2023
Àwọn Òkú Yíò Dúró Níwájú Ọlọ́run
Oṣù Kejìlá 2023


“Àwọn Òkú Yíò Dúró Níwájú Ọlọ́run,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kejìlá 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kejìlá 2023

Àwọn Òkú Yíò Dúró níwájú Ọlọ́run

Nínú ìfihàn rẹ̀, Jòhánù rí Ìdájọ́ Ìgbẹ̀hìn.

Àwòrán
Jésù Krístì

Ó wá Lẹ́ẹ̀kansi láti Ṣe Àkóso àti láti Jọba, láti ọwọ́ Mary Sauer

àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọ́n dúró níwájú Ọlọ́run

Agbára Àjínde Jésù Krístì nmú gbogbo àwọn ènìyàn wá sí iwájú Ọlọ́run láti gba ìdájọ̀ (wo Álmà 11:42–44; 33:22; 40:21; Hẹ́lámánì 14:15–17; Mọ́mọ́nì 9:13–14).

a ṣí àwọn ìwé náà

Àwọn ìwé wọ́nyí nṣojú àwọn àkọsílẹ̀ tí a pamọ́ lórí ilẹ̀-ayé nípa ohun tí àwọn ènìyàn ṣe lórí ilẹ̀-ayé láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà májẹ̀mú (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mu 128:7).

ìwé ìyè

“Ní ọgbọ́n kan Ìwé Ìyè ni àkópọ̀ àwọn èrò àti ìṣe ènìyàn—àkọsílẹ̀ ayé rẹ̀. Bákannáà, àwọn ìwé-mímọ́ fihàn pẹ̀lú pé àkọsílẹ̀ tọ̀run ni a pamọ́ nípa àwọn olotitọ” (Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Ìwé Ìyè,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org).

dídálẹ́jọ́

Ìdájọ́ Ìgbẹ̀hìn nwá lẹ́hìn ìgbà tí àwọn ènìyàn bá jínde. Jésù Krístì yíò jẹ́ Adájọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ìdájọ́ yí yíò pinnu ògo ayérayé tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yíò gbà. (Wo Ìtọ́nisọ́nà sí àwọn Ìwé-mímọ́, “Dídájọ́, Ìgbẹ̀hìn,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org; Álmà 41:3–5; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:26–32.)

gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ wọn

Ẹnìkọ̀ọ̀kan yíò di dídàlẹ́jọ́ nípasẹ̀ ohun tí wọ́n ṣe àti ohun tí wọ́n nifẹ sí (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 137:9). Wọn yíò di dídálẹ́jọ́ nípa bóyá wọ́n gbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ̀run tí wọ́n sì ṣe ìṣe ní ìbàmu pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ eyikeyi tí wọ́n gbà nínú ayé yí.

Tẹ̀