2019
Mímú Síṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Jẹ́ Aláyọ̀
Oṣù Kẹrin 2019


ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹta Kerin 2019

Mímú Síṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Jẹ́ Aláyọ̀

Sísìn pẹ̀lú ifẹ́ nmú ayọ̀ wá fún olùfúnni àti olùgba bákannáà.

Nígbàmíràn ìwákiri wa fún ìdúnnú nínú ayé yí lè dàbí sísáré lórí ìlọkùn. À nsáré a sì nsáré síbẹ̀síbẹ̀ a nní ìmọ̀lára bíi pé a kò tíì dé ìbì kankan rárá. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, èrò ti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn kan dàbí fífi ọ̀pọ̀ kùn ìṣe láti ṣe ni.

Ṣùgbọ́n Bàbá wa Ọ̀run nfẹ́ kí a nì ìrírí ayọ̀ Ó sì ti sọ fún wa pé “ènìyàn wà, kí wọ́n lè ní ayọ̀” (2 Nífáì 2:25). Àti pé Olùgbàlà kọ́ni pé ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ apákan pàtàkì bí a ṣe lè mú ayọ̀ wá sínú ìgbé ayé wa àti ìgbé ayé àwọn ènìyàn míràn.

Kíni ìwàrere jẹ́?

Ayọ̀ ni a túmọ̀ sí “ímọ́lára `ìgbádùn àti ìdùnnú nlá.”1 Àwọn wòlíì Ọjọ́-ìkẹhìn ti pèsè ìsọdimímọ̀ lórí ibi tí ayọ̀ tí nwá àti bí a ti nri i. “Ìmọ̀lára ayọ̀ tì à nní kò ní í ṣe púpọ̀ pẹ̀lú àwọn ipò ìgbé ayé wa, ó sì ní ohun gbogbo í ṣe pẹ̀lú ìfojúsùn ìgbé ayé wa, “ ni Ààrẹ Russel M. Nelson wí.” … Ayọ̀ nwá láti ọ̀dọ̀ àti nítorí [Jésù Krístì]. Òun ni orísun gbogbo ayọ̀.”2

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Nmú Ayọ̀ Wá

Nígbàtí Léhì ṣe àbápín èso igi ìyè, ẹ̀mí rẹ̀ kún “fún ayọ̀ nlá púpọ̀” (1 Nephi 8:12). Ìfẹ́ inú rẹ̀ àkọ́kọ́ ni láti pín èso yí pẹ̀lú àwọn tí ó fẹ́ràn.

Síṣetán wa láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn lè mú irú ayọ̀ yí wá fún wa àti sí wọn. Olùgbàlà kọ́ àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ pé èso tí à nmú wa nígbàtí a ba ní ìsopọ̀ sí I nṣe ìrànwọ́ láti mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ wá fún wa (wo John 15:1–11). Ṣíṣe iṣẹ́ Rẹ̀ nípa sísìn àti wíwá láti mú àwọn ẹlòmíràn wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ lè jẹ́ ìrírí aláyọ̀ (wo Lùkù 15:7; Álmà 29:9; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 18:16; 50:22). A lè ní ìrírí ayọ̀ yí àní ni ojú àtakò àti ìjìyà (wo 2 Awọn Ará Kọ́ríntì 7:4; Colossians 1:11).

Olùgbàlà fi àpẹrẹ pìpè hàn wá, pé ọ̀kan lára àwọn orísun títóbi jùlọ ti ayọ̀ òtítọ́ nínú ayé ikú ni a nrí nípasẹ̀ iṣẹ́ ìsìn. Nígbàtí a bá ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa bii ti Olùgbàlà, pẹ̀lú ìfẹ́ àìlẹ̀gbẹ́ àti ìfẹ́ nínú ọkàn wa, a lè ní ìrírí ayọ̀ tí ó kọjá ìdùnnú lásán.

“Bí a ṣe tẹ́wọ́gba [ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́] pẹ̀lú ọkàn síṣetán, a ó … súnmọ́ dída àwọn ẹnìyàn Síónì à ó sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ayọ̀ títayọ pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a ti rànlọ́wọ́ ní ẹgbẹ́ ipá ọ̀nà ọmọlẹ́hìn,” ni Arábìnrin Jean B. Bingham, Ààrẹ Gbogbògbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ kọ́ni.3

Báwo Ni A Ṣe Lè Mú Kí Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Jẹ́ Aláyọ̀ Si?

Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà láti mú ayọ̀ títóbi ju wá sínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa. Nihin ni àwọn èrò díẹ̀:

  1. Ẹ ní òye èrò yín nínú síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Àwọn èrèdí púpọ̀ wà láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Nígbẹ̀hìn, àwọn aápọn wa gbọ́dọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn èrò ti Ọlọ́run “láti ṣe ìmúṣẹ ìyè ayérayé àti àìkú ènìyàn” (Moses 1:39). Bí a ṣe ntẹ́wọ́gba ìpè Ààrẹ Russell M. Nelson láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ní ẹ̀gbẹ́ ipá ọ̀nà májẹ̀mú, a lè rí ayọ̀ ní kíkópa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run.4 (Fún ọ̀pọ̀ síi lórí èrò ti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, wo “Àwọn Ẹ̀kọ́ Ipìlẹ̀ Ṣíṣé Iṣẹ́ Ìránṣẹ́: Èrò Tí Yíò Yí Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Wa Pada,” nínú Liahona.)

  2. Mú kí ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nípa àwọn ènìyàn máṣe jẹ́ iṣẹ́ ṣíṣe. Ààrẹ Thomas S. Monson nran wa léti lemọ́lemọ́: “Máṣe jẹ́ kí wàhàlà kan láti yanjú di pàtàkì ju ẹnikan láti fẹ́ràn.”5 Ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ nípá fífẹ́ràn àwọn ènìyàn, kìí ṣe nípa àwọn ohun láti ṣe. Bí a ṣe ndàgbà láti fẹ́ràn bí Olùgbàlà ti ṣe, a ó fi ààye gba ayọ̀ tí ó nwá láti inú sísin àwọn ẹlómíràn.

  3. Mú iṣẹ́ ìránṣẹ́ rọrùn. Ààrẹ M. Russell Ballard, Aṣojú Ààrẹ ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá, sọ fún wa pé: “Àwọn ohun nlá ní à nṣe nípasẹ̀ àwọn ohun kékeré àti rírọ̀rùn. … Àwọn ìṣe ìwàrere àti iṣẹ́ ìsìn wa kékeré àti rírọ̀rùn yíò kórapọ̀ sínú ìgbé ayé kíkún pẹ̀lú ìfẹ́ fún Bàbá Ọ̀run, ìfọkànsìn sí iṣẹ́ Olúwa Jésù Krístì, àti ọgbọ́n àláfíà àti ayọ̀ nìgbàkugbà tí a bá nawọ́ jade sí ara wa.”6

  4. Mu wàhàlà kúrò nínú ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Kìí ṣe ojúṣe yín láti mú ìgbàlà ẹnìkan ṣẹ. Èyí wà ní àárín ẹnì náà àti Olúwa. Ojúṣe wa ni láti fẹ́ràn wọn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yípadà sí Jésù Krístì, ẹnití í ṣe Olùgbàlà wọn.

Máṣe Mú Ayọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Kúrò

Ní ìgbà míràn àwọn ènìyàn máa nlọ́ra láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò, nítorínáà fífúnni ní iṣẹ́ ìsìn wa lè jẹ́ ohun tí wọ́n nílò gan. Ṣùgbọ́n fífi ipá mú àwọn ènìyàn fúnrawa kìì ṣe ìdáhùn, bakannáà. Bíbèèrè fún ààyè ṣíwájú ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ jẹ́ èrò rere.

Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ nípa ìyá àdáwà kan ẹnití ó ní ààrùn ilẹ̀-gbígbóna—tí àwọn ọmọ rẹ̀ náà sì ṣàìsàn bákannáà. Ile tí ó máa nmọ́ tónítóní tẹ́lẹ̀ wá di àìní-ìtọ́jú àti dídọ̀tí. Awọn àwo àti aṣọ kún ilẹ̀.

Ní àkokò kan nígbàtí ó ní ìmọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀ tán pátápátá, àwọn arábìnrin ẹgbẹ́ ìrànlọ́wọ́ kan ìlẹ̀kùn rẹ̀. Wọn kò sọ pé, “Jẹ́ kí a mọ tí a bá lè ṣèrànwọ́.” Nígbàtí wọ́n rí ipò náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́.

“Wọ́n pá gbogbo ìdọ̀tí náà mọ́, wọ́n mú ìmọ́lẹ̀ àti àyíká mímọ́ wá sínú ilé náà, wọ́n sì pe ọ̀rẹ́ kan láti mú àwọn oúnjẹ tí wọ́n nílò gan wá. Nígbà tí wọ́n parí iṣẹ́ wọn nígbẹ̀hìn tí wọ́n sì sọ pé ó dàbọ̀, wọ́n fì ìyá kékeré nàá sílẹ̀ nínú ẹkún—ẹkún ìmoore àti ìfẹ́.”7

Àwọn mèjèèjì olùfúnni àti olùgbà ní ìmọ̀lára ìdùnnú àti ayọ̀.

Ẹ Mú Ayọ̀ Gbèrú nínú Ayé Yín.

Bí ayọ̀, àláfíà, àti ìtẹ́lọ́rùn tí a lè mú gbèrú nínú ayé wá bá ṣe pọ̀ sí, ni a ó ṣe lè ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn sí bí a ṣe nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ayọ̀ nwá láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ (wo Galatians 5:22 àti Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 11:13). Ohun tí a lè gbàdúrà fún ni (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 136:29) tí a sì le pè wá sínú ayé wa. Nihin ni àwọn èrò díẹ̀ fún mímú ayọ̀ gbèrú nínú ìgbé ayé wa:

  1. Ka Àwọn Ìbùkún Rẹ Bi ẹ ṣe nyẹ ìgbé-ayé yín wo, ẹ kọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ti bùkún yín pẹ̀lú sínú ìwé ìròhìn yín.8 Ẹ ṣe akíyèsí gbogbo ohun rere ní àyíká yín.9 Ẹ fojúsí ohun tí ó lè máa pa yín mọ́ kúrò ní níní ìmọ̀lára ayọ̀, ki ẹ sì kọ àwọn ọ̀nà tí ẹ fi lè yanjú tàbí ní òye wọn dáradára síi sílẹ̀. Ní àkokò Àjíìnde yí, ẹ mú àsìkò láti wá ìsopọ̀ gíga ju pẹ̀lú Olùgbàlà (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 101:36).

  2. Ẹ gbìyànjú síṣe àfiyèsí. JẸE lè rí ayọ̀ si pẹ̀lú ìrọ̀rùn ní àkokò ìjíròrò kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.10 Fífi ètí sílẹ̀ tímọ́tímọ́ sí ohun tí ó nmú ayọ̀ wá (wo 1 Chronicles 16:15). Mímú àkokò kúrò ní ìbákẹgbẹ́ ìròhìn nígbàmíràn le di ṣíṣe láti gbìyànjú síṣe àfiyèsí.11

  3. Ẹ yera fún fífi arayín wéra. Wọ́n ti sọ wípé ìfiwéra ni olè ayọ. Páùlù kìlọ̀ pé àwọn wọnnì “tí wọ́n ndá òṣùwọ̀n arawọn fúnra wọn, àti tí wọ́n nfi ara wọn wéra laarin ara wọn, kò gbọ́n” (2 Corinthians 10:12).

  4. Ẹ wá ìfihàn araẹni. Olùgbàlà kọ́ni: “Tí ẹ bá bèèrè, ẹ ó gba ìfihàn lórí ìfihàn, ìmọ̀ lórí ìmọ̀, kí ẹ lè mọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ àti àláfíà—èyí tí ó nmú ayọ̀ wá, èyí tí ó nmú ìyè ayérayé wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 42:61).

Ìpè láti ṣe ìṣe

Báwo ni ẹ ṣe lè fi kún ayọ̀ tí ẹ̀ nrí nínú ayé yín nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́?

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. “Ayọ̀,” en.oxforddictionaries.com

  2. Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Ìtúsílẹ̀ Ẹ̀mí,” Liahona, Nov. 2016, 82.

  3. Jean B. Bingham, “Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìranṣẹ Bí Olùgbàlà ti Ṣe,” Liahona, May 2018, 106.

  4. Russell M. Nelson, “Bí A Ṣe N Tẹsiwaju Papọ̀,” Liahona, Apr. 2018, 7

  5. “Wíwá Ayọ̀ nínú Ìrìnàjò náà,” Amọ̀ná, Oṣù Kọkànlá. 2008, 88.

  6. M. Russell Ballard, “Rírí Ayọ̀ Nípa Níní-ìfẹ́ Iṣẹ́ Ìsin.” Liahona, May 2011, 49.

  7. Wo Dieter F. Uchtdorf, “Fífi Tayọ̀tayọ̀ Gbé Ìgbé-ayé Ìhìnrere,” Liahona, Nov. 2014, 120 120.

  8. Wo Henry B. Eyring, “Óò Rántí, Rántí,” Liahona, May 2007, –21.

  9. Wo Jean B. Bingham, “Kí Ayọ̀ Yín Lè Kún,” Liahona, May 2017, 87.

  10. Wo Dieter F. Uchtdorf, “Ti Àwọn Ohun tí Wọ́n Ṣe Pàtàkì Jùlọ,” Liahona, Nov. 2010, 22.

  11. Wo Gary E. Stevenson, “Ìṣíjibò Ẹ̀mí,” Liahona, Nov. 2017, 46.