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ níwájú Ọlọ́run.

Àwòrán
àwọn ọwọ́ tó ngbàdúrà

Ìkejì ni láti gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì.

Àwòrán
atọ́nà

Ìkẹ́ta ni láti gbọ́ràn déédé.

Àwòrán
ọkàn títúnṣe

Ìkẹ́rin sì ni láti gbàdúrà láti mọ àwọn àìní àti ọkàn àwọn ẹlòmíràn àti bí a ó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ fún Olúwa.

Mo gbàdúrà pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi pé ẹ ó gbọ́ ohùn Ẹ̀mí, èyí tí a rán sí yín pẹ̀lú inúrere tó bẹ́ẹ̀. Mo sì gbàdúrà pé ẹ ó ṣí ọkan yín nígbà gbogbo láti gba Ẹ̀mí náà kí ẹ lè ní ayọ̀ ti níní Òun pẹ̀lú yín bí ojúgbà yín nígbà gbogbo.

Tẹ̀