2023
Àwọn Ọjọ́ Méje ti Ṣíṣe Àbápín
Oṣù Keje 2023


“Àwọn Ọjọ́ Méje ti Ṣíṣe Àbápín,” Fún okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kéje 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kéje 2023.

Àwọn Ọjọ́ Méje ti Ṣíṣe Àbápín

Ẹ lè ṣe àbápín ìhìnrere ní àwọn ọ̀nà déédé àti àdánidá. Ṣe ẹ ti ṣetán fún ìpènijà náà?

Nígbàtí a bá sọ̀rọ̀ nípa pípín àwọn ẹ̀rí wa, a máa nfi ìgbà gbogbo ronú nípa jíjẹ́ àwọn ẹ̀rí wa nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa tàbí àwọn àgbékalẹ̀ déédé míràn. Ṣùgbọ́n a ti gbà wá níyànjú láti “wá àwọn ànfàní láti mú ìgbàgbọ́ rẹ gòkè ní àwọn ọ̀nà àdánidá àti déédé.”1

Nínú ìpènijà ọjọ́-méje ìsàlẹ̀, ẹ lè ṣe àbápín ẹ̀rí yín ní onírurú ọ̀nà ní ojojúmọ́ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ẹ lè ṣe àwọn ohun wọ̀nyí ní èyíkéyi ètò, tàbí ẹ tilẹ̀ lè jáde wá pẹ̀lú àwọn èrò ti ara yín! Ṣe ẹ ti ṣetán fún ìpènijà náà?

Àwòrán
ilé-ìpàdé

Àwọn ìjúwe láti ọwọ́ Emily Davis

Ọjọ́ Kínní: Ilé Ìjọsìn

E ro jíjẹ́ ẹ̀rí yín nínú ìpàdé àwẹ̀ àti ẹ̀rí kan nínú ilé ìjọsìn bí ó bá jẹ́ ohun tí ẹ ní ìtunú pẹ̀lú. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bákannáà ẹ lè pín ẹ̀rí yín nínú ìjọ nípa kíkópa nínú àwọn kílásì yín ní ọjọ́ Ìsìnmi àti ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́mínárì. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ bá ṣe àbápín níbẹ̀ lè gbé àwọn ẹlòmíràn ga kí ó sì fún àwọn ẹ̀rí wọn lókun àti tiyín bákannáà.

Àwòrán
àwọn ọ̀rẹ́

Ọjọ́ Kejì: Àwọn Ọ̀rẹ́

Kíni ẹ kọ́ ní ilé-ìjọsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi? Njẹ́ ẹ fẹ́ràn ohun tí ẹnìkan ṣe àbápín nínú ọ̀rọ̀ ìpàdé oúnjẹ Olúwa kan tàbí nínú ọ̀rọ̀ kílásì yín? Bóyá orin ìbẹ̀rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin ìsìn tí ó jẹ́ ààyò yín. Sọ fún ọ̀rẹ́ kan nípa rẹ̀! Lẹ́hìnnáà bèèrè nípa òpin ọ̀sẹ̀ wọn pẹ̀lú.

Àwòrán
fóònù pẹ̀lú ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn

Ọjọ́ Kẹ́ta: Ìbákẹ́gbẹ́ Ìròhìn

Ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn jẹ́ ibi nlá kan láti ṣe àbápín àwọn ohun ti-ẹ̀mí ní-déédé àti ní-àdánidá. Fún ọjọ́ yí ti ìpènijà náà, ẹ gbèrò ṣíṣe àbápín àlẹ̀mọ́ kan nípa:

  • Ọ̀kan lára àwọn ààyò ẹsẹ ìwé mímọ́ yín.

  • Àyọsọ gbígbéniga kan láti inú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.

  • Èrò tàbí ìrírí ti-ẹ̀mí kan.

  • Ohun kan tí ẹ nifẹ tàbí ní ìmoore nípa Olùgbàlà.

  • Ọ̀nà kan tí Òun ti ràn yín lọ́wọ́ láìpẹ́ yí tàbí ìwà kan tí ẹ mọyì nínú Rẹ̀ àti ìdí.

Àwòrán
fóònù pẹ̀lú fídíò àti àtẹ̀jíṣẹ́

Ọjọ́ Kẹ́rin: Àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí Fídíò

Fi ọ̀rọ̀ gbígbéniga kan ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ kan nípasẹ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí fídíò. Ẹ lè pín ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ kan tí ẹ rò pé wọ́n lè fẹ́ràn, ẹ sọ ohun kan fún wọn tí ẹ ní ìmoore fún nípa wọn, tàbí kí ẹ ṣe àbápín nípa ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì. Fún àpẹrẹ, wọ́n lè nílò láti mọ̀ nípa ìfẹ́ Baba Ọ̀run fún wọn. Ẹ lè sọ fún wọn ní ojúkojú nígbàgbogbo bákannáà!

Àwòrán
ọ̀dọ́mọbìnrin pẹ̀lú fèrè bíi àwòrán-ọkàn

Ọjọ́ Karun: Iṣẹ́-ìsìn

Ẹ lè ròó bí sisin àwọn ẹlòmíràn ti lè jẹ́ ọ̀nà láti ṣe àbápín ẹ̀rí yín. Àpọ́télì Páùlù wí fún Tímóteu pé, “Jẹ́ àpẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ̀, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́” (1 Tímóteu 4:12). Nítorínáà ẹ lè fi àwọn ìgbàgbọ́ yín hàn nípasẹ̀ àpẹrẹ yín, nípa sisin àwọn ẹlòmíràn bí Olùgbàlà yíò ti sìn wọ́n.

Àwòrán
ṣìṣe iṣẹ́-ọnà

Ọjọ́ Kẹfà: Iṣẹ̀-ọnà

Nígbàmíràn àwọn ènìyàn nlo iṣẹ́-ọnà bí ọ̀nà tí ó yàtọ̀ láti ṣe àbápín àwọn èrò àti ìmọ̀lára wọn. Ẹ lè lo àwọn ohun kíkùn, àwòrán gbígbẹ́, ewì, orin, tàbí irù àwọn iṣẹ́-ọnà míràn láti ṣe àbápín irú ìmọ̀lára ti ẹ ní nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀.

Àwòrán
àwọn ọ̀dọ́ nsọ̀rọ̀

Ọjọ́ Kéje: Ìbárasọ̀rọ̀ Lásán

Ẹ máṣe bẹ̀rù láti sọ àwọn ìgbàgbọ́ yín nínú àwọn ìgbékalẹ̀ lásán, gẹ́gẹ́bí ẹ ó ti ṣe àbápín àwọn èrò míràn tí ẹ ní nípa àkọlé kan pàtó.

Bẹ́ẹ̀ni, ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣe ìjọ tàbí ìwé mímọ́ kan tí ẹ kà láìpẹ́, ṣùgbọ́n ó tilẹ̀ lè jẹ́ lásán díẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ bákannáà. Fún àpẹrẹ:

  • Bí ẹ bá ní ìmọ̀lára ìmísí nípa àdánidá, ẹ fi ìmoore yín hàn sí ẹlòmíràn nípa àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.

  • Bóyá ẹ ní ìrirí dídára ti ẹ̀mí kan ní àìpẹ́. Sọ fún ọ̀rẹ́ kan nípa rẹ̀ tí kò bá jẹ́ ti araẹni púpọ̀jù.

  • Ẹ wá àwọn àfijọ ìhìnrere nínú ìwé tàbí eré ìtàgé kan tí ẹ fẹ́ràn, kí ẹ sì ṣe àbápín ìwòye yín.

Déédé àti Àdánidá

Bí ẹ ti nwá onírurú àwọn ọ̀nà láti ṣe àbápín àwọn ìgbàgbọ́ yín, yíò di àdánidá síi àti púpọ̀ síi fún yín láti ṣe. Ó lè dàbí òdì ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n èyí náà dára! Ẹ rántí pé, ẹ̀rí yín fúnrararẹ̀ jẹ́ àdánidá síi yín tẹ́lẹ̀—ó jẹ́ apákan irú ẹni tí ẹ jẹ́. Ṣíṣe àbápín rẹ̀ lè di àdánidá pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí ó gbà ni sísọ nípa rẹ̀ díẹ́díẹ̀ si ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

Báwo ni ẹ ó ti ṣe àbápín ẹ̀rí yín ní òní?

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Dieter F. Uchtdorf, “Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́rin. 2019” (Ẹ́nsáìnì tàbí Làìhónà, Oṣù Karun 2019, 17).

Tẹ̀