Ọdọ
Nígbàtí ọ̀rẹ́ mi kú
Olùkọ̀wé náà ńgbé ní Utah, USA
Ní ìgbà ìṣíwájú mi nílé ìwé gíga, ọ̀rẹ́ mi ní àrùn ọpọlọ ó sì kú níjọ́ kejì. Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo jẹ́ ọmọ ìjọ, mo ṣì ntiraka. Mo ti gba ẹ̀kọ́ ní gbogbo ayé mi pé mo lè yípada sí Bàbá Ọ̀run àti Olùgbàlà fún ohunkóhun, ṣùgbọ́n èmi kò tíi ní láti la irú ohun báyìí kọjá tẹ́lẹ̀rí.
Mo sọkún fún ọ̀pọ̀lọpọ́ wákàtí, ní ìgbìyànjú láti rí ohun kan—ohunkohun—láti fún mi ní àláfíà. Alẹ́ náà lẹ́hìn ikú rẹ̀, mo yípadà sí ìwé orin. Bí mo ṣe nṣí àwọn ojú ewé náà, Mo dé orí “Bá Mi Gbé; Ó ti di Ọjọ́rọ̀” (Àwọn orin, no. 165). Ẹsẹ kẹ́ta hàn gbangba sí mi:
Bá Mi Gbé, Ní Ọjọ́rọ̀ Yí
Àti pé àdáwà ni òru náà yíò jẹ́
Tí èmi kò bá lè bá ọ sọ̀rọ̀
Tàbí wá ìmọ́lẹ̀ mí nínú rẹ̀.
Òkùnkùn ayé, ni mo bẹ̀rù
Pé yíò gbé nínú ilé mi
Ah Olùgbàlà, Dúró pẹ̀lú mi ní alẹ́ yí;
Kíyèsi, ó ti di Ọjọ́rọ̀ .
Ẹsẹ yí kún inú mi pẹ̀lú àláfíà púpọ̀. Mo mọ̀ nígbà náà pé kìí ṣe pé Olùgbàlà lè dúró ní alẹ́ náà pẹ̀lú mi nìkan ṣùgbọ́n bákannáà pé Òun mọ irú ìmọ̀lára tí mo nní gan an. Mo mọ̀ pé ìmọ̀lára ìfẹ́ ti mo ní nípa orin náà kìí ṣe pé ó mú mi la òrù ọjọ́ náà já nìkan ṣùgbọ́n ó mú mi la ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àdánwò míràn ti mo ti faradà já.