Ọ̀rọ̀ Àjọ Olùdarí Kínní, oṣù kẹ́rin ọdún 2013
Ó Jíìnde
Ẹ̀rí kan nípa ti dídájú àjíìnde ti Jésù Krístì jẹ́ orísun ìrètí kan àti ìpinnu bákannáà. Ó sì lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún èyíkéyí ọmọ ti Ọlọ́run. Ó jẹ́ ọjọ́ kan fún mi ní ìgbà ẹ̀rùn ní oṣù kẹfà 1969 nígbàtí ìyá mi kú, ó ti rí bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọdún látigbà náà, àti pé bẹ́ẹ̀ni yíò rí títí èmi ó ri lẹ́ẹ̀kansi.
Ìbànújẹ́ kúrò ní ìyapa ránpẹ́ ni o rọ́pò ìdùnnú lọ́gán. Ó ti pọ̀ ju ìrètí kan lọ fún àtúnpadà-dàpọ̀ kan. Nítorí Olúwa ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ hàn nípa àwọn wòlíì Rẹ̀ àti pé nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti fẹsẹ̀ òtítọ́ ti àjíìde múlẹ̀ sí mi, mo lè rí nínú iyè-inú mi ohun tí yíò dàbí láti di àtúnpadà-wàpapọ̀ pẹ̀lú olùyàsímímọ́ wa àti àwọn olùfẹ́ wọnnì tó ti jíìnde:
“Àwọn wọ̀nyí ni àwọn wọnnì tí yíò jáde wá nínú àjíìde ti olódodo. …
“Àwọn wọ̀nyí ni àwọn wọnnì tí a kọ àwọn orúkọ wọn sọ́run, níbi tí Ọlọ́run àti Krístì jẹ́ adájọ́ ti ohun gbogbo.
“Àwọn wọ̀nyí ni àwọn olódodo ènìyàn tí a ṣe ní pípé nípa Jésù Olùlàjà ti májẹ̀mú tuntun, ẹni tí ó ṣàṣe jáde ètùtù pípé yí nípa ìtàsílẹ̀ ti ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀” (D&C 76:65, 68–69).
Nítorí Jésù Krístì já àwọn ìdè ti ikú, gbogbo àwọn ọmọ ti Bàbá Ọ̀run tí a bí sínú ayé náà yíò jíìde ní ara kan tí kò ní kú láéláé. Nítorínáà ẹ̀rí mi àti tìrẹ nípa ti òtítọ́ ológo lè mú ìtani ti àdánù àyànfẹ́ ọmọ ẹbí kan kúrò tàbí ọ̀rẹ́, kí ó sì rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ìfojúsọ́nà àti ìpinnu tódájú.
Olúwa ti fi ẹ̀bùn àjíìde fún gbogbo wa, níbití wọ́n gbé àwọn ẹ̀mí wa sí nínú àwọn ara tó gba ìtúsílẹ̀ àwọn rírí àìpé (rí Alma 11:42–44). Ìyá mi yíò farahàn bí ọ̀dọ́ àti ìtànṣán, àwọn ìyọrísí ọjọ́ orí àti àwọn ọdún ti ìjìyà rírí ti kúrò. Tí yíò wá fun àti sí wa gẹ́gẹ́bí ẹ̀bùn kan.
Ṣùgbọ́n àwọn wọnnì lára wa tí ó ńgbèrò láti wà pẹ̀lú rẹ̀ láèláè gbọ́dọ̀ mú agbára láti yàn wọn yege fún ẹgbẹ́ náà, láti gbé níbi tí Bàbá àti Àyànfẹ́ Ọmọkùnrin Rẹ̀ tó jíìnde ńgbé nínú ògo. Ìyẹn ni ibì kanṣoṣo èyítí ìgbé ayé ẹbí ti lè tẹ̀síwájú títí ayérayé. Ẹ̀rí kan nípa ti òtítọ́ náà ti mú ìpinnu mi pọ̀si láti yege ara mi àti àwọn wọnnì tí mo fẹ́ràn fún ipò tó ga jù lọ ní ìjọba cẹ̀lẹ́stíà (rí D&C 76:70).
Olúwa fi ìtọ́nà kan fùn wa ní ìwákiri wa fún ìyè ayérayé nínú àwọn àdúrà oúnjẹ Olúwa tí ó ńrànmí lọ́wọ́ àti pé ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́. A pè wá láti tún àwọn májẹ̀mú ìrìbọmi wa ṣe ní gbogbo ìpàdé Oúnjẹ Olúwa.
A ṣèlérí láti rántí Olùgbàlà náà nígbàgbogbo. Àwọn àmì ti Ètùtù Rẹ̀ ńrànwá lọ́wọ́ láti mọ iyì títóbi ti iye tí Ó san láti já àwọn ìdè ikú , láti fi àánú fún wa, àti láti pèsè ìdáríjì ti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tí a bá yàn láti ronú pìwàdà.
A ṣèlérí láti pà àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Kíka àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ ti àwọn wòlíì alààyè àti fífetísílẹ̀ sí àwọn olùsọ̀rọ̀ ìmísí ní àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa ńrán wa létí ti àwọn májẹ̀mú wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀mi Mímọ́ ńṣàmúwa àwọn òfin tí a nílò jù láti pamọ́ lọ́jọ́ náà sí àwọn iyè inú àti ọkàn wa.
Nínú àwọn àdúrà Olúwa, Ọlọ́run ṣe àwọn ìlérí láti rán Ẹ̀mí Mímọ́ náà láti wà pẹ̀lú wa (see Moroni 4:3; 5:2; D&C 20:77, 79) Mo ti ri ní ìṣẹ́jú akàn pé Ọlọ́run lè fún mi ní ohun tí ó dàbí ìmọ̀ara ti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ara ẹni kan. Ó ńṣàmúwá sí ìfojúsí mi ohun tí mo ti ṣe tí ó mú inú Rẹ̀ dùn, nínílò mi fún ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì, àti àwọn orúkọ àti àwọn ojú ti ènìyàn tí Òun yíò jẹ́ kí nsìn fún Un.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, ìrírí lèraléra náà ti yí ìrètí padà sí àwọn ìmọ̀làra ti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ tí ó mú ìdánilójú wá pé àánú ṣílẹ̀kùn fún mi nípa Ètùtù ti Olùgbàlà àti Àjíìde.
Mo jẹ́rí pé Jésù ni Krístì àjíìde, Olùgbàlà wa, àti àpẹrẹ pípé wa àti atọ́nà sí ìyè ayérayé.
© Ọdún 2013 nípasẹ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/12. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/12. Àyípadà èdè ti First Presidency Message, April 2013. Yoruba. 10664 779