2014
Ìlérí ti ìyípadà ọkàn náà
July 2014


Ọ̀rọ̀ Àjọ Alákóso Gbogbogbò, Oṣù Kéje Ọdún 2014

Ìlérí ti ìyípadà àwọn ọkàn náà

Àwòrán
Alákóso Henry B. Eyring

Ìyá mi, Mildred Bennion Eyring, nínú ìlú àwọn olóko ti Granger, Utah, USA. Ìkan lára àwọn arákùnrin rẹ̀, Roy, tẹ̀lé òwò ìdílé ti títọ́jú àgùtàn. Gẹ́gẹ́bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ó ńlo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀sẹ̀ kúrò nílé. Bí àsìkò ṣe ńlọ ó dínkù ní ìfẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ. Nígbà tí ó yá ó kúrò lọ sí Idaho, USA, ó gbéyàwó, ó sì ní àwọn ọmọ mẹ́ta. Ó kú ní ọjọ́ orí ọgbọ̀n ó lé mẹ́rin nígbàtí ìyàwó rẹ̀ jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n àti pé àwọn ọmọ rẹ̀ kéré.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹbí Roy kékeré wà ní Ìdaho àti pé ìyá mi ti kúrò níbí ẹgbẹ̀rún méjì ólé ọgọ́rún márún máìlì (ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé márúndínlọ́gbọ̀n kilómítà) sí New Jersey, USA, ó ńfìgbà púpọ̀ kọ àwọn lẹ́tà ìfẹ́ àti ìgbìyànjú sí wọn. Ẹbí ti arákùnrin ìyá mi ńfi ìfẹ́ kíkún tọ́ka sí ìyá mi bíi “Àùntí Mid.”

Àwọn ọdún kọjá lọ, àti pé níjọ́ kan mo gba ìpè tẹlifónù látọ̀dọ̀ ìkan lára àwọn cousin arábìnrin mi. Wọ́n sọ fún mi pé opó Roy ti kú. Cóùsìn mi sọ pé, “Àùntí Mid yíò fẹ́ láti mọ̀.” Àùntí Mid ti kú ti pẹ́ sẹ́hìn, ṣùgbọ́n ẹbí rẹ̀ ṣì ńní ìmọ̀lára ìfẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ńnawọ́ jáde láti sọ fún mi.

Mo ní ìfọwọ́tọ́ nípa bí ìyá mi ṣe ṣe ojúṣe irúkannáà nínú ẹbí rẹ̀ bí àwọn wòlíì Nífáì ṣe ṣe ojúṣe nínú àwọn ẹbí wọn nípa dídúró pẹ́kípẹ́kí sọ́dọ̀ àwọn ìbátan tí wọ́n fẹ́ láti mú wá sínú ìhìnrere ti Jésù Krístì. Nífáì kọ àkọsílẹ̀ kan pé òun nírètí tí yíò nípá lórí àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ láti padà sí ìgbàgbọ́ ti Bàbáńlá wọn, Léhì. Àwọn ọmọ Mòsíàh fi irú ìfẹ́ kannáà hàn bí wọ́n ṣe ńwàásù ìhìnrere sí àwọn àtẹ̀lé ti Léhì.

Olúwa ti pèsè àwọn ọ̀nà fún wa láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ nínú àwọn ẹbí tí ó lè tẹ̀síwájú títíayé. Àwọn ọ̀dọ́mọdé nínú Ìjọ lóní ńní ìmọ̀lára ọkàn wọn tó ńyípadà sí ẹbí wọn. Wọ́n ńṣàwárí àwọn orúkọ ti ọmọ ẹbí wọn tí kò ní ànfàní láti gba àwọn ìlànà ti ìgbàlà nínú ayé yí. Wọ́n mú àwọn orúkọ wọnnì lọ sí tẹ́mpìlì. Nígbàtí wọ́n wọnú omi ìrìbọmi, wọ́n ní ànfàní láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ti Olúwa àti ti ọmọ ẹbí ẹnití wọ́n ńṣe ìrọ́pọ̀ àwọn ìlànà fún.

Mo lè rántí ìfẹ́ nínú ohùn ti cóùsìn mi tí ó pè mí tí ó sì sọ pé, “Ìyá wa ti kú àti pé Àùntí Mid yíò fẹ́ kí o mọ̀.”

Àwọn wọnnì lára yín tí ó ṣe àwọn ìlànà fún ẹbí ńnawọ́ jáde ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọ Mòsíàh àti wòlíì Nífáì náà ti ṣe. Bíiti wọn, ìwọ yíò ní ìmọ̀lára ayọ̀ fún àwọn wọnnì tí ó tẹ́wọ́gba ẹbọ yín. Bákannáà o lè nírétí láti ní ìmọ̀lára irú ìtẹ́lọ́rùn ńlá bákannáà bíiti Ámmọ́nì, ẹnití ó sọ nípa iṣẹ́ ìsìn àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ láárín àwọn ọmọ ẹbí jíjìn.

“Nítorínáà, ẹ jẹ́ kí a ṣògo, bẹ́ẹ̀ni, a ó ṣògo nínú Olúwa, bẹ́ẹ̀ni a ó yọ̀, nítorí ayọ̀ wa kún; bẹ́ẹ̀ni, a ó yin Ọlọ́run wa títíláé. Kíyèsi, tani ó lè ṣògo jù lọ nínú Olúwa? Bẹ́ẹ̀ni, tani ó lè sọ púpọ̀ jù nípa agbára ńlá rẹ̀, àti ti àánú rẹ̀, àti ti ìjìyà pípẹ́ rẹ̀ síwájú àwọn ọmọ ènìyàn? Kíyèsíi, mo sọ fún yín pé, èmi kò lè ní ìmọ̀lára ipa tó kéré jù lọ” (Álmà 26:16)

Mo ṣe ìjẹ́rí pé àwọn ìmọ̀lára ti ìfẹ́ tí ẹ ní fún ọmọ ẹbí yín—níbikíbi tí wọ́n lè wà—jẹ́ ìmúṣẹ ti ìlérí pé Èlíjàh yíò wá. Ó sì wá. Ọkàn àwọn ọmọ ńyípadà sí bàbá wọn, àti pé ọkàn àwọn bàbá ńyípadà sí àwọn ọmọ wọn (rí Málákì 4:5–6; Ìwé Ìtàn—Koseph Smith 1:38–39). Nígbàtí ẹ bá ní ìmọ̀lára láti wá àwọn orúkọ ti àwọn bàbáńlá yín àti láti mú orúkọ wọ̀nyí lọ sí tẹ́mpìlì, ẹ̀ ńní ìrírí ìmúṣẹ ti àsọtẹ́lẹ̀ náà.

Ó jẹ́ ìbùkún láti gbé ní àsìkò ìgbàtí ìlérí ti ọkàn yíyípadà ńwá sí ìmúṣẹ. Mildred Bennion Eyring ní ìmọ̀lára ìtẹramọ́ nínú ọkàn rẹ̀. Ó fẹ́ràn ẹbí arákùnrin rẹ̀, àti pé ó sì nawọ́ jáde sí wọn. Wọ́n ní ìmọ̀lára ọkàn wọn tó yípadà nínú ìfẹ́ sí Àùntí Mid nítorí wọ́n mọ̀ pé ó fẹ́ràn wọn.

Tẹ̀