2019
Bí Ẹ̀mí Ṣe Lè (àti pe Yíò) Ràn Yín Lọ́wọ́ láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́.
Oṣù Kẹsan 2019


Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹsan 2019

Báwo NI Ẹ̀mí Ṣe Lè (àti pe Yíò) Ràn Yín Lọ́wọ́ láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́.

Ìfiṣẹ́lénilọ́wọ́ oyè-àlùfáà láti ṣe iṣé-ìránṣẹ́, tí a fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin bákannáà, pẹ̀lú ẹ̀tọ́ láti gba ìfihàn.

ministering

Àwọn ìjúwe látinú àwọn àwòrán Getty.

Ìpè láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ àti láti sìn àní ní ìfẹ́ bí Olùgbàlà ti ṣe lè fìgbàmíràn dàbí ìpeniníjà—pàtàkì nígbàtí ó bá gba nínawọ́ jáde sí àwọn wọnnì tí a kò lè dámọ̀ dáadáa. Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ míllíọ́nù ọ̀nà láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́, à nro bí a ṣe lè mọ àwọn ọ̀nà dídára-jùlọ láti nawọ jáde sí àwọn wọnnì tí wọ́n filewalọ́wọ́.

A kò ní láti ròó pẹ́ nítorí ìtiraka wa òdodo le gba ìtọ́nisọ́nà nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

“Ìfilenilọ́wọ́ iṣẹ́ ìranṣẹ́ yín mímọ́ nfún un yín ní ẹ̀tọ́ sí ìmísí,” ni Arábìnrin Bonnie H. Cordon, Ààrẹ Gbogbogbò àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin sọ. “Ẹ lè wá ìmísí náà pẹ́lú ìgbẹ́kẹ̀lé.”1

Nígbàtí a bá wá láti sìn bí Olùgbàlà ti ṣe, a lè gba ìtọ́nisọ́nà nípasẹ̀ Ẹ̀mí kannáà tí ó tọ́ Ọ sọ́nà. Èyí jẹ́ pàtàkì nítòótọ́ nígbàtí a bá nsìn nínú ìfiṣẹ́léni lọ́wọ́, bíi ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, tí a ṣe lábẹ́ àṣẹ kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà bíṣọ́ọ̀pù. Nihin ni àwọn àbà mẹ́fà fún ṣíṣe ìṣẹ́-ìránṣẹ́ pẹ̀lú Ẹ̀mí.

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ní Ẹ̀mí Nígbàtí Mo Bá Nṣe Iṣẹ́-ìránṣẹ́?

  • Bèèrè fún Ìtọnisọ́nà. Bábá Ọ̀run nfẹ́ kí a sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Òun nínú àdúrà. Àdúrà kìí fàyè gbà wá láti sún mọ́ Ọ típẹ́típẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n bákannáà ó nmú “àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run nfẹ́ láti fún wa ṣùgbọ́n tí wọ́n nmú ipò wá lórí ìbèèrè fún wọn.”2 “Bí a ṣe ngbàdúrà tí a sì nwá láti ní ìmọ̀ nínú ọkàn wọn,” ni arábìnrin Cordon sọ, “Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Bàbá Ọ̀run yíò darí wa àti pé Ẹ̀mí Rẹ̀ yíò bá wa lọ.”3

  • Máṣe Dúró fún Ìṣílétí kan. Jẹ́ aláápọn gidi. Jẹ́ “olùṣiṣẹ́ onítara ” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 58:27), ẹ ó sì ri pé àwọn ìtiràkà yín lè gba ìtọ́nisọ́nà àti ìgbéga. “Lílọsíwájú pẹ̀lú iṣẹ́-ìsìn wa àti iṣẹ́ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti yege fún ìfihàn,” ni Ààrẹ Dallin H. Oaks, Olùdámọ̀ràn Kínní nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní sọ. “Nínu ṣíṣe-àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ mi mo ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ ìfihàn sí àwọn ọmọ Ọlọ́run nwá nígbàtí wọ́n bá wà lórí ìrìn, kìí ṣe nígbàtí wọ́n bá joko sínú ibùgbé wọn tí wọ́n ndúró fún Olúwa láti sọ fún wọn ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti gbé.”4

Báwo ni Mo Ṣe Lè Dá àwọn Ìṣílétí láti ṣe Iṣẹ́-ìránṣẹ́ Mọ̀?

  • Gba Àmọ̀ràn Mọ́mọ́nì. A ko nílò láti fi ara kọ́ ìbínú lórí bóyá èrò kan jẹ́ ìṣílétí tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Kìí ṣe nígbàtí a ní kọ́kọ́rọ́ ìrọ̀rùn Mọ́mọ́nì láti mọ̀: Tí ẹ bá ní èrò tí ó nṣí yín létí láti ṣe rere àti láti gbàgbọ́ tàbí láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbàgbọ́ nínú Krístì, ẹ lè mọ̀ pé ti Ọlọ́run ni (wo Moroni 7:16).

  • Ẹ Máṣe Dàmú nípa Rẹ̀. “Ẹ fò sínú omi-ìwẹ̀ kí ẹ sì wẹ̀.” ni Alàgbà Jeffrey R. Holland ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ. Ẹ dojúkọ àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àìní. Ẹ máṣe darasílẹ̀ ní ríronú bóyá ẹ gbọ́dọ̀ ṣe ìfàṣẹ́hìn náà tàbí ìtúkọ̀ ajá. Tí a bá tẹ̀lé àwọn kókó ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a ti kọ́, dúró ní ìbámu pẹ̀lú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà, àti wíwá Ẹ̀mí Mímọ́ láti tọ́ wa sọ́nà, a kò lè kùnà.”5

Kíní Ọnà Tó Darajùlọ láti Tẹ̀lé Ìṣínilétí kan?

  • Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Arábìnrin Susan Bednar (ìyàwó Alàgbà David A. Bednar ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá) ni àpẹrẹ nlá kan ti títẹ̀lé àwọn ìṣílétí. Lẹ́hìn gbígbàdúrà “fún ojú ti-ẹ̀mí láti rí àwọn tí wọ́n wà nínú àìní,” ó wò yíká agbo ìjọ àti pé yíò fìgbàgbogbo “ní ìmọ̀lára ti-ẹ̀mí láti ṣèbẹ̀wò pẹ̀lú tàbí ṣe ìpè tẹlifóònù sí ẹnìkan pàtó,” ni Alàgbà Bednar ṣe àbápín. “Nígbàtí Arábìnrin Bednar gba irú ìtẹ̀mọ́ra kan, ó fèsì kíákíá ó sì gbọ́ran si. Ó jẹ́ ọ̀ràn pé ní kété tí wọ́n bá ṣe ‘àmín’ ní ìparì-àdúrà, òun yíò sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́mọdé kan tàbi dìmọ́ arábìnrin kan tàbí, ní ìpadàbọ̀ sílé, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mú tẹlifóònùkí ó sì pè.”6

  • Tìgboyà-tìgboyà. Ìbẹ̀rù ìpatì àti àwọn ìmọ̀lára ojútítí, áìpé, tàbí jíjẹ́ aláìnirọra lè dènà wa ní títẹ̀lé ìṣílétí kan láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. “Nínú onírurú àwọn àkokò àti ọ̀nà, gbogbo wa ní ìmọ̀lára àìpé, àìdánilójú, bóyá àìyẹ,” ni Alàgbà Gerrit W. Gong ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ. “Síbẹ̀síbẹ̀ nínú àwọn ìtiraka òtítọ́ wa láti nifẹ Ọlọ́run àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí aladugbo wa, a lè ní ìmọ̀làra ìfẹ́ Ọlọ́run àti ìnílò ìmísí fún ti ayé wọn àti ayé wa ní àwọn ọ̀nà ọ̀tun àti mímọ́-síi.”7

    Arákùnrin kan ṣe àbápín bi òun ṣe lọ́ra láti nawọ́ jáde sí ọkọ obìnrin kan ẹni tí ó fẹ́ pa ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbẹ̀hìn ó pe ọkọ náà láti bá òun jẹ oúnjẹ-òsán. “Nígbàtí mo wípé, ‘Ìyàwó rẹ fẹ́ pa ara rẹ̀. Ìyẹn gbọ́dọ̀ jẹ́ ìbonimọ́lẹ̀ fún ọ. Ṣe ó fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?’ ó sọkún ní gbangban,” ó ṣe àbápín. “A ní ìbárasọ̀rọ̀ rírọ̀ tó sí fanimọ́ra a sì mú ìsúnmọ́raẹni tó lọ́lá kan gbèrú àti ìgbẹ́kẹ̀lé ní àárín ìṣẹ́jú díẹ̀.”8

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Bonnie H. Cordon, “Dída Olùṣọ́ Àgùntàn,” Liahona, Oṣù Kọkànlá (Belu). 2018, 76.

  2. Ìtumọ̀ Bíbélì, “Àdúrà.”

  3. Bonnie H. Cordon, “Dída Olùṣọ́ Àgùntàn,” 76.

  4. Dallin H. Oaks, “Ní Àkokò Tirẹ̀, ní Ọnà Tirẹ̀,” Liahona, Oṣù Kẹjọ (Ògún). 2013, 24.

  5. Jeffrey R. Holland, “Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ ti Ìlàjà,” Liahona, Oṣù Kọkànlá (Belu). 2018, 77.

  6. David A. Bednar, “Yára láti Kíyèsí,” Liahona, Oṣù Kejìlá (Ọ̀pẹ). 2006, 17.

  7. Gerrit W. Gong, “Ògùṣọ̀ Ìgbàgbọ́ Wa,” Liahona, Oṣù Kọkànlá (Belu) 2018, 42.

  8. . Wo Bonnie H. Cordon, “Dída Olùṣọ́ Àgùntàn kan,” 76.