Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kẹta 2020
ṢÍṢE IṢẸ́ ÌRÁNṢẸ́ NÍPASẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN TẸ́MPÌLÌ
Nígbatí a bá ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti gbádùn àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì, à nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.
Lílọ sí tẹ́mpìlì yẹ fún ìtiraka náà. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé “tẹ́mpílí ṣe kókó sí ìgbàlà àti ìgbéga wa àti sí ti àwọn ẹbí wa. …
“… Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nílò ìfúnnilókun ẹ̀mí tí ó nlọ lọ́wọ́ àti kíkọ́ni tí ó ṣeéṣe nínú ilé Olúwa nìkan .”1
Lílọ sí tẹ́mpìlì gba ṣíṣe àkóso àkokò, àwọn ojúṣe, àti àwọn ohun èlò wa, bákannáà bíi mímúrasílẹ̀ ní ti ẹ̀mí. A nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nígbàtí a bá dá àwọn ìdènà tí ó npa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wá mọ́ kúrò nínú tẹ́mpìlì mọ̀ tí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí àwọn ìyanjú.
Tẹ́mpìlì Jẹ́ Ìbùkún kan tí Ẹnìkẹ́ni Lè Gbádùn
Ìránṣẹ́ ìhìnrere kan, Meg, tí ó padà dé láípẹ́ nrìn lọ́ sí ibi àwọn ilẹ̀kùn Tẹ́mpìlì Kona Hawaii nígbàtí ó ṣe àkíyèsí ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó dá joko ní orí bẹ́nṣì ní ìta. Meg ní ìmọ̀lára pé kí òun bá obìnrin náà sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ko dáa lójú ohun tí ó lè sọ. Nítorínáà ó bèèrè nípa ìtumọ̀ àwòrán fífín ní ibi ọrùn ẹsẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin náà. Èyíinì bẹ̀rẹ̀ ìbásọ̀rọ̀ kan tí ó fi ààyè gba ọ̀dọ́mọbìnrin náà, Lani, láti ṣe àbápín ìtàn rẹ̀.
Lani wí fún Meg nípa ìlàkàkà rẹ̀ láti padà sí ìkópa ní kíkún nínú Ìjọ, àwọn ọmọ ìjọ dáradára tí wọ́n nràn án lọ́wọ́, àti ìrètí rẹ̀ láti ṣe èdidì pẹ̀lú ọmọdébìnrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan.
Meg pe Lani láti wá joko ní ibi yàrá ìdúró tẹ́mpìlì pẹ̀lú òun. Wọn kò ní lè lọ síwájú si inú tẹ́mpìlì sìbẹ̀, ṣùgbọ́n wọn yíò lè sọdá iloro ẹnu-ọ̀nà. Lani gbà, wọ́n sì jọ lọ papọ̀ la àwọn ìlẹ̀kùn ti ẹnu ọ̀nà gangan kọjá. Òṣìṣẹ́ tẹ́mpìlì kan fi bẹ́nṣì kan ní abẹ́ àwòrán Olùgbàlà hàn wọ́n.
Bí wọ́n ṣe joko papọ̀, Lani rọra sọ jẹ́jẹ́ pé, “ó wùmí gan láti wá sí inú tẹ́mpìlì loni, ṣùgbọ́n ara mi ngbọ̀n.” Nítorípé Meg tẹ̀lé Ẹ̀mí, ó ṣe ìrànwọ́ láti dáhùn àdúrà jẹ́jẹ́ Lani.
Àwọn Èrò láti Ṣe Ìrànwọ́ fún Àwọn Wọnnì tí kòní Ìkaniyẹ.
Àní àwọn wọnnì tí wọn kò tíì ní ìkaniyẹ tẹ́mpìlì báyìí lè di alábùkún nípasẹ̀ tẹ́mpìlì.
-
E ṣe àbápín àwọn ìmọ̀lára yín nípa bí Olúwa ti bùkún yín nípasẹ̀ iṣẹ́ tẹ́mpìlì.
-
Pe ẹnìkan láti wà ní ibi ìṣílé tẹ́mpìlì kan tàbí gbàgede àwọn àlejò. Ẹ wá àwọn ìṣílé tó nbọ̀ ní temples.ChurchofJesusChrist.org.
-
Ẹ wo àwọn fọ́tò kí ẹ sì kọ́ ẹ̀kọ síi nípa tẹ́mpìlì ní temples.ChurchofJesusChrist.org.
Mú Lílọ sí Tẹ́mpìlì Rọrùn Síi fún àwọn Ẹlòmíràn.
Àní fún àwọn ọmọ ìjọ pẹ̀lú ìkaniyẹ tẹ́mpìlì, lílọ sí tẹ́mpìlì lè jẹ́ ìpèníjà kan. Àwọn kan lè nílò láti rin ìrinàjò àwọn ọ̀nà jíjìn. Àwọn míràn lè ní àwọn ọmọ kékeré tàbí àwọn arúgbo ọmọ ẹ́bí tí wọ́n nílò ìtọ́jú. A lè ṣiṣẹ́ papọ̀ láti mú kí iṣẹ́ ìsìn tẹ́mpìlì ṣeéṣe fún gbogbo ènìyàn.
Leola Chandler ní ìmọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀ nípa títọ́jú ọkọ rẹ̀ àláìlera àti àwọn ọmọ wọn mẹ́rin. Nítorínáà ó pinnu láti fi àkokò kan sọ́tọ̀ ní ọjọọjọ́ Ìṣẹ́gun láti lọ sí tẹ́mpìlì tí ó wà nítòsí. Ó di orísun kan ti àláfíà àti agbára nínú ayé rẹ̀.
Ní ọjọ́ kan ó gbọ́ pé àwọn arábìnrin àgbàlagbà kan nínú wọ́ọ̀dù rẹ̀ fi taratara fẹ́ láti lọ sí tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n wọn kò ní ọ̀nà láti gbé ara wọn dé ibẹ̀. Leola gbà láti wà wọ́n lọ. Fún ogójì ọdun tí ó tẹ̀le, kò sáábà lọ sí tẹ́mpìlì ní òun nìkan.2
Leola ní ìbùkún, ó sì bùkún àwọn ẹlòmíràn nígbàtí ó gbà láti kó wọn pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí tẹ́mpìlì.
Àwọn Èrò láti Ran àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ láti Lọ Sí Tẹ́mpìlì
Báwo ni ẹ ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti dé tẹ́mpìlì léraléra síi? Ẹ lè ri pé àwọn èrò kannáà yíò ràn yín lọ́wọ́ bákannáà.
-
Ẹ Lọ papọ̀. Gbà láti pèsè tàbí ṣe ètò fún ọkọ̀ fún ẹnìkan. Ó lè gba ẹnìkan míràn níyànjú láti lọ sí tẹ́mpìlì bákannáà.
-
Ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹbí tàbí wọ́ọ̀dù láti ràn yín lọ́wọ́ ṣe àwọn ìlànà fún àwọn bàbánlá yín, nípàtàkì nígbàtí ẹ bá ti ní àwọn orúkọ ẹbí púpọ̀ ní síṣetán fún àwọn ìlànà.
-
Ẹ gbà láti gba ọmọ tọ́ kí àwọn òbí lè lọ sí tẹ́mpìlì. Tàbí ẹ ṣe ètò láti bojútó àwọn ọmọ ara yín ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
Nígbàtí Tẹ́mpìlì Bá Jìnnà Réré
Chandradas “Roshan” àti Sheron Antony ti Colombo, Sri Lanka, pinnu láti ṣe èdidì nínú tẹ̀mpìlì. Ọ̀rẹ́ wọn Ann àti Kumarasamy ní ìdùnnú gidi fún wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé dídé Tẹ́mpìlì Manila Philippines kò rọrùn tàbí gbọ̀pọ̀.
Kò ṣeéṣe láti gba àṣẹ ìrìnnà, wọ́n kò sì ní agbára láti ra tíkẹ́tì ní orí ọkọ̀ òfúrufú míràn. Nígbẹ̀hìn, ọjọ́ náà dé. Ṣùgbọ́n, ní àkókò ìdúró wọn díẹ̀ ní Malaysia, wọ́n ríi pé láti tẹ̀síwájú lọ sí Philippines, wọ́n nílò àṣẹ ìrìnnà tàbí nílò láti fò pẹ̀lú ọkọ̀ òfúrufú míràn kan tí ó yàtọ̀ Kò ṣeéṣe láti gba àṣẹ ìrìnnà, wọ́n kò sì ní agbára láti ra tíkẹ́tì ní orí ọkọ̀ òfúrufú míràn. Ṣùgbọ́n wọn kò lè gba èrò pípadà sí ilé mọ́ra láì ṣe èdidì.
Láìmọ ohun míràn láti ṣe, Rosahn pe Anton. Anton àti Ann fi taratara fẹ́ láti ṣe ìrànlọ́wọ́. Wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tọkọtaya díẹ̀ ní Sri Lanka tí wọ́n ti ṣe èdidi ní tẹ́mpìlì, wọ́n sì mọ irú ìbùkún tí ó jẹ́. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ wọ́n lo àwọn ìpamọ́ wọn láti ran ọmọ ẹ́bí kan lọ́wọ́ nínú àìní, wọn kò sì ní owó tí ó tó láti ran Roshan àti Sheron lọ́wọ́ láti ra tíkẹ́tì fún ọkọ̀ òfurufú titun.
Ní Sri Lanka ó jẹ́ àṣà fún ọkọ láti ra ẹ̀gbà ọrun wúrà fún ìyàwó pé kí òun lè ní owó díẹ̀ bí ọkọ rẹ̀ bá kú. Ann pinnu láti ta ẹ̀gbà ọrùn rẹ̀ láti ṣe ìrànwọ́ láti ra àwọn tíkẹ́tì titun náà. Ẹ̀bùn inúrere rẹ̀ mú kí ó ṣeéṣe fún Roshan àti Sheron láti dé tẹ́mpìlì ní Manila ní àkókò tí wọ́n yàn.
“Mo mọ iyì èdidì tẹ́mpìlì,” ni Ann sọ. “Mo mọ̀ pé Sheron àti Roshan yíò jẹ́ okun nlá sí ẹ̀ka náà. Èmi ko fẹ́ kí wọ́n ó pàdánù ànfàní yí.”3
Àwọn Èrò láti Ran Àwọn Wọnnì Tí Wọn Kò Lè Bẹ Tẹ́mpìlì Wò Lọ́wọ́
A lè pè yín láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn wọnnì tí wọn kò lè lọ sí tẹ́mpìlì léraléra tàbí rárá nítorí àwọn ọ̀nà jíjìn tàbí àwọn ìnáwó. Ṣùgbọ́n ẹ lè wá àwọn ọ̀nà síbẹ̀síbẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ iyì àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì.
-
Kọ́ni tàbí kópa papọ̀ nínú kílásì ìmúrasílẹ̀ tẹ́mpìlì tàbí ti ìtàn ẹbí.
-
Fún wọn ní fọ́tò ti tẹ́mpìlì kan láti gbé kọ́ ní ilé wọn.
-
Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ síi nípa àwọn májẹ̀mú tí wọ́n ti ṣe àti láti pa wọ́n mọ́.
-
Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ síi nípa àwọn májẹ̀mú tí wọ́n ti ṣe àti láti pa wọ́n mọ́. Gbèrò lílo “Níní òye Àwọn Májẹ̀mú Wa pẹ̀lú Ọlọ́run: Àyẹ̀wò kan nípa àwọn Ìlérí tí ó Ṣe Pàtàkì Jùlọ,” nínú Làhónà Oṣù Kéje 2012.
© 2020 Láti ọwọ́ Intellectual Reserve, Inc. All rights reserved. A tẹẹ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì 6/19. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/19. Àyípada éde ti Ministering Principles, March 2020. Yoruba. 16985 779