Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kéje Ọdún 2013
Ayé Nílò Àwọn Olùlànà Lóní
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ìrìn olùlànà ti ọdún 1847 kò bẹ̀rẹ̀ ní Nauvoo, Kirtland, Far West, tàbí New York ṣùgbọ́n yálà ní England, Scotland, Scandinavia, tàbí Germany jínjìn. Àwọn ọmọdé kónkóló kò lè ní òye kíkún ti ìgbàgbọ́ tí kò dúró jẹ́ tí ó fún àwọn òbí wọn lókun inú láti fi àwọn mọ̀lẹ́bì, àwọn ọ̀rẹ́, ìtùnnú, àti ìdáàbòbò sílẹ̀ lẹ́hìn.
Ẹni kékeré kan lè bèèrè, “Ìyá mí, kílódé tí à á nfi ilé sílẹ̀? Níbo ni à á nlọ?”
“Wá kálọ, ẹni iyebíye; à á nlọ sí Síónì, ìlú nlá ti Ọlọ́run wa.”
Láárín ìdáàbòbò ti ilé àti ìlérí ti Síónì ni ìbínú àti àrékérekè ti àwọn omi ti Atlantic nlá dúró sí. Ta ló lè ròhìn ìbẹ̀rù tí ó mú ọkàn ènìyàn láárín àwọn ìsọdá oníparun wọnnì? Ní ìṣílétí nípa ti àwọn ìsúfé ìdákẹ́jẹ́ ti Ẹ̀mí, ní ìmúdúró nípa ìgbàgbọ́ ìrọ̀rùn síbẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin, àwọn olùlànà ènìyàn mímọ́ náà gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run wọ́n sí gbé ìṣíkọ̀ kalẹ̀ sórí ìrìnàjò wọn.
Níkẹhìn wọ́n dé Nauvoo à fi láti tún jáde lẹ́ẹ̀kansi ní ìdojúkọ àwọn ìṣòro lórí ipa ọ̀nà náà. Àwọn òkúta-ibòji ti sage àti òkúta sàmì sí àwọn sààrè ní gbogbo ipa ọ̀nà náà láti Nauvoo dé ilú nlá Salt Lake. Irú bẹ́ẹ̀ ní iye tí lára àwọn olùlànà san. A sin ara wọn ní àláfíà, ṣùgbọ́n àwọn orúkọ wọn ńgbé àyè títí láé.
Àwọn akọ màlúù tí ó ti rẹ̀ fa igi, àwọn ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ẹrù npariwo, àwọn akíkanjú ọkùnrin ńṣe làálàá, àwọn ìlù ogun ńdún, àti pé àwọn ẹranko bíi kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nwu bí ajá. Ṣùgbọ́n ìgbàgbọ̀ tì ìmísí àti ìjì tó ti darí àwọn olùlànà náà ńtẹ̀síwájú síi. Nígbàkúgbà wọ́n nkọrin:
Wá, wá, ẹ̀nyin ènìyàn mímọ́, ẹ máṣe bẹ̀rù làálàá tàbí iṣẹ́;
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ayọ̀ kọjú mọnà rẹ.
Bí ìrìnàjò yí tilẹ̀ jẹ́ líle sí ọ,
Ore-ọ̀fẹ́ yíò dàbí ọjọ́ rẹ. …
Gbogbo nkan jẹ́ dídára! Gbogbo nkan jẹ́ dídára!1
Àwọn olùlànà wọ̀nyí rántí àwọn ọ̀rọ̀ ti Olúwa: “A ó bẹ àwọn ènìyàn mi wò nínú ohun gbogbo, kí wọ́n ba lè múra sílẹ̀ láti gba ògo tí Mo ní fún wọn, àní ògo ti Síónì.”2
Àkókò tó kọjá lọ nmú àwọn ìrántí wa ṣókùnkùn àti ìmoore wa dínkù fún àwọn tí ó rin ọ̀nà ti ìrora, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ sẹ́hìn ipa ọ̀nà àmì-omijé ti àwọn sààrè àláìlórúkọ. Ṣùgbọ́n báwo ní àwọn ìpeniníjà tòní? Ṣé kò sí àwọn ọ̀nà olókúta láti rìnrìnàjò, kò sí àwọn òkè tí ó nípọn láti gùn, kò sí àwọn ọ̀gbùn láti sọdá, kò sí àwọn ipa ọ̀nà láti là, kò sí àwọn odò láti fẹsẹ̀ làjá? Tàbí njẹ́ àìní wà nísisìyí gan fún ẹ̀mí olùlànà náà láti tọ́ wa kúrò ní àwọn ìparun tí ó nlérí láti bò wá mọ́lẹ̀ kí ó sì darí wa sí ìdáàbòbò ti Síónì kan?
Ní àwọn ọdọdún méwèwá láti ìparí Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ìdíwọ̀n ìwà rere tí dínkù léraléra. Iṣẹ́ àlébù ńyípo sókè; ìwà tótọ́ ńdojú kọ lẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà lórí ọkọ̀ ìjàmbá òmìrán agbénisóke-gbénikalẹ̀ nlá kan, tí wọ́n nwá àwọn ìwárìrì ohun ti ìgbà yí ní fífi àwọn ayọ̀ ti ayérayé ṣèrúbọ. Nípa bẹ́ẹ̀ a pàdánù àláfíà.
A gbàgbé bí àwọn ara Greece àti ará Rómù ṣe lékè lọ́nà ológo nínú ayé àìlajú kan àti bí ìṣẹ́gun náà ṣe parí—bí àìjáfara àti pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ní ìkẹhìn ṣe borí wọn lọ sí ìparun wọn. Ní ìparí, ju bí wọ́n ti ṣe fẹ́ òmìnira, wọ́n fẹ́ ìdáàbòbò àti ayé onítùnú, wọ́n sì sọ gbogbo ìtùnú àti ìdáàbòbò àti òmìnira nù.
Má ṣe yọ̀nda fún àwọn ìtànjẹ ti Sátánì; yálà, dúró ṣinṣin fún òtítọ́. A kò le è tẹ́ àwọn ìpóngbẹ àìnítẹ́lọ́rùn ti tẹ̀mí-tara lọ́rùn nípa ìwákiri àìlópin fún ayọ̀ ní àárín àwọn ìyára ti àìbalẹ̀ ọkàn àti ìwà búburú. Ìwà búburú kò lè darí sí ìwà rere láé. Ìkóríra kò lè mú ìfẹ́ gbòòrò si láé. Ìṣojo kò lè fúnni ní ìgboyà láé. Iyèméjì kò lè ṣe ìmísi ìgbàgbọ̀ láé.
Ó nira fún àwọn kan láti farada àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gan àtí ìbàjẹ́ tí àwọn òmùgọ̀ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ń fi ìpamọ́ra ẹni, ìṣòtítọ́ àti ìgbọràn sí àwọn àṣẹ ti Ọlọ́run ṣe yẹ̀yẹ́. Ṣùgbọ́n láé ní ayé kò ti ka pípa ìpìnlẹ̀ṣẹ̀ mọ́ sí. Nígbà tí a pàṣẹ fún Nóà kí ó kọ́ ọkọ̀ ìgbàlà, àwọn òmùgọ̀ èrò wojú ọ̀run tí kò ní ìkùúkùú, àti pé nígbà náà wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ wọ́n sìí ńpariwo—títí dìgbà tí òjò náà dé.
Njẹ́ ó yẹ kí a kọ́ ìrú àwọn ẹ̀kọ́ oníyebíye bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kànkan si? Àkókò nyí padà, ṣùgbọ́n òtítọ́ dúró títí. Nígbà tí a bá kùnà láti jèrè lára àwọn ìrírí tí ìgbà tó ti kọjá, a ti ṣègbé láti tún ṣe wọn pẹ̀lú gbogbo ìrora ọkàn, ìjìyà, àti àròkàn. Ṣé a kò ní ọ̀gbọ́n láti gbọ́ràn sí Ẹni tí ó mọ ìbẹ̀rẹ̀ láti òpin—Olúwa wa, tí ó gbèrò ìlànà ìgbàlà—sànju ejò náà, tí ó kóríra ẹwà rẹ̀.
Ìwé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan ṣàlàyé olùlànà gẹ́gẹ́bí “ẹnití ó ńlọ ṣíwájú láti pèsè tàbí láti ṣí ọ̀nà fún àwọn míràn láti tẹ̀lé.”3 Njẹ́ a lè, bá kan, ṣe àkójọpọ̀ ìgboyà àti ìdúróṣinṣin ti èrò tí ó jẹ́ bí ìwà àwọn olùlànà ti ìràn tẹ́lẹ̀? Njẹ́ ìwọ àti èmi, ní tòótọ́ gan, lè jẹ́ olùlànà?
Mo mọ̀ pé a lè jẹ́ bẹ́ẹ̀. Àá, bí ayé ṣe nílò àwọn olùlànà lóní!
© Ọdún 2013 nípasẹ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/13. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/13. Àyípadà èdè ti Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kéje Ọdún 2013. Yoruba.10667 779