“Àwọn Ọjọ́ Méje ti Ṣíṣe Àbápín,” Fún okun Àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kéje 2023.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kéje 2023.
Àwọn Ọjọ́ Méje ti Ṣíṣe Àbápín
Ẹ lè ṣe àbápín ìhìnrere ní àwọn ọ̀nà déédé àti àdánidá. Ṣe ẹ ti ṣetán fún ìpènijà náà?
Nígbàtí a bá sọ̀rọ̀ nípa pípín àwọn ẹ̀rí wa, a máa nfi ìgbà gbogbo ronú nípa jíjẹ́ àwọn ẹ̀rí wa nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa tàbí àwọn àgbékalẹ̀ déédé míràn. Ṣùgbọ́n a ti gbà wá níyànjú láti “wá àwọn ànfàní láti mú ìgbàgbọ́ rẹ gòkè ní àwọn ọ̀nà àdánidá àti déédé.”1
Nínú ìpènijà ọjọ́-méje ìsàlẹ̀, ẹ lè ṣe àbápín ẹ̀rí yín ní onírurú ọ̀nà ní ojojúmọ́ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ẹ lè ṣe àwọn ohun wọ̀nyí ní èyíkéyi ètò, tàbí ẹ tilẹ̀ lè jáde wá pẹ̀lú àwọn èrò ti ara yín! Ṣe ẹ ti ṣetán fún ìpènijà náà?
Ọjọ́ Kínní: Ilé Ìjọsìn
E ro jíjẹ́ ẹ̀rí yín nínú ìpàdé àwẹ̀ àti ẹ̀rí kan nínú ilé ìjọsìn bí ó bá jẹ́ ohun tí ẹ ní ìtunú pẹ̀lú. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bákannáà ẹ lè pín ẹ̀rí yín nínú ìjọ nípa kíkópa nínú àwọn kílásì yín ní ọjọ́ Ìsìnmi àti ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́mínárì. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ bá ṣe àbápín níbẹ̀ lè gbé àwọn ẹlòmíràn ga kí ó sì fún àwọn ẹ̀rí wọn lókun àti tiyín bákannáà.
Ọjọ́ Kejì: Àwọn Ọ̀rẹ́
Kíni ẹ kọ́ ní ilé-ìjọsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi? Njẹ́ ẹ fẹ́ràn ohun tí ẹnìkan ṣe àbápín nínú ọ̀rọ̀ ìpàdé oúnjẹ Olúwa kan tàbí nínú ọ̀rọ̀ kílásì yín? Bóyá orin ìbẹ̀rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orin ìsìn tí ó jẹ́ ààyò yín. Sọ fún ọ̀rẹ́ kan nípa rẹ̀! Lẹ́hìnnáà bèèrè nípa òpin ọ̀sẹ̀ wọn pẹ̀lú.
Ọjọ́ Kẹ́ta: Ìbákẹ́gbẹ́ Ìròhìn
Ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn jẹ́ ibi nlá kan láti ṣe àbápín àwọn ohun ti-ẹ̀mí ní-déédé àti ní-àdánidá. Fún ọjọ́ yí ti ìpènijà náà, ẹ gbèrò ṣíṣe àbápín àlẹ̀mọ́ kan nípa:
-
Ọ̀kan lára àwọn ààyò ẹsẹ ìwé mímọ́ yín.
-
Àyọsọ gbígbéniga kan láti inú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.
-
Èrò tàbí ìrírí ti-ẹ̀mí kan.
-
Ohun kan tí ẹ nifẹ tàbí ní ìmoore nípa Olùgbàlà.
-
Ọ̀nà kan tí Òun ti ràn yín lọ́wọ́ láìpẹ́ yí tàbí ìwà kan tí ẹ mọyì nínú Rẹ̀ àti ìdí.
Ọjọ́ Kẹ́rin: Àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí Fídíò
Fi ọ̀rọ̀ gbígbéniga kan ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ kan nípasẹ̀ àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí fídíò. Ẹ lè pín ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ kan tí ẹ rò pé wọ́n lè fẹ́ràn, ẹ sọ ohun kan fún wọn tí ẹ ní ìmoore fún nípa wọn, tàbí kí ẹ ṣe àbápín nípa ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì. Fún àpẹrẹ, wọ́n lè nílò láti mọ̀ nípa ìfẹ́ Baba Ọ̀run fún wọn. Ẹ lè sọ fún wọn ní ojúkojú nígbàgbogbo bákannáà!
Ọjọ́ Karun: Iṣẹ́-ìsìn
Ẹ lè ròó bí sisin àwọn ẹlòmíràn ti lè jẹ́ ọ̀nà láti ṣe àbápín ẹ̀rí yín. Àpọ́télì Páùlù wí fún Tímóteu pé, “Jẹ́ àpẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ̀, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́” (1 Tímóteu 4:12). Nítorínáà ẹ lè fi àwọn ìgbàgbọ́ yín hàn nípasẹ̀ àpẹrẹ yín, nípa sisin àwọn ẹlòmíràn bí Olùgbàlà yíò ti sìn wọ́n.
Ọjọ́ Kẹfà: Iṣẹ̀-ọnà
Nígbàmíràn àwọn ènìyàn nlo iṣẹ́-ọnà bí ọ̀nà tí ó yàtọ̀ láti ṣe àbápín àwọn èrò àti ìmọ̀lára wọn. Ẹ lè lo àwọn ohun kíkùn, àwòrán gbígbẹ́, ewì, orin, tàbí irù àwọn iṣẹ́-ọnà míràn láti ṣe àbápín irú ìmọ̀lára ti ẹ ní nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀.
Ọjọ́ Kéje: Ìbárasọ̀rọ̀ Lásán
Ẹ máṣe bẹ̀rù láti sọ àwọn ìgbàgbọ́ yín nínú àwọn ìgbékalẹ̀ lásán, gẹ́gẹ́bí ẹ ó ti ṣe àbápín àwọn èrò míràn tí ẹ ní nípa àkọlé kan pàtó.
Bẹ́ẹ̀ni, ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣe ìjọ tàbí ìwé mímọ́ kan tí ẹ kà láìpẹ́, ṣùgbọ́n ó tilẹ̀ lè jẹ́ lásán díẹ̀ jú bẹ́ẹ̀ lọ bákannáà. Fún àpẹrẹ:
-
Bí ẹ bá ní ìmọ̀lára ìmísí nípa àdánidá, ẹ fi ìmoore yín hàn sí ẹlòmíràn nípa àwọn ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.
-
Bóyá ẹ ní ìrirí dídára ti ẹ̀mí kan ní àìpẹ́. Sọ fún ọ̀rẹ́ kan nípa rẹ̀ tí kò bá jẹ́ ti araẹni púpọ̀jù.
-
Ẹ wá àwọn àfijọ ìhìnrere nínú ìwé tàbí eré ìtàgé kan tí ẹ fẹ́ràn, kí ẹ sì ṣe àbápín ìwòye yín.
Déédé àti Àdánidá
Bí ẹ ti nwá onírurú àwọn ọ̀nà láti ṣe àbápín àwọn ìgbàgbọ́ yín, yíò di àdánidá síi àti púpọ̀ síi fún yín láti ṣe. Ó lè dàbí òdì ní àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n èyí náà dára! Ẹ rántí pé, ẹ̀rí yín fúnrararẹ̀ jẹ́ àdánidá síi yín tẹ́lẹ̀—ó jẹ́ apákan irú ẹni tí ẹ jẹ́. Ṣíṣe àbápín rẹ̀ lè di àdánidá pẹ̀lú. Gbogbo ohun tí ó gbà ni sísọ nípa rẹ̀ díẹ́díẹ̀ si ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
Báwo ni ẹ ó ti ṣe àbápín ẹ̀rí yín ní òní?
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀pada ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kéje 2023.Language. 19045 779