Fún Okun Àwọn Ọ̀dọ́
Ìbáṣepọ̀ Alàgbára Kan
Oṣù Kẹ́jọ 2024


Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́ , Oṣù Kẹ́jọ 2024

Ìbáṣepọ̀ Alágbára Kan

Májẹ̀mú kan ju àdéhùn lọ; ìbáṣepọ̀ kan ni.

àwọn àga aláwọ̀-ewé

Emi ṣi ní awòrán àwọn àga aláwọ̀-ewé tí Alàgbà Pistone àti Alàgbà Morasco fi joko nígbà tí wọ́n kọ́ ẹbí mi nínú ilé wa ní Argentina. Wọ́n kọ́ni pẹ̀lú agbára ti-ẹ̀mí lọ́pọ̀lọpọ̀ dé bí pé arábìnrin mi ọmọ ọdún mẹwa àti emi (ọdún mẹsan) yíò lọ fọwọ́kan àwọn aga náà lẹ́hìn tí wọn ti kúrò, ní ìrètí pé agbára náà yíò yí wa lára.

Láìpẹ́ mo kẹkọ pé agbára náà kò wá látinú àga ṣùgbọ́n látinú níní májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ kan pẹ̀lú Ọlọ́run àti Jésù Krístì.

Ìrírí Ìrìbọmi Mi

Mo dá májẹ̀mú àkọ́kọ́ ní Ọjọ́ Kẹtàlá Oṣù Kọkànlá, 1977. Èmi kò rántí púpọ̀ nípa ìrìbọmi mi, ṣùgbọ́n mo rántí tí Alàgbà Pistone nràn mi lọ́wọ́ sínú omi tí Alàgbà Morasco fi ẹsẹ̀ mi múlẹ̀ nígbàtí irun mi ṣi tutù. Bákannáà mo rántí ayọ̀ tí mo ní ìmọ̀lára rẹ̀ bí àwọn ọ̀rẹ́ titun wọ́ọ̀dù ṣe nfi dídìmọ́ra àti ìfẹnukoni fúnni ní ọ̀nà àwọn ara-Argentina àti ìfẹ́-inú líle tí mo mọ̀lára láti jẹ́ olotitọ ọmọbìnrin Baba Ọ̀run.

ẹbí níbi irìbọmi

Arábìnrin Spannaus kékeré (àárín) pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀ (ní apá òsì), arábìnrin rẹ̀ Silvina (jíjìn ní apá ọ̀tún), àti Alàgbà Morasco.

Lẹ́hìnnáà mo damọ̀ pé ayọ̀ tí mo ní ìmọ̀lára rẹ̀ nwá látinú ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Mo kẹkọ pé bí mo bá ti fi òtítọ́ pa àwọn májẹ̀mú mi pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́, Ẹ̀mí náà yíò wà pẹ̀lú mi. Ẹ̀mí Mímọ́ kàn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbùkún alágbára tí ó nwá látinú májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ kan pẹ̀lú Ọlọ́run àti Jésù Krístì.

Nísisìyí, àní nígbàtì àwọn ìdí, èrò, àti ìṣe mi bá dínkù, mo ní ìrètí láti tẹramọ́ gbígbìyànjú. Kínìdí? Nítorí ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa nmu ṣeéṣe fún mi láti tún àwọn májẹ̀mú mi ṣe kí n sì dá àwọn májẹ̀mú titun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Mo fi ìmoore hàn gidi fún ìbùkún náà.

Májẹ̀mú Ìbáṣepọ̀, Ìyárí Kan

À ngbọ́ léraléra pé àwọn májẹ̀mú ni ọ̀nà-méjì tí a fi nṣe àwọn ìlérí ní àárín wa àti Ọlọ́run. Nígbàtí ìyẹn jẹ́ òtítọ́, èyí kìí ṣe gbogbo ohun tí wọ́n jẹ́. Ní òdodo, “olùpamọ́ májẹ̀mú kìí ṣe òwò ṣíṣe ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ ìwúrí kan.”

Nítorínáà báwo ni ẹ ó ṣe dá májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ kan sílẹ̀ pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà? Wọ́n fẹ́ràn yín ní pípé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì fẹ́ láti bùkún yín (wo 3 Nefi 14:11). Ṣùgbọ́n ìbáṣepọ̀ ọ̀nàkọ́ná méjì ngba àkokò àti ìfẹ́ láti ẹ̀gbẹ́ méjèjì.

Ṣé ẹ̀ nfẹ́ láti lo àkokò síi pẹ̀lú Wọn? Nígbàtí ẹ bá ṣe àwọn ohun tí Wọn ó ṣe, ẹ̀ nrìn pẹ̀lú Wọn! Ìyẹn lè jẹ́ ìrọ̀rùn bí fífetísílẹ̀ sí ọ̀rẹ́ ní ìgbà àkokò líle kan, mímú àkokò láti ṣeré pẹ̀lú tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan, tàbí pẹ̀lú ẹnìkan tí ó nímọ̀lára ìpatì. Láìpẹ́, mo lo àkokò ní rírìn pẹ̀lú Ọlọ́run nípa gbígba ohun ìfiránṣẹ́ sílẹ̀ àti fífi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ kan ní Argentina ẹnití ó nní ìmọ̀lára ìdánìkanwà. Bákannáà mo pinnu láti pa ìwé-ìkaniyẹ mi mọ́ ní aápọn nítorí kí nlè lo àkokò pẹ̀lú Oluwá nínú ilé mímọ́ Rẹ̀. Ẹ lè gbàdúrà fún àwọn èrò tí yíò ràn yín lọ́wọ́ láti lo àkokò pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà yín.

Ṣé ẹ fẹ́ láti fihàn Wọ́n pé ẹ ní aájò? Ẹ ṣesí àwọn òfin tí ẹ ti dá májẹ̀mú láti pamọ́ bí ọ̀nà kan láti fi ìfẹ́ yín hàn, kìí ṣe bí títòsílẹ̀ àwọn òfin. Fún àpẹrẹ, láti gbé Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n, mo kọ́ bí mo ti lè se àwọn oúnjẹ afúnnilókun. Nísisìyí mò nkọ́ àwọn ọmọbìnrin mi láti ṣe bákannáà. Bí ẹ ti nfi ìfẹ́ pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ìfẹ́ yín fún Un àti Olùgbàlà yíò gbèrú.

Àwọn májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì yíò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ̀ Wọ́n dáradára kí a sì ní ààyè púpọ̀ sí agbára Wọn nínú ayé wa—láìlòpin ju ohunkóhun tí àkójọ àwọn aga aláwọ̀-ewé lè fúnni. Àti pé agbára náà yíwapadà títíláé!

Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ann M. Madsen, nínú Truman G. Madsen, Tẹ́mpìlì Náà: Níbití Ọ̀run Ti Pàdé Ayé (2008), 69.