Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kejìlá 2019
Ohun tí Ìtàn Kérésìmesì Kọ́ Wa nípa Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ
“Èyí ni àyànfẹ́ àkokò ti ọdún. Kọrin ìbámu kan; ìgbà Kérésìmesì yíò tó dé ìhín. Sọ ìtàn òtítọ́ ti ìbí Jésù, nígbàtí, ó wá sí ayé, bí ọmọ-ọwọ́” (“Orin Àbínibí Náà,” Ìwé Orin àwọn Ọmọdé, 52).
Àkókò Kérésìmesì ni ìgbà ìyanu kan nígbàtí àwọn àgùtàn, àwọn olùṣọ́-àgùtàn, àwọn ibùjẹ́-ẹran, àti àwọn ìràwọ̀ tó gba ìtumọ̀ titun lọ́gán. Wọ́n di olùṣeré pàtàkì nínú títúnsọ ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì nínú ìwé-ìtàn ènìyàn: ìbí Jésù Krístì. Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí fi ìràn àbínibí kan hàn nínú ilé wọn. Àwọn míràn ṣe àmì kan láti ka ìtàn ìbí Rẹ̀ tàbí kópa nínú ìṣeré kan. Bíi gbogbo àwọn ìtàn Krístì, ìtàn ìbí Rẹ kún fún àwọn ẹ̀kọ́ tí a lè kọ́ nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, nípa ṣíṣe àbápín ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀ ayé. “Ìtàn Kérésìmesì jẹ́ ìtàn ìfẹ́ kan,” ni Ààrẹ Henry B. Eyring, Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní.
“… Nínú àwọn ìtàn ti ìbí Krístì, a lè rí kí a sì ní ìmọ̀lára ẹnití Ó ti jẹ́ àti ẹnití Ó jẹ́. Ìyẹn nmú ẹrù wa fúyẹ́ lẹgbẹ ọ̀nà. Àti pé yíò darí wa láti gbàgbé arawa àti láti mú ẹrù fúyẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn.”1
“Kò sí yàrá fún wọn nílé èrò” (Lúkù 2:7)
Olùṣọ́-ilé-èrò náà kùnà láti ṣe yàrá fún Olùgbàlà, ṣùgbọ́n a kò ní lati ṣe àṣìṣe náà! A lè ṣe yàrá fún Olùgbàlà nínú ọkàn wa nípa ṣíṣe yàrá fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lórí àwọn tábìlì wa, nínú ilé wa, àti nínú àwọn àṣà wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àṣà ẹbí lè ṣe ìrántí dídùn síi àní àti nípasẹ̀ kíka àwọn ẹlòmíràn kún. Daiana àti ẹbí rẹ̀ ní àṣà kan nípa pípé ẹnìkan láti lo kékésìmesì pẹ̀lú wọn. Ní Oṣooṣù Kejìlá, wọ́n sọ̀rọ̀ wọ́n sì gbèrò ẹni tí wọn yíò fẹ́ láti pè.2 Bóyá ẹbí yín lè bẹ̀rẹ̀ irú àṣà kannáà. Bóyá ẹnìkan tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí yíò fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ ẹbí yín ní kíkọ àwọn orin Kérésìmesì alárinrin papọ̀. Bákannáà a lè ṣe yàrá níbi oúnjẹ alẹ́ Kérésìmesì fún ẹnìkan tí ó lè má ní ẹbí ní agbègbè náà.
Ọ̀nà dídára wo láti ṣayẹyẹ Olùgbàlà ju láti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ nípa ìkàkún? Rántí pé Ó npé “gbogbo ènìyàn láti wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí wọ́n sì pín ninu inúrere rẹ̀; kò sì kọ ẹnìkẹ́ni tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, dúdú àti funfun, inú ìdè àti òmìnira, akọ àti abo; ó sì nrántí àwọn abọ̀rìṣà; gbogbo wọn sì dàbí ọ̀kan sí Ọlọ́run, Júù àti Kèfèrí mejèèjì” (2 Nífáì 26:33). Ẹ ṣe yàrá kí ẹ dá ìkàkún sílẹ̀.
“Awọn olùṣọ́-àgùtàn nbẹ ní ìlú náà, wọ́n nṣọ́ agbo àgùtàn wọn ní òru” (Lúkù 2:8)
Ó dàbí ìbámu pé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yíò wà ní àárín àwọn àkọ́kọ́ láti kí Olùgbàlà ọmọ-jòjòló. Àwọn wòlíì àtijọ́ tọ́ka sí Jésù Krístì bí “Olùṣọ́-àgùtàn Ísráẹ́lì” (Orin Dafidi 80:1) àti “Olùṣọ́-àgùtàn lórí gbogbo ilẹ̀ ayé” (1 Nífáì 13:41). Krístì Fúnrarẹ̀ wípé, “Èmi ni olùṣọ́-àgùtàn rere, mo sì mọ àwọn àgùtàn tèmi” (Jòhánù 10:14). Mímọ àwọn àgùtàn tiwa àti títọ́jú wọn ni kókó ara jíjẹ́ Olùṣọ́-àgùtàn àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí Olùgbàlà ti ṣe.
Pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lẹ̀ tó tàn yanyan àti àwọn ẹ̀ṣọ́ dídán, àwọn ohun púpọ̀ wà láti wò ní àkokò Kérésìmesì. Ṣùgbọ́n bóyá ẹwà títóbijù ti àkokò ni a lè rí nígbàtí a bá rántí láti yí ìdojúkọ wa padà sí àwọn wọnnì tí à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àti títọ́jú àwọn agbo tiwa. Ṣíṣe ìtọ́jú lè jẹ́ mímọ ohun tí ẹnìkan fẹ́ràn jùlọ tàbí bíbi ẹnìkan léèrè nípa ètò ìsinmi. À nṣe ìtọ́jú nígbàtí a bá rí tí a sì npèsè fún àìní àwọn ẹlòmíràn—èyí tó hàn gbangban àti èyí tí kò hàn tóbẹ́ẹ̀.
Nígbàtí Cheryl pàdánù ọkọ rẹ̀ Mick lójijì, ó sì dàmú. Gẹ́gẹ́bí Kérésìmesì rẹ̀ àkọ́kọ́ láìsí i ṣe nsúnmọ́, àdánìkanwà ndàgbà si. Pẹ̀lú-ọpẹ́, arábìnrin Shauna òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ wà níbẹ̀. Shauna àti ọkọ rẹ̀, Jim, pe Cheryl sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè ìjáde. Wọ́n ṣàkíyèsí kóòtù Cheryl tó ti gbó wọ́n sì gbèrò láti ṣe ohunkan nípa rẹ̀. Àwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣíwájú Kérésìmesì, Shauna àti Jim mú ẹ̀bùn Kérésìmesì kan wá fún Cheryl: Kóòtù dídárá tuntun kan. Wọ́n mọ ìnílò ti-ara Cheryl fún kóòtù kan ṣùgbọ́n bákannáà ti ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ fún ìtùnú àti ìbáṣepọ̀. Wọ́n dìde sókè láti mú àwọn ìnílò wọnnì ṣẹ bí wọ́n ṣe lágbára tó wọ́n sì fi àpẹrẹ dídára hàn bí àwa náà ṣe lè tọ́jú àwọn agbo wa.3
“Àwọn olùṣọ́-àgùtàn náà bá ara wọn sọ pé, Ẹ jẹ́ kí a lọ tààrà sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù” (Lúkù 2:15)
“Ẹ jẹ́ kí a lọ tààrà” ni ìfipè àkúnwọ́sílẹ̀ kan! Àwọn olùṣọ́-àgùtàn kò rò pé yíò rẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn jù láti rin ìrìn náà. Wọn ko lọ sí Bẹ́tlẹ́hẹ́mù jẹ́jẹ́ níti arawọn. Wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ yípadà sí ara wọn wọ́n sì wípé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ tààrà!”
Bíótilẹ̀jẹ́pé a lè má tilẹ̀ pe àwọn ọ̀rẹ́ wa láti wá rí Olùgbàlà ọmọ-ọwọ́ náà, a lè pè wọ́n láti ní ìmọ̀ ẹ̀mí ti Kérésìmesì (tàbí ẹ̀mí ti Krístì) nípa sísìn pẹ̀lú wọn. “Ọ̀nà láti ní àlékún ẹ̀mí Kérésìmesì ni láti nawọ́ jáde pẹ̀lú inúrere sí àwọn wọnnì ní àyíká wa kí a sì fúnni nípa arawa,” ni Arábìnrin Bonnie L. Oscarson, Ààrẹ Gbogbogbò àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin tẹ́lẹ̀ sọ.4 Ẹ ròó pé ẹ̀ ndi àbẹ́là kan mú. Àwọn ẹlòmíràn dájúdájú lè rí kí wọ́n sì jèrè látinú ìmọ́lẹ̀ nínú àbẹ́là yín, ṣùgbọ́n ro ìwúrí tí wọ́n lè ní tí ẹ bá lo àbẹ́là yín láti tan àbẹ́là wọn àti láti fi àyè gbà wọ́n láti di ìmọ́lẹ̀ mú fún arawọn.
Krístì Fúnrarẹ̀ kọ́ni pé àwọn wọnnì tí wọ́n tẹ̀le E yíò ní ìmọ́lẹ̀ ayé (wo Jòhánù 8:12). Sísìn bí Òun ti ṣe ni ọ̀nà kan tí a fi lè tẹ̀lé E àti láti gbádùn ìmọ́lẹ̀ ìlérí. Nítorínáà pín ìmọ́lẹ̀ náà nípa pípé àwọn ẹlòmíràn láti sìn pẹ̀lú yín! Báwo ni ẹ̀yin àti àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí fi lè sìn papọ̀? Lápapọ̀ ẹ lè múra oúnjẹ aládùn yín sílẹ̀ tàbí kí ẹ ya ẹnìkan lẹ́nu pẹ̀lú ẹ̀bùn kékeré kan tàbí àkọsílẹ̀ ránpẹ́. Lápapọ̀ ẹ lè ní ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ tí ó nwá ní títẹ̀lé àpẹrẹ iṣẹ́ ìsìn Krístì.
“Wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yi” (Lúkù 2:17)
O rọrùn láti ro ìyayọ̀ ìdùnnú àwọn olùṣọ́-àgùtàn bí wọ́n ti pín àwọn ìròhìn alára ti ìbí Krìstì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn bí ó ti ṣeéṣe. Kíkéde nípasẹ̀ àwọn ángẹ́lì, Mèsíàh tí a sọtẹ́lẹ̀ ti dé! Ó wà nihin! Nítòótọ́, pínpín ìròhìn rere ti Olùgbàla ni àkolé ìtàn Àbínibí náà. Àwọn ángẹ́lì kọrin. Ìràwọ̀ fì ọ̀nà náà hàn. Àwọn olùṣọ́-àgùtàn sọọ́ di mímọ̀ lẹ́hìn odi.
A lè fi ohùn wa kún ìtàn Kérésìmesì nípa pínpín ìròhìn rere àti jijẹri nípa Olùgbàlà. “Bí ẹ ṣe nni ànfàní láti ṣe aṣojú Olùgbàlà nínú ìtiraka iṣẹ́ ìránṣẹ́ yín, ẹ bèèrè lọ́wọ́ ara yín, ‘Báwo ni mo ṣe lè ṣe àbápín ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere pẹ̀lú ẹnìkọ̀ọ̀kan yí tàbí ẹbí?’” ni Arábìnrin Jean B. Bingham, Ààrẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ sọ. “Kíni Ẹ̀mí nmí sími láti ṣe?”5
Nihin ni àwọn àbá díẹ̀ fún yín láti yẹ̀wò bí ẹ ṣe nwá láti mọ̀ bí ẹ ṣe lè pín ẹ̀rí yín nípa Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀:
-
Wá ìwé-mímọ́ kan tí ó ngbé àwọn ìmọ̀lára yín jáde nípa Olùgbàlà tàbí fi ìdí tí ẹ fi ní ìmoore hàn sí I. Ẹ pín pẹ̀lú àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí.
-
Fi àtẹ̀jíṣẹ́ kan ránṣẹ́ tàbí ọ̀rọ̀ ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn pẹ́lú fídíò Kérésìmesì kan. Awọn alárà kan wà ní ChurchofJesusChrist.org!
-
Ẹ sọ fún ọ̀rẹ́ kan nípa ìrántí pàtàkì tàbí àṣà tí ó nrán yín létí nípa Krístì.
Ẹ ní ìgbàgbọ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ yíò jẹ́ ẹ̀rí nípa òtítọ́ ẹ̀rí yín, gẹ́gẹ́bí ó ti jẹ́ ẹ̀rí sí Simeon àti Anna pé ọmọ-ọwọ́ náà Jésù ni Olùgbàlà (wo Lúkù 2:26, 38).
“Láti bu olá fún bíbọ̀ [Jésù Krístì] sínú ayé lódodo, a gbọ́dọ̀ ṣe bí Òun ti ṣe kí a sì nawọ́ jáde nínú àánú àti ìyọ́nú sí àwọn ọmọlàkejì wa,” ni Alàgbà Dieter F. Uchtdorf ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá sọ. “A lè ṣe èyí lójojúmọ́, nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Ẹ jẹ́ kí èyí di àṣà Kérésìmesì wa, ibikíbí èyíówù kí a wà—láti ní inú rere díẹ̀ síi, ni ìdáríjì síi, dínkù nínú ìdánilẹ́jọ́, ní ímoore síi, àti nínú inúrere síi ní pínpín ọ̀pọ̀ wa pẹ̀lú àwọn wọnnì nínú àìní.”6
© 2019 by Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹẹ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì 6/18. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/18. Àyípada éde ti Ministering Principles, December 2019. Yoruba. 15773 779