2013
Dídarí nípa Ìgbàgbọ̀
July 2013


Ọ̀dọ́

Dídarí nípa Ìgbàgbọ̀

Akọ̀wé yìí ngbé ni North Carolina, USA.

Èmi kò ní jẹ́ gbàgbé láé rírin àwọn ilẹ̀ ní Winter Quarters, Nebraska, USA, níbi tí àwọn olùlànà tí gbé ní ọ̀pọ̀ ọdún tẹ́lẹ̀. Ilẹ̀ náà ní ìmọ̀-inú mímọ́, bí ẹnipé mò ńṣe àbẹ̀wò tẹ́mpílì tí ó wà níta.

Ojú mi kú fún omijé, tí ó bo ìran mi. Mo rí ère kan ṣùgbọ́n èmi kò lé dá àwọn àwòrán rẹ̀ mọ̀. Nígbà tí mo nu omijé mi kúrò, mo rí ọkùnrin àti obìnrin kan tí ojú wọn kún fún ẹ̀dùn. Bí mo ti ṣe wòó ní sísúnmọ́, mo rí àwòrán ọmọ ọwọ́ kan tí ó dùbúlẹ̀ ní sààrè kan ní ẹsẹ̀ wọn.

Ìran yìí mú mi kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìmí-ẹdùn: ìbànújẹ́, ìbínú, ìmoore, àti ayọ̀. Mo fẹ́ láti mú ìrora tí àwọn ènìyàn mímọ́ wọnnì ti ní kúrò, ṣùgbọ́n mo ní ìmoore nígbà kan náà fún ohun tí wọ́n ti fi rúbọ fún ìhìnrere.

Ìrírí mi ní Winter Quarters ràn mí lọ́wọ́ láti ní òyé pé Bàbá Ọ̀run nfún àwọn ọmọ Rẹ̀ ní ìhìnrere àti pé Ó ńfún wọn ní agbára láti yàn láti ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ pẹ̀lúrẹ̀. Àwọn òbí ọmọ ọwọ́ yẹn ti lè yàn láti gba ọ̀nà tó rọrùn. Títẹ̀lé wòlíì àti gbígbé ayé ìhìnrere nílò kí àwọn olùlànà yí tẹ̀síwájú bíótilẹ̀jẹ́ wípé ó túmọ̀ sí sínsin ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n yàn láti mú ìhìnrere wọnú ayé wọn atí láti gba àwọn ìpeniníjà wọn. Mo kẹ́kọ́ pé àwọn ìyàsímímọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ sí ìhìnrere àti ìpinnu wọn láti tẹ̀síwájú ní ìdarí nípa ìgbàgbọ́ àti ìrètí—ìrètí fún ọjọ́ iwájú dídán àti ìgbàgbọ̀ pé Olúwa mọ̀ wọ́n, àti pé Ó lè dẹ́kun ìrora wọn.

Tẹ̀