2017
Pé Kí Wọ́n Lè Jẹ́ Ọ̀kan
July 2017


Ọ̀rọ̀ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù Kéje Ọdún 2017

Pé Kí Wọ́n Lè Jẹ́ Ọ̀kan

Ẹ fi tàdúrà-tàdúrà ṣe àṣàrò ohun èlò yìí kí ẹ sì lépa fún ìmísí lati mọ ohun tí ẹ ó ṣe àbápín. Báwo ni níní òye èrò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ṣe nmúra àwọn ọmọbìnrin Ọlọ́run sílẹ̀ fún àwọn ìbùkún ìyè ayérayé?

Relief Society seal

Ìgbàgbọ, Ẹbí, Ìranlọwọ

“Jésù ṣe àṣeyege ìrẹ́pọ̀ pípé pẹ̀lú Bàbá nípa fífi ara Rẹ̀ sílẹ̀, méjèèjì ẹ̀mí àti ara, sí ìfẹ́ ti Baba,” ni Alàgbà D. Todd Christofferson ti Iyejú àwọn Apọ́stélì Méjìlá kọ́ni.

“… Dájúdájú a kò ní jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run àti Krístì títí a ó fi jẹ́ kí ìfẹ́ inú àti ààyò Wọn di ohun tí ó tóbi jùlọ tí a fẹ́. A kò lè dé irú ipò ìjọ̀wọ́ araẹni sílẹ̀ yí ni ọjọ́ kan, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, Olúwa yíò kọ́ wá tí a ó bá ní ìfẹ́ títí di, ìgbà àsìkò, tí a ó lè sọ ní rẹ́gí pé Òun wà nínú wa gẹ́gẹ́bí Bàbá ṣe wà nínú Rẹ̀.”1

Linda K. Burton, Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, kọ́ni bí a ṣe lè ṣiṣẹ́ sí ipa ọ̀nà ìrẹ́pọ̀ yí: “Ṣíṣe àti pípa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ jẹ́ ìfihàn ìfọkànsìn wa láti dà bíi Olùgbàlà. Èrò náà ni láti làkàkà fún ìwà tí ó dára jùlọ tí a fi hàn nínú àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ ààyò orin kan : Èmi ó lọ ibi tí o fẹ́ kí nlọ. … Èmi ó sọ ohun tí o fẹ́ kí nsọ . … Èmi ó jẹ́ ohun tí o fẹ́ kí njẹ́.’”2

Alàgbà Christoferson bákannáà rán wá létí pé “Bí a ṣe ńssa ipá wa lójoojúmọ́ àti lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti tẹ̀lé ipa ọ̀nà ti Krístì, ẹ̀mí wa ntẹnumọ́ títayọ rẹ̀, ogun làárín wa nwálẹ̀, àwọn ìdánwò ndáwọ́ dúró láti dàni láàmú.”3

Neill F. Marriott, Olùdámọ̀ràn Kejì nínù Àjọ Ààrẹ Gbogbogbò ti àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin, jẹ́ ẹ̀rí ti àwọn ìbùkún ìlàkàkà láti jẹ́kí ìfẹ́ wa wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ti Ọlọ́run: “Mo ti tiraka láti mú ìfẹ́ ayé ikú kúrò láti ní àwọn nkan ní ọ̀nà ti ara mi ní ìgbẹ̀hìn dídá mọ́ pé ọ̀nà mi kò tó, ní òpin, àti pé ó jẹ́ òfegè sí ọ̀nà ti Jésù Krístì. Ọ̀nà‘[ti Bàbá Wa Ọ̀run]ni ipá ọ̀nà tí ó darí sí ìdùnnú ní ayé yí àti ìyè ayérayé ní ayé tó nbọ̀.’”4 Ẹ jẹ́ kí a fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ làkàkà láti di ọ̀kan pẹ̀lú Bàbá wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.

Àfikún àwọn Ìwé Mímọ́ àti Ìwífúnni

John 17:20–21; Àwọn Ará Éfésù 4:13; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 38:27; reliefsociety.lds.org

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. D. Todd Christofferson, “Kí Wọ́n Lè Jẹ́ Ọ̀kan nínú wa,” Liahona, Nov. 2002, 71

  2. Linda K. Burton, “Agbára náà, Ayọ, àti Ìfẹ ti Pípa Májẹmú Mọ” Amọ̀nà, Osù Kọkànlá 2013, 111.

  3. D. Todd Christofferson, “Kí Wọ́n Lè Jẹ́ Ọ̀kan nínú wa,” Liahona, Nov. 2002, 71

  4. Neill F. Marriott, “Fífi Ọkàn Wa Fún Ọlọ́run,” Liahona, Nov. 2015, 32.