2019
Báwo Ni A Ṣe Lè Dá Ọ̀làjú Wíwà-pẹ̀lú Ní Ìjọ Kan Sílẹ̀?
Oṣù Keje 2019


ministering

Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kéje 2019

Báwo Ni A Ṣe Lè Dá Ọ̀làjú Wíwà Ní Ìjọ Kan Sílẹ̀?

Nígbàtí a bá wo àyíká àwọn wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ká wa, à nrí àwọn ènìyàn tí ó dàbí pé wọ́n fìrọ̀rùn wà níbámu. Ohun tí a kò mọ̀ ni pé àní ní àárín àwọn wọnnì tí ó dábí pé wọ́n wà níbamu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa tó nímọ̀lára ìfisílẹ̀. Àṣàrò kan, fún àpẹrẹ, láìpẹ́ ri pé bí ààbọ̀ àwọn àgbàlagbà ní Ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni ìròhìn fìhàn pé wọ́n ní ìmọ̀lára àdáwà, ìfisílẹ̀, tàbí ìyàsọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn míràn.1

Ó jẹ́ pàtàkì láti ní ìmọ̀lára wíwà-pẹ̀lú. Ó jẹ́ ìpìlẹ̀ ìnílò ènìyàn kan, àti pé nígbàtí a bá ní ìmọ̀lára ìpatì, ó npanilára. Jíjẹ́ pípatì lè mú àbájáde àwọn ìmọ̀lára ìbànújẹ́ tàbí ìbínú wá.2 Nígbàtí a kò bá nímọ̀lára pe a wà pẹ̀lú, a nní ìtẹ́sí láti wá ibi kan tì a ti le nítura. A níláti ran gbogbo ènìyàn lọ́wọ́ láti nímọ̀lára pẹ́ wọ́n wà pẹ̀lú ìjọ.

Wíwà-pẹ̀lú Bíiti Olùgbàlà

Olùgbàlà ni àpẹrẹ pípé ti ìmọyì àti mimú àwọn míràn wà pẹ̀lú. Nígbàtí Ó yan àwọn Àpọ́stélì Rẹ̀, Kò kọbiara sí ipò, ọrọ̀, tàbí iṣẹ́ tójọjú. O fiyì fún obìnrin Ará Samáríà níbí kànga, ní jíjẹ́ẹ̀rí àtọ̀run wá Rẹ̀ sí obìnrin náà pẹ̀lú bí àwọn Júù ṣe ntàbùkù àwọn Ará Samáríà (wo Jòhánù 4). Ó nwo ọkàn àti pé kò lọ́wọ́ fún ipò àwọn ẹnìkẹ́ni (wo 1 Sámúẹ́lì 16:7; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 38:16, 26).

Olùgbàlà wípé:

“Òfin titun kan ni mo fi fún yín, Pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín; gẹ́gẹ́bí èmi ti fẹ́ràn yín, pé kí ẹ fẹ́ràn ara yín bákannáà.

“Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yíò mọ̀ pé ẹ jẹ́ ọmọẹ̀hìn mi, tí ẹ bá fẹ́ràn ara yín” (Jòhánù 13:34–35).

Kíni A Lè Ṣe?

Nígbàmíràn ó ṣòro láti sọ tí ẹnìkan bá nímọ̀lára bí wọ́n ṣe wà níta. Ọ̀pọ̀ ènìyàn kìí sọọ́—bẹ́ẹ̀ni kìí ṣe híhàn kedere. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọ̀kàn ìfẹ́ni, ìtọ́nisọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́, àti ìtiraka láti nífura, a lè damọ̀ nígbàtí ẹnìkan kò bá nímọ̀lára wíwà pẹ̀lù nínú àwọn ìpàdé Ìjọ àti àwọn ìṣeré.

Àwọn Àmì Iṣeéṣe Tí Ó Lè Mú Ẹnìkan Nímọ̀lára Ìpatì:

  • Àpẹrẹ ara típẹ́típẹ́, bí irú dídi apa mọ́ra dọindọin tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì.

  • Jijoko ní ẹ̀hìn yàrá tàbí dídá joko.

  • Àìlọ sí ile-ìjọsìn rárá tàbí àìlọ déédé.

  • Fífi àwọn ìpàdé sílẹ̀ tàbí àwọn ìṣeré ṣíwájú àkokò.

  • Àìkópa nínú àwọn ìbánisọ̀rọ̀ tàbí àwọn ẹ̀kọ́.

Àwọn wọ̀nyí lè jẹ́ àmì ẹ̀dùn-ọkàn míràn bákannáà, bíi ìtìjú, ìgbọ̀ngbọra, tàbí àìnítura. Àwọn ọmọ-ìjọ lè ní ìmọ̀lára “ìyàtọ̀” nígbàtí wọ́n bá jẹ́ ọmọ Ìjọ titun, láti orílẹ̀-èdè míràn tàbí ọ̀làjú, tàbí ti wọ́n ti ní ìrírí ìyípadà ìgbé ayé ìdẹ́rùbàni àìpẹ́, bíi ìkọ̀sílẹ̀, ikú ọmọ ẹbí kan, tàbí pípadàbọ́ láti míṣọ̀n ṣíwájú àkokò.

Láìka èrèdí náà sí, a kò gbọdọ̀ lọ́ra láti nawọ́ jáde nínú ìfẹ́. Ohun tí a sọ àti ohun tí a ṣe lè dá ìmọ̀lára kan pé gbogbo ènìyàn ni a gbàmọ́ra sílẹ̀ àti pé gbogbo ènìyàn ni a nílò.

Àwọn Ọ̀na láti Wà Pẹ̀lú àti Ìgbanimọ́ra:

  • Ẹ máṣe fì gbogbo ìgbà joko lọ́dọ́ àwọn kannáà nínú ìjọ.

  • Ẹ wo kọjá ìwò ara ìta àwọn ènìyàn láti rí ẹni tí wọ́n jẹ́ lótitọ́. (Fún púpọ̀ si lórí àkọlé yí, wo “Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ni Rírí àwọn Ẹlòmíràn bí Olùgbàlà ti Ṣe,” Liahona, June 2019, 8–11.)

  • Ẹ mú àwọn ẹlòmíràn sínú ìbánisọ̀rọ̀.

  • Ẹ pe àwọn ẹlòmíràn láti jẹ́ ara ìgbé ayé yín. Ẹ lè mú wọ́n sínú àwọn ìṣeré tí ẹ ti ngbèrò tẹ́lẹ̀.

  • Ẹ wá kí ẹ sì ní ìgbéga lórí ifẹ́ tó wọ́pọ̀.

  • Ẹ máṣe dá ìbánidọ́rẹ̀ dúró lásán nítorí ẹnìkan kò bá ìgbìrò yín mu.

  • Nígbàtí ẹ bá rí ohunkan tó tayọ nípa ẹnìkan, ẹ ní ìfẹ́ nínú èyí dípò kí ẹ yisí ẹgbẹ́ tàbí yẹra fun.

  • Ẹ fi ìfẹ́ hàn kí ẹ sì fúnni ní ìyẹ́nisí òdodo.

  • Ẹ wá àkokò láti ronú nípa ohun tí ó túmọ̀sí gan an nígbàtí a bá wípé Ìjọ wà fún gbogbo-ènìyàn, bí ó ti wù kí àwọn ìyàtọ̀ wọn tó. Báwo ni a ṣe lè mu èyí jẹ́ òtítọ́?

Kìí fì gbogbo ìgbà rọrùn láti nímọ̀lára ìtura ní àyíká àwọn ènìyàn tí wọ́n yàtọ̀ sí wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìṣe, a lè dára si ní wíwá iyì nínú àwọn ìyàtọ̀ àti ìmoore fún àwọn ìdásí tí ẹnìkọ̀ọkan nmúwá tó tayọ. Bí Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá ṣe kọ́ni, àwọn ìyàtọ̀ wa lè rànwálọ́wọ́ láti mu wá dára si, jẹ́ onídùnnú ènìyàn: “Ẹ wá, rànwálọ́wọ́ láti gbéga àti láti fún ọ̀làjú ìwòsàn kan, inúrere, àti àánú lókun sí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.”3

Di alábùkún Wíwà Pẹ̀lú

Christl Fechter kó lọ sí orílẹ̀ èdè míràn lẹ́hìn ogun ìtúká ìbílẹ̀ rẹ̀. Òun kò lè sọ èdè náà dáadáa àti pé kò mọ ẹnìkẹ́ni ní àyíká-àdúgbò rẹ̀ titun, nítorínáà ní àkọ́kọ́ ó nímọ̀lára ikọsẹgbẹ àti àdáwà.

Bí ọmọ Ìjọ kan, ó fúnrarẹ̀ ní ìgboyà ó sì bẹ̀rẹ̀ sí nlọ sí wọ́ọ̀dù rẹ̀ titun. Ó dàmú pé ìsọ̀rọ̀ rẹ to nípọn yíò mú kí àwọn ènìyàn yẹra sí fífẹ́ láti ba sọ̀rọ̀ tàbí pé wọn yíò pe òun lẹ́jọ́ fún jíjẹ́ obìnrin kan tódáwá.

Ṣùgbọ́n ó pàdé àwọn míràn tí ó fojúfo àwọn ìyàtọ̀ rẹ̀ àti gbígbàámọ́ra sí àárín àwọn ọ̀gbà ọ̀rẹ wọn. Wọ́n nawọ́ jáde nínú ìfẹ́, àti pé láìpẹ́ ó rí ararẹ̀ bíi olùrànlọ́wọ́ tó nkọ́ yàrá Alakọbẹrẹ kan. Áwọn ọmọdé ni àpẹrẹ nlá ti ìtẹ́wọ́gbà, àti ìmọ̀lára níní ìfẹ́ àti nínílò láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun àti ṣíṣèrànwọ́ láti jí ìfọkànsìn ìgbà-pípẹ́ rẹ̀ sí Olúwa dìde.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Wo Alexa Lardieri, “Study: Many Americans Report Feeling Lonely, Younger Generations More So,” U.S. News, May 1, 2018, usnews.com.

  2. Wo Carly K. Peterson, Laura C. Gravens, and Eddie Harmon-Jones, “Asymmetric Frontal Cortical Activity and Negative Affective Responses to Ostracism,” Social Cognitive and Affective Neuroscience, vol. 6, no. 3 (June 2011), 277–85.

  3. Dieter F. Uchtdorf, “Gbaàgbọ́, Nifẹ, Ṣeé,” Liahona, Nov. 2018, 48.