Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kejì(Erele)2019
Mímú Àánú Gbèrù Si láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́
Mímú Àánú Gbèrù Si láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ. Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́. A lè gbe àwọn ẹlòmíràn ga bí a ṣe ngbìyànjú láti ní òye ohun tí wọ́n nní ìrírí rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe lè fihàn pé a ní ìfẹ́ láti rìn nínú rẹ̀ pẹ̀lú wọn.
Nítorí Bàbá wa Ọ̀run nfẹ́ kí a dà bíi Tirẹ̀, àwọn ìpèníjà tí à ndojúkọ nínú ayé yí lè di áwọn ànfàní ìkẹ́ẹ̀kọ́ tí a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀ tí a sì dúró lórí ipá ọ̀nà. Láìlóríre, dídúró lórí ipá ọ̀nà lè nira gidi nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára bíì ípé à ndojúkọ àwọn àdánwò wọ̀nnì fúnra wa.
Ṣùgbọ́n a kò nílàti dá rìn ní ipá ọ̀nà náà. Olúgbàlà ṣe àṣepé àánú pipe, ó sọ̀kalẹ̀ kọjá ohun gbogbo kí Òun lè mọ láti tu wá nínú, nínú àwọn ìpọ́njú àti àìlera wa (wo Álmà 7:11–12; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 122:8). Ó lérò kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ kí a sì fi àánú hàn bákannáà. Gbogbo ọmọ Ìjọ ti dá májẹ̀mú láti “ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tó nṣọ̀fọ̀; bẹ́ẹ̀ni, àti láti tu àwọn tó nfẹ́ ìtùnú nínú” (Mosiah 18:9). Pẹ̀lú àwọn ìpènijà ti ara wa, a kọ́ nínú gbogbo ìwé mímọ́ láti yípadà pátápátá kí a sì “gbé ọ̀wọ́ èyí to relẹ̀ sókè, kí a fún [eékún] aláìlera lókun” ki a sì “mú ipá ọ̀nà wọn lọ tààrà fún ẹsẹ̀ yín, kí èyí tí ó yarọ lè kúrò ní ipá ọ̀nà” (Hébérù 12:12–13; bákannáà wo Isaiah 35:3–4; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 81:5–6).
Bí a ṣe nmú àwọn ẹlòmíràn dání, ẹ jẹ́ kí wọ́n gbára lé wa, kí wọ́n sì rìn pẹ̀lú wọn, a nràn wọ́n lọ́wọ́ làti dúró ní ipá ọ̀nà tó gùn tó fún Olùgbàlà kìí ṣe láti yí wọn padà nìkan—ọ̀kan lára kókó àwọn èrò ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́—ṣùgbọ́n bákannáà láti wò wọ́n sàn (wo Doctrine and Covenants 112:13).
Kíni ìwàrere jẹ́?
Àánú ni níní òye ìmọ̀lára, èrò, àti ipò ẹlòmíràn látinú ìgbìrò wọn sànju ti ara wa lọ.1
Jíjẹ́ aláàánú ṣe pàtàkì nínú ìtiraka wa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn àti mìmù èrò wa ṣẹ bí arákùnrin àti arábìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́. O fi ààyè gbà wá láti fi ara wa sípò àwọn ẹlòmíràn.
Rírìn nínú ipò àwọn ẹlòmíràn
A sọ ìtàn náà nípa ọkùnrin onìtijú Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ẹni tí ó máa ndá joko ní ìlà ẹ̀hìn ilé ìjọsìn. Nígbàtí ọmọ iyejú àwọn alàgbà kan bá kú lójijì, bíṣọ́ọ̀pù yíò fi àwọn ìbùkún oyèàlùfáà fún àwọn ọmọ ẹbí alàgbà náà láti tù wọ́n nínú. Àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ gbé oúnjẹ wa. Àwọn ọ̀rẹ́ dídára àti aladugbo ṣè abẹ̀wò pẹ̀lú ẹbí náà wọ́n sì wípé, “Ẹ jẹ́ kí a mọ̀ tí ó bá ní ohun tí a lè ṣe láti ṣèrànwọ́.”
Ṣugbọ́n nígbàtí ọkùnrin onítijú yí bẹ ẹbí náà wò lọ́jọ́ náà, ó tẹ aago-ìlẹ̀kùn àti pé nígbàtí opó náà dáhùn, ó kàn sọ jẹ́jẹ́ pé, “mo wá láti nu àwọn bàtà yín ni.” Ní wákàtí díẹ̀, gbogbo àwọn bàtà ẹbí náà ti mọ́ ó sì ndán ní ìmúrasílẹ̀ fún ìsìnkú. Ní Ọjọ́ ìsinmi tó tẹ́le ẹbí alàgbà olóògbé náà joko lẹgbẹ onìtìjú ọkùnrin náà ní ìlà ẹ̀hìn.
Nihin ni ọkùnrin tí ó dí ipò ìnílo àìlèṣe. Àwọn àti òun di alábùkún nípa ìtọ́nisọ́nà-àánú ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbèrú Si Nínú Àánú?
Àwọn miran di alábùkún pẹ̀lú ẹ̀bùn láti lè ní àánú. Ṣùgbọ́n fún àwọn wọnnì tí wọ́n nlàkàkà, ìròhìn rere wà. Ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́hìn, ọ̀pọ̀ ìdàgbàsókè àwọn oluwádìí ló ti kọ́ àánú. Nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn nwá láti àkórí pẹ̀lú onírurú àbádé, ọ̀pọ̀ lára wọn gbà pé àánú jẹ́ ohun kan tí a lè kọ́.2
A lè gbàdúrà fún ẹ̀bùn àánú. Ní ètò láti dára si, bakánnáà ó jẹ́ ìrànwọ́ láti ní òye dídárasi nípa bí àánú ṣe nṣiṣẹ́. Àwọn àbá wọ̀nyí wọ́pọ́ bíi kókó àwọn ohun èlò ti àánú.3 Nígbàtí ìwọ̀nyí máa nṣẹlẹ̀ àní láìsí ìtara pé wọ́n nṣẹlẹ̀, níní ìfura wọn nfún wa ní ààyè láti rí àwọn ànfàní láti dára si.
1.Ní òye
Àánú nfẹ́ níní òyè nípa ipò àwọn ẹlòmíràn. Bí a bá ṣe ní òye ipò wọn dáradára sí, ni yíò fi rọrùn láti ní òye bí wọ́n ṣe lé ní ìmọ̀lára nípa rẹ̀ àti ohun tí a lè ṣe láti ṣèrànwọ́.
Fifi aápọn fetísílẹ̀, ní bíbèèrè àwọn ìbèèrè, àti dídámọ̀ràn pẹ̀lú wọn àti àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ìṣe pàtàkì fún níní òyè ipò wọn. Kọ́ ẹ̀kọ́ si nípa àwọn ìṣètò wọ̀nyí nínu àwọn ohun Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Síṣe Ìṣẹ́ ìránṣẹ:
-
“Àwọn Ohun Marun tí Olùfẹtísílẹ̀ Rere Nṣe,” Liahona, June 2018, 6.
-
“Dámọ̀ràn Nípa àwọn Àìní Wọn,” Liahona, Sept. 2018, 6.
-
“Gbígba àwọn Míràn Láàyè nínú Iṣẹ́ Ìránṣẹ́—Bí ó ṣe Ṣeéṣe.” Liahona,Oct. 2018, 6.
Bí a ṣe nwá láti ní òye, a gbọ́dọ̀ mù àkokò láti ní òye kókó ipò wọn sànju ṣíṣe àròsọ lòrì ẹlòmíràn tí ó ní irú ìrírí kannáà. Bíkòṣebẹ́ẹ̀, a lè sọ àmì náà nù kí a sì fi wọ́n sílẹ̀ nínú àìlóye.
2. Ròó
Nínú itiraka wa láti pa májẹ̀mú wa mọ́ láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí o nṣọ̀fọ̀ kí a sì tu àwọn wọnnì tí ó wà nínú ìnílò ìtùnú ninu, a lè gbàdúrà fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti ní òyè ohun tí ẹnìkan lè ní ìmọ̀lára rẹ̀ àti bí a ṣe lè ṣèrànwọ́.4
Lẹ́ẹ̀kan tí a bá ti ní òye ipò ẹnìkan, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa—bóyá ó ṣẹlẹ̀ níti àdáyébá tàbí bẹ́ẹ̀kọ́—lè lọ nínú ríro ohun tí a ó ronú tàbí ní ìmọ̀lára nínú ipò náà lé. Níní òye àwọn èrò wọnnì àti ẹ̀dùn-ọkàn, pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́, lè ṣèrànwọ́ ìtọ́sọ́nà ìdáhùn wa sí ipò wọn.
Bí a ṣe wá láti ní òye àwọn ipò ẹlòmíràn tí a sì nrò bí wọn ṣe lè ní ìmọ̀lára, ó ṣe pàtàkì pé kí a maṣe dáwọn lẹ́jọ́ láìtọ́ (wo Matthew 7:1). Jíjẹ́ ọlọfintoto bí ẹnìkan ṣe dé ipò náà lè darí wa láti dín ìrora tí ipò náà dá sílẹ̀ kù.
3. Fèsì
Bí a ṣe nfèsì ṣe pàtàkì nítorí pé ìyẹn ni àánú tí a nfi hàn. Àwọn ọ̀nà àìlónkà wà láti bánisọ̀rọ̀ òye wa látẹnu àti àìsọ̀rọ̀ látẹnú. Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé ìfojúsùn wa kìí ṣe láti yanjú wàhálà. Nígbàkugbà ìfojúsùn náà ni láti gbé sókè jẹ́jẹ́ àti láti fúnni lókun nípa jíjẹ́ kí wọ́n mọ pè wọn ko dánìkan wà. Èyí lè túmọ̀ sí sísọ pé, “Inúmi dùn tí o sọ fún mi” tàbí “Ma bínú. Èyí gbọ́dọ̀ nípalára.”
Ní gbogbo ọ̀ràn ìfèsì wa gbọ́dọ̀ jẹ́ òtítọ́. Àti pé nígbàtí ó bá tọ́, fífí ara sílẹ̀ tobẹ́ẹ̀ láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn rí àwọn àìlera àti àìláàbò lè dá ọgbọ́n ìsopọ̀ oníyebíye sílẹ̀.
Ìpè láti ṣe ìṣe
Bí ẹ ṣe ngbèrò àwọn ipò àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún, ẹ ro wíwà nínú ipò wọn àti ohun tí ẹ ó rí pé ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ jùlọ tí ẹ bá wà ní ipò wọn. Gbàdúrà láti ní òye bí wọn ṣe lè ní ìmọ̀lára àti láti tẹ̀le e. Ìfesì yín lè rọrùn, ṣùgbọ́n yíò nítumọ̀.
© 2019 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹẹ ní USA Àṣẹ Gẹẹsì 6/18. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/18. Ìyírọ̀pada éde Ministering Principles, February 2019. Yoruba. 15763 779