2023
Ẹ gba Ẹ̀mí náà fún Ìtọ́sọ́nà Yín
Oṣù Kẹwa 2023


“Ẹ gba Ẹ̀mí náà fún Ìtọ́sọ́nà Yín,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹwa. 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹwa 2023.

Ẹ gba Ẹ̀mí náà fún Ìtọ́sọ́nà Yín

Baba wa ní Ọ̀run mọ̀ pé nínú ayé ikú a ó kojú àwọn ìpènijà, ìpọ́njú, àti rúdurùdu; Ó mọ̀ pé a ó ja ìjàkadì pẹ̀lú àwọn ìbèèrè, àwọn ìjákulẹ̀, àwọn àdánwò, àti àwọn àilera. Láti fún wa ní okun ayé ikú àti ìtọ́sọ́nà tọ̀run, Ó pèsè Ẹ̀mí Mímọ́.

Nípa ìyànsíṣẹ́ tọ̀run, Ẹ̀mí nmísí, njẹ́ ẹ̀ri, nkọ́ni, ó sì nṣí wa létí láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa. A ní ojúṣe mímọ́ láti kọ́ ẹkọ láti dá ipá Rẹ̀ mọ̀ nínú ayé wa kí a sì kọ ibi ara síì.

Báwo ni a ó ti ṣe èyí?

Àkọ́kọ́, à ó tiraka láti gbé ìgbé-ayé tó yẹ fún Ẹ̀mí.

Ìkejì, a gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ láti gba Ẹ̀mí náà.

Ìkẹ́ta, a gbọ́dọ̀ dá Ẹ̀mí náà nígbàtí ó bá wá.

Ìkẹ́rin, a gbọ́dọ̀ ṣe ìṣe lórí ìṣílétí àkọ́kọ́.

Njẹ́ kí a mú ìpè Olúwa daindain láti “tújúká, nítorí èmi yíò darí yín” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 78:18). Òun ndarí wa nípaẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Njẹ́ kí a gbé ìgbé ayé tó súnmọ́ Ẹ̀mí, ní ṣíṣe kíákíá lórí àwọn ìṣílétí wa àkọ́kọ́, ní mímọ́ pé wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Mo jẹ́ ẹ̀rí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ láti tọ́ wa sọ́nà, láti ṣọ́ wa, àti láti wà pẹ̀lú wa títí láé.

Tẹ̀