Ọ̀rọ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù Kárún Ọdún 2016
Òun Yíò Gbé Ọ Lé Èjìká Rẹ̀ Yíò Sì Gbé Ọ Lọ Sílé
Gẹ́gẹ́bí Olùṣọ́ Àgùtàn Rere ṣe rí Àgùtàn rẹ̀ tí ó nù, tí ẹ ó bá gbé ọkàn yín sókè sí Olùgbàlà aráyé, Òun yíò wáa yín rí.
Ọ̀kan lára àwọn ìrántí málegbàgbé ipò èwe mi bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú igbe ti agogo ìkìlọ̀ tí ó ngba inú afẹ́fẹ́ lati ọ̀ná jíjìn tí ó njí mi lójú oorun. Kí ó tó pẹ́, ìró míràn, ariwo tí kò hàn àti kíkùn àwọn abẹ̀bẹ̀ ọkọ̀, ó npọ̀ si díẹ̀díẹ̀ títí tí ó fi mi èfúùfù tìtì. Bí ìyá wa ṣe ti tọ́ wa dádáa, àwa ọmọ kọ̀ọ̀kan gbé àpò wa a sì sáré lọ órí òkè síbi ààbò ajónirun kan. Bí a ṣe nyára nínú alẹ́ dúdú, ahọ́n iná aláwọ̀ ewé àti funfun njábọ́ láti inú òfúrufú láti ṣe àmì àwọn àfojúsùn fún àwọn olùjọ́nirun. Ó ṣe àjèjì dé bí pé, olúkúlùkù npe àwọn ahọ́n iná wọ̀nyí ní àwọn igi Kérésìmesì.
Mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rí kan sí àgbáyé nígbà ogun.
Dresden
Kò jìnà sí ibi tí àwọn ẹbí mi gbé rí ni ìlú nla Dresden wa. Àwọn wọ̃nnì tí wọ́n gbé nìbẹ̀ ti jẹ́rí sí bóyá bíi ìgbà ẹgbẹ̀rún ohun tí mo ti rí. Àwọn ìjì iná líle tó wúwo, tí ó ṣẹlẹ̀ nípasẹ̀ ẹgbẹgbẹ̀rún òṣùwọ̀n tá àwọn ohun ìjà olóró aláriwo, tí ó gbálẹ̀ káàkiri Dresden nù, ní pípa bíi ìdá àádọ́rũn ìlú nlá náà run ati ní fífi àwọn òkúta wíwó àti eérú sílẹ̀ ní jíjí dìde wọn.
Ní ìgbà tí kò pẹ́ rárá, ìlú nlá tí a ti fún ní orúkọ ìnagijẹ “Àpótí Àlùmọ́nì” kò sí mọ́. Erich Kastner, olùkọwé kan tí ó jẹ́ German, kọ nípa ìparun náà, “Ní ẹgbẹ̀rún ọdún ni a kọ́ ẹwà rẹ̀, ní alẹ́ kan ni ó parun pátápátá.”1 Ní ìgbà èwe mi èmi kò le fi ojú inú wo bí ìparun ti ogun kan tí àwọn ènìyàn tiwa bẹ̀rẹ̀ ṣe le jẹ́ bíborí láé. Ayé ní àyíka wa farahàn pátápátá bíi aláìnírètí ati aláìní ọjọ́ ọlà kankan.
Ní ọdún tó kọjá mo ní ànfàní láti padà sí Dresden. Àádọ́rin ọdún lẹ́hìn ogun náà, lẹ́ẹ̀kansíi, ó jẹ́, “Àpótí Àlùmọ́nì” ìlú nlá kan. Wọ́n ti kó àwọn èérún kúrò, wọ́n sì ti mú ìlú nlá náà padàbòsípò àní wọ́n sì ti tũnṣe.
Ní ìgbà ìbẹ̀wò mi mo rí ìjọ Lutheran dídára, Frauenkirche, Ìjọ ti Ìyáàfin wa. Tí wọ́n kọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ní àwọn ọdún 1700, ó ti jẹ́ ọ̀kàn lára àwọn alumọ́nì dídán ti Dresden rí, ṣùgbọ́n ogun ti dín in kù sí ìdọ̀tí tí a kójọ. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ó dúró bẹ́ẹ̀, títí tí wọ́n fi pinnu pé wọ́n ó tún Frauenkirche kọ́.
Àwọn òkúta láti inú ìjọ tí ó ti parun náà ni wọ́n tí kójọ tí wọ́n sì tọ́ju, ati pè nígbà tí ó ṣeéṣe, wọ́n lòó nínú àtúnkọ́ náà. Ní òní ẹ lè rí àwọn òkúta àjókù dúdú wọ̀nyí tí wọ́n hàn lára ògiri ìta. “Àwọn àpá” wọ̀nyí kìí ṣe ìránnilétí ti ìwé ìtàn ogun ti ilé yí nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ó jẹ́ ohun ìrántí lati ní ìrètí—àmì títayọ kan ti agbára ènìyàn láti dá ìgbé ayé titun láti inú eérú.
Bí mo ṣe njíròrò lóri ìtàn Dresden tí mo sì nníyanu lórí ọgbọ́n ati ìpinnu ti àwọn wọ̃nnì tí wọ́n mú ohun tí ó ti parun patápátá padàbọ̀sípò, mo ní ìmọ̀lára dídùn ti agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Dájúdájú, mo ronú , tí ènìyàn bá lè mú èérún, èérún, àti ìyókù ìlú nlá tí ó ti fọ́ wẹ́wẹ́ tí wọ́n sì ṣe àtúnkọ́ ilé àrà onímísí kan tí ó ga sókè lọ síwájú àwọn ọ̀run, báwo ni Bàbá wa Elédùmarè ṣe lágbára síi tó láti mú àwọn ọmọ Rẹ̀ tí wọ́n ti ṣubú, tiraka, tàbí sọnù padàbọ̀sípò?
Kò jẹ́ nkan bí ó ti wù kí ó dà bíi pé ìgbé ayé wa ti ṣègbé pátápátá tó. Kò jẹ́ nkan bí ó ti wù kí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa pupa tó, bí ìkorò wa ṣe jinlẹ̀ tó, tí a nìkan wà, ti a jẹ́ pípatì, tàbí bí ọkàn wa ṣe lè bàjẹ́ tó. Àní àwọn wọnnì tí wọ́n wà lainí ìrètí, tí wọ́n ngbé nínú asán, tí wọ́n ti dalẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé, ti wọ́n ti ju ìwà òtítọ́ wọn sílẹ̀, tàbí yípadà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run le di títúnṣe. Bí kò ṣe àwọn ọmọ ègbé tí kò wọ́pọ̀, kò sí ìgbé ayé kan tí ó fọ́nká tó bẹ́ẹ̀ tí kò le ṣe é mú padàbọ̀sípò.
Ìrọ̀hìn aláyọ̀ ti ìhìnrere ni èyí: nítorí ètò ìdùnnú ayérayé tí Bàbá wa Ọ̀run onífẹ̀ẹ́ pèsè àti nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin ti Jésù Krístì náà, a kò lè ní ìràpadà nìkan láti inú ipò ìṣubú wa kí a sì padàbọ̀sípò sí ìwà mímọ́, ṣùgbọ́n bákannáà a lè kọjá àwọn àfinúrò ti ara ikú kí a sì di ajogún ìyè ayérayé àti alábápín ògo àìlèjúwe ti Ọlọ́run.
Òwe Àgùtàn tí ó Sọnù
Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà, àwọn ọlórí ẹlẹ́sìn ti ọjọ́ Rẹ̀ kò faramọ́ kí Jésù maa lo àkókò pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n kà sí “àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Bóyá sí wọ́n ó dàbíí pé Òun nfaradà tàbí ó ngba ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ra. Bóyá wọ́n gbàgbọ́ pé ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti ran ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà ni nípa dídá wọn lẹ́bi, bíbù wọ́n kù, àti dídójú tì wọ́n
Nígbàtí Olùgbàlà fura ohun tí àwọn Pharisee àti àwọn akọ̀wé nrò, Ó sọ ìtàn kan:
“Ọkùnrin wo ni nínú nyín, tí ó ní ọgọ́rún àgùtàn, bí ó bá sọ ọ̀kan nù nínú wọn, tí kì yíò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rún ìyókù sílẹ̀ ní ijù, tí kì yíò sì tọsẹ èyí tí ó nù lọ, títí yíò fi ríi?
Nígbà tí ó sì ti ri tán, ó gbe lé èjìká rẹ, ó nyọ̀.”2
Ní àwọn ọgọọ́gọ̀rún ọdún tó ti kọjá, òwe yí ni wọ́n ti fi àṣà túmọ̀ sí bíi ìpè sí ìṣe fún wa láti mú àwọn àgùtàn tí ó sọnù padà wá àti pé kí a nàwọ́ jáde sí àwọn wọnnì tí wọ́n ti sọnù. Ní ìgbàtí èyí tọ̀nà tí ó sì dára dájúdájú, mo nrò pé bóyá nkan míràn wà ní ìdí rẹ̀.
Njẹ́ ó ṣeéṣe pé kí èrò ti Jésù, lákọ́kọ́ àti ṣíwájú, jẹ́ láti kọ́ni nípa iṣẹ́ ti Olùṣọ́ Àgùtàn Rere?
Njẹ́ ó ṣeéṣe pé Ó njẹ́ ẹ̀rí ti ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ aláìgbọràn?
Njẹ́ ó ṣeéṣe pé ọ̀rọ̀ Olùgbàlà ni pé Ọlọ́run mọ̀ dáadáa nípa àwọn wọnnì tí wọ́n sọnù—ati pé Òun yíò wá wọn rí, pé Òun yío nàwọ́ jáde sí wọn, ati pé Òun yío gbà wọ́n là?
Bí èyíinì bá rí bẹ́ẹ̀, kíni àgùtàn gbọ́dọ̀ ṣe láti yege fún ìrànlọ́wọ́ ti ọ̀run yí?
Njẹ́ àgùtàn nílò láti mọ̀ bí a ṣe nlo àwọn ohun èlò ìtọ́jú ilé Ọlọ́run tí ó gbọgbón láti ṣírò ìdarí ìbú rẹ̀? Njẹ́ ó nílò láti lè lo GPS kan láti túmọ̀ ipò rẹ̀? Njẹ́ ó ní láti ní amòye láti dá áppì kan silẹ̀ tí yíò pè fún ìrànlọ́wọ́? Njẹ́ àgùtàn nílò ìfọwọ́sí láti ọ̀dọ̀ onígbọ̀wọ́ kan kí Olùṣọ́ Àgùtàn Rere tó lè wá gbàlà?
Rárá. Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Àgùtàn náà yẹ fún ìgbàlà ti ọ̀run jẹ́jẹ́ nítorí Olùṣọ́ Àgùtàn Rere fẹ́ràn rẹ̀.
Sí mi, òwe àgùtàn tó sọnù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ ọ̀rọ̀ tí ó kún fún ìrètí jùlọ nínú gbogbo ìwé mímọ́.
Olùgbàlà wa, Olùṣọ́ Àgùtàn Rere, mọ̀ Ó sì fẹ́ràn wa. Ó mọ̀ Ó sì fẹ́ràn yín.
Ó mọ ìgbà tí ẹ̀yin bá sọnù, Ó sì mọ ibi tí ẹ wà. Ó mọ ìbànújẹ́ yín. Àwọn ẹ̀bẹ̀ ìdákẹ́jẹ́ yín. Àwọn ẹ̀rù yín. Àwọn ẹkún yín.
Kò jẹ́ nkan bí ẹ ṣe di sísọnù—bóyá nítorí àwọn àṣàyàn yín tí kò dára tó ni tàbí nítorí àwọn ipò tí ó kọjá agbára yín.
Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé ẹ jẹ́ ọmọ Rẹ̀. Òun sì fẹràn yín. Ó fẹ́ràn àwọn ọmọ Rẹ̀.
Nítorí Ó fẹ́ràn yín. Òun yíò wá yín rí. Òun yíò gbée yín lé èjìká Rẹ̀ ní yíyọ ayọ̀.Nígbàtí ó bá gbée yín wá sílé, Òun yíò sọ fún ọ̀kan àti gbogbo wọn pé, “Ẹ bá mi yọ; nítorí mo ti rí àgùtàn mi tí ó sọnù.” Nígbàtí ó bá sì gbée yín wá sílé, Òun yíò sọ fún ọ̀kan àti ẹni gbogbo pé, “Ẹ bá mi yọ; nítorí mo ti rí àgùtàn mi tí ó sọnù.”3
Kíni A Gbọ́dọ̀ Ṣe?
Ṣùgbọ́n ẹ lè máa ronú pé, kíní ohun náà? Dájúdájú mo níláti ṣe ju dídúró lásán lọ láti kàn jẹ́ gbígbàlà .
Nígbàtí ó wu Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ pé kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ padà sí ọ́dọ̀ Rẹ̀, Òun kò ní fi tipátipá mú ẹnikẹ́ni lọ sí ọ́run.4 Ọlọ́run kò ní gbà wá là ní ìlòdì sí ìfẹ́ inú wa.
Nítorínáà kíni a gbọ́dọ̀ ṣe?
Ìfipè Rẹ̀ rọrùn:”
Yípadà … sí mi.”5
“Wá sọ́dọ̀ mi.”6
Súnmọ́ mi èmi ó sì sún mọ́ ọ.”7
Èyí ni bí a ṣe lè fi hàn Án pé a fẹ́ di gbígbàlà
Ó bèèrè fún ìgbàgbọ́ kékeré kan. Ṣùgbọ́n ẹ máṣe sọ ìrètí nù.Tí ẹ kò bá lè lò ìgbàgbọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ nísisìnyí, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrètí. Tí ẹ kò bá lè ṣe àkójọ ìgbàgbọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ nísisìnyí, ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìrètí.
Tí ẹ kò bá lè sọ pé ẹ mọ pé Ọlọ́run wà níbẹ̀, ẹ lè ní ìrètí pé Òun wà. Ẹ lè ní ìfẹ́ inú láti gbàgbọ́.8 Èyí ti tó láti bẹ̀rẹ̀.
Nígbànáà, ní ṣíṣe ìṣe lórí ìrètí náà, ẹ nawọ́ jáde sí Bàbá Ọ̀run. Ọlọ́run yíò nawọ́ ìfẹ́ Rẹ̀ sí ọ̀nà ọ̀dọ̀ yín, àti pé iṣẹ́ ìgbàlà àti ìyípadà Rẹ̀ yíò sì bẹ̀rẹ̀.
Ní àkokò, ẹ̀yin yíò dá ọwọ́ Rẹ̀ mọ̀ nínú ayé yín. Ẹ ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀. Àti pé ìfẹ́ láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ àti láti tẹ̀lé ọ̀nà Rẹ̀ yíò gbèrú síi pẹ̀lú ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ kọ̀ọ̀kan tí ẹ̀ ngbé.
A npe àwọn ìṣísẹ̀ ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ní “ìgbọ́ran.”
Èyí kìí ṣe ọ̀rọ̀ olókìkí kan lọ́jọ́ òní. Ṣùgbọ́n ìgbọ́nran ni èrò inú ti a nṣìkẹ́ nínú ìhìnrere ti Jésù Krístì nítorí a mọ̀ pé “nípasẹ̀ Ètùtù ti Krístì, gbogbo ènìyàn lè ní ìgbàlà, nípa ìgbọ́ran sí àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà Ìhìnrere.”9
Bí a ṣe npọ̀ síi nínú ìgbàgbọ́, bákannáà a gbọ́dọ̀ pọ̀ síi nínú ìṣòdodo. Ṣíwájú mo ṣe àtúnsọ ọ̀rọ̀ olùkọ̀wé kan tí ó jẹ́ German tí ó ráhùn ìparun Dresden. Bákannáà Ó kọ́ sílẹ̀ ní gbólóhùn ọ̀rọ̀ yí: “Es gibt nichts Gutes, ausser man tut es.” Fún àwọn wọnnì tí kìí sọ èdè sẹ̀lẹ́stíà, èyí ni a ṣe àyípadà èdè rẹ bíi “Kò sí ohun kan tí ó jẹ́ rere àyàfi tí ẹ bá ṣeé.”10
Ẹyin àti èmi lè sọ̀rọ̀ jíjágeere jùlọ nípa ti àwọn ohun ẹ̀mí. A lè fún àwọn ènìyàn ní ìwúrí pẹ̀lú ìtumọ̀ ọlọ́gbọ́n lórí àwọn àkórí nípa ẹ̀sìn. A lè sọ̀rọ̀ bíi ewì nípa èsìn kí a sì “lá àlá nípa ibùgbé [wa] lókè.”11 Ṣùgbọ́n tí ìgbàgbọ́ wa kò bá yí ọ̀nà ìgbé ayé wa padà—tí àwọn ohun tí a gbàgbọ́ kò bá fún àwọn ìpinnu ojojúmọ́ wa lágbára—ẹ̀sìn wa já sí asán, àti pé ìgbàgbọ́ wa, tí kò bá kú, dájúdájú kò dára àti pé ó wà nínú ewu ti ìṣubú nígbẹ̀hìn.12
Ìgbọ́ran ni ẹ̀jẹ̀ ìyè ti ìgbàgbọ́. Nípa ìgbọ́ran ni a kó ìmọ́lẹ̀ jọ sínú ẹ̀mí wa
Ṣùgbọ́n ní àwọn ìgbà míràn mo rò wipe à kìí ní òye ìgbọ́ran. A lè ri ìgbọ́ràn bíi pé ó jẹ́ òpin nínú ara rẹ̀, ju kí ó jẹ́ ọ̀nà sí òpin kan. Tàbí a lè gún òòlù àfijúwe ti ìgbọ́ran lórí irin anvil ti àwọn òfin nínú ìlàkàkà kan láti mú àwọn tí a fẹ́ràn wà ní ìbámu, nípa fífi bọná nígbàkugbà kí a sì lùú léraléra sínú àwọn ohun mímọ́ síi, níti ọ̀ràn ọ̀run.
Kò sí iyèméjì nípa rẹ̀, àwọn ìgbà míràn wà tí a nílò ìpè gidi sí ìrònúpìwàdà. Dájúdájú, àwọn díẹ̀ wà tí a lè dé ọ̀dọ̀ wọn ní ọ̀nà yí nìkan.
Ṣùgbọ́n bóyá àfiwé tí ó yàtọ̀ kan wà tí ó lè ṣe àlàyé ìdí tí a fi ngbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run. Bóyá ìgbọ́ran kìí ṣe ètò kan tó bẹ́ẹ̀ ti títẹ̀, lílọ́, àti gígún ẹ̀mí wa sínú ohun kan tí a kò jẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ètò nípa èyí tí à nṣe àwárí ohun tí a jẹ́ gan an.
Ọlọ́run Elédùmarè ni ó dá wa. Òun ni Bàbá wa Ọ̀run. A jẹ́ Ẹ̀mí ọmọ Rẹ̀ bí ó ti rí. A dáwa pẹ̀lú ohun èlò àrà ìyebíye jùlọ tí títúnṣe wọn ga jù, àti pé nípa báyìí a ngbé ohun ti ọ̀run nínú ara wa.
Níhĩn lórí ilẹ̀, bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ , àwọn èrò wa àti àwọn ìṣe ndi kíkópọ̀ pẹ̀lú èyí tí ó bàjẹ́, tí kò mọ́, àti èléèrí. Erùpẹ̀ náà àti ẹ̀gbin ti ayé ndọ̀tí àwọn ẹ̀mí wa, ó nsọ ọ́ di ṣíṣòro láti damọ̀ àti láti rántí ẹ̀tọ́ ìbí wa àti èrò.
Ṣùgbọ́n gbogbo èyí kò lè yí irú ẹni tí a jẹ́ nítòótọ́ padà. Àwọn ìpìlẹ̀ àtọ̀runwá ti ìwà àbínibí wa wà síbẹ̀. Àti pé lójú ẹsẹ̀ tí a bá yàn láti fi ọkàn wa sí ọ̀dọ̀ olùfẹ́ wa Olùgbàlà tí a sì gbé ẹsẹ̀ wa sí ipá ọ̀nà ti ọmọ ẹ̀hìn, ohun ìyanu kan nṣẹlẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run kún ọkàn wa; ìmọ́lẹ̀ ti òtítọ́ kún inú wa; a bẹ̀rẹ̀ láti ju ìfẹ́ lati dẹ́ṣẹ̀ nù, àti pé a kò fẹ́ rìn nínú òkùnkùn mọ́.13
A kò rí ìgbọ́ran bí ìjìyà kan mọ́ ṣùgbọ́n bí gbígba ara wa sílẹ̀ ní ipá ọ̀nà sí àyànmọ́ ti ọ̀run wa. Àti pé díẹ̀díẹ̀, ìbàjẹ́ náà, erùpẹ̀, àti àwọn ìdíwọ́ ti ilẹ̀ ayé yí yíò já kúrò. Nígbẹ̀hìn, àìdíyelé, ẹ̀mí ayérayé ti ọ̀run tí ó wà nínú wa yíò hàn, ìtànṣán ìwàrere a di ìwà àbínibí wa.
Ẹ yẹ fún Ìgbàlà
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, Mo jẹ́rí pé Ọlọ́run rí wa bí a ṣe jẹ́ bí a ṣe wà nítòótọ́—Ó rí wa pé a yẹ fún ìgbàlà.
Ẹ lè ní imọ̀lára pé ìgbé ayé yín ti bàjẹ́. Ẹ lè ti dẹ́ṣẹ̀. Ẹ lè máa bẹ̀rù, bínú, ṣọ̀fọ̀, tàbí ìfìyàjẹ nípa iyèméjì. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí Olùṣọ́ Àgùtàn Rere ṣe rí àgùtàn rẹ̀ tó sọnù, tí ẹ ó bá gbé ọkàn yín sókè sí Olùgbàlà aráyé, Òun yíò wá yín rí.
Òun yíò gbà yín là
Òun yíò gbé e yín sókè yíò sì gbé yín lé èjìká Rẹ̀.
Òun yíò gbé yín lọ Sílé
Tí ọwọ́ ara ikú bá lè yí èrún àti eegun padà sí ilé ìjọsìn dídára kan, nígbànáà a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé olólùfẹ́ Ọlọ́run wa lè, yíò sì tún wa ṣe. Ètò Rẹ̀ ni láti mú wa dúró nínú ohun kan tó ga ju ohun tí a jẹ́ tẹ́lẹ̀ lọ—gíga ju bí a ṣe lè ro láéláé lọ. Pẹ̀lú ìṣísẹ̀ ti ìgbàgbọ́ tí à ngbé ní ọ̀nà ọmọ ẹ̀hìn, à ndàgbà sínú ènìyàn ológo ayérayé àti ayọ̀ àìlópin tí wọ́n ṣe wá láti dà.
Èyí ni ẹ̀rí mi, ìbùkún mi, àti àdúrà ìgbàgbọ́ ìrẹ̀lẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Ọgá wa, ní orúkọ Jésù Krístì, àmìn.
© 2016 by Intellectual Reserve, Inc.All rights reserved. A tẹẹ ní USA Àṣẹ Gẹẹsì 6/15. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/15 Àyípadà Èdèti Visiting Teaching Message, May 2016. Yoruba 12865 779