“Pínpín Ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà ní ọjọ́ Kérésìmesì,” Làìhónà, Oṣù Kejìlá (Ọ̀pẹ) 2020
Àwọn Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kejìlá (Ọ̀pẹ) 2020
Pínpín ìmọ́lẹ̀ Olùgbàlà ní Kérésìmesì
Ẹ kíyèsí àwọn wọnnì tí ẹ̀ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí. Báwo ni ẹ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti súnmọ́ Krístì ní àkókò Kérésìmesì yi?
Nígbàtí à ńṣè ìrántí Jésù Kristì Olùgbàlà ní gbogbo ọdún, Kérésìmesì jẹ́ àkókò tí a máa ńṣe àjọyọ̀ ẹ̀bùn tó tóbi jùlọ tí a ti fúnni rí: “Nítorí Ọlórun fẹ́ràn aráyé tóbẹ́ẹ̀ gẹ, tí ó fí fi ọmọ bíbí rẹ kanṣoṣo fúnni” (Jòhánnù 3:16). Bí a ṣe nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní Kérésìmesì, àwa náà lè fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn tí yio ràn wọ́n lọ́wọ́ láti súnmọ Olùgbàlà si. Ó jẹ́ ìyàlẹ́nu láti ronú nípa ara wa gẹ́gẹ́bí fífi ẹ́bùn tí Bàbá wa ọ̀run fún wa hàn.
Mo ṣì ṣìkẹ́ Ẹ̀bùn náà
Susan Hardy, California, USA
Nígbàtí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá, Olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi mi, Alàgbà Deets, sọ fún kíláàsì wa pé tí a ó bá ṣe àkọ́sórí àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ kí a sì ṣàlàyé ǹkan tí ó jẹ́ fún òun, òun yio ra àkópọ̀ ìwé mímọ́ ti arawa fún wa.
Arákùnrin àti Arábìnrin Deets jẹ́ tọkọtaya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Kòdá mi lójú pé Arákùnrin Deets lè ra ẹ̀bùn kankan fún ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n mo pinnu pé tí ó bá rò wípé àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkí to bẹẹ láti kọ́sórí, mo maà gbá ìpèníjà náà.
Lẹ́hìn tí mo ti parí gbogbo mẹ́tàlá, àkókò tí lọ mo sì ti gbàgbé ìlérí rẹ̀.
Nígbànáà, ní Ọjọ́ Kérésìmesì, Mo gba ẹ̀bùn kan tí orúkọ mí wà lórí rẹ̀. Mo ṣíi mo sì rí àkópọ̀ àwọn ìwé mímọ́ fún mi, pẹ̀lú káàdì tó gbà mí níyànjú láti máa kà wọ́n déédé. Èyí jẹ́ 1972, àti pé títí di òní mo ṣì ní àwọn ìwé mímọ́ náà. Wọ́n jẹ́ iyebíye fun mi.
Kìí ṣe oye tí ẹ̀bùn jẹ́ ṣugbon ti inúrere tí ó fihàn mí pẹ̀lú ìfarajìn tí ó ní ìfẹ́ láti ṣe fún mi ni ó mú mi ní ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ làti ma ṣe àṣarò ninu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà. Mo gbìyànjú láti tẹ̀lé àpẹrẹ ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bíiti Arákùnrin Deets nípa fífún àwọn tí o wà ní àyíká mi ni ẹ̀bùn tí o ni ìtumọ̀, ní ìrètí wípé mo lè bùkún ayé àwọn ẹlòmíràn bi òun ṣe bùkún tèmi.
Ìpè láti Ṣe Ìkópa kan
Richard M. Romney, Utah, USA
Nìgbàtí àwọn tí ó nṣètò Kérésìmesì ní wọ́ọ̀dù wa ní kì nṣe ìbẹ̀wò sí ọmọ ìjọ tí kìí wá sí ìpàde déédé kí n sì pèé láti kópa nínu ètò náà, mo ní láti gbà pé mò ngbọ̀n. Mo ti pàdé Darren ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo rí, nígbàtí ó kópa nínu ìṣe wọ́ọ̀dù kan ṣíwájú. Ó ti sán aṣọ alùpùpù kan yíká orí rẹ̀. Ìrun funfun rẹ gígún ni ó sopọ̀ bí ìru ẹṣin, ó ní irùngbọ̀n funfun tí ó kún, àti pé àwọn apá rẹ̀ ni a fi ìkọlà bò.
Báyi, pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ kan, Mo dúró ní ẹnu ọ̀nà Darren, pẹ̀lú iyèmejì ohun tí ó le sọ. Ó ní kí a wọlé, a sì wí fún ìdí tí a fi wà níbẹ̀. Ó wípé, “Óò, èmi ma fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀!”
Ó ṣe iṣẹ́ tó yànilẹ́nu, ìrànlọ́wọ́ láti jẹ́ kí ìṣe náà ní ìtumọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ní àkokò díẹ̀ lẹ́hìnnáà, wọ́n ní kí èmi àti ojúgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi máa ṣe àbẹ̀wò sí Darren léraléra. Ìnú rẹ̀ má ńdùn láti rí wa nígbàgbogbo, a sì tí ní àwọn ọ̀rọ̀ àjọsọ aládùn. M’o dúpẹ̀ fún ìmísí láti pè é láti kópa nínu àwọn ìṣe wọ́ọ̀dù tí o jásí ìṣìkẹ́ ìbáṣepọ̀ kan.
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ sí àwọn Ẹlòmíràn ní Kérésìmesì
nihin ní àwọn ǹkan tí ẹ lè ṣe láti ri dájú pé àwọn tí ẹ nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí lè mọ pé ẹ̀ ńronú nípa wọn, pàápàá ní àkókò ọdún yi.
-
Nígbà míràn ìpè orí fóònù tàbí títẹ ọ̀rọ̀ má ńṣe àwọn iṣẹ́ àrà. Bíbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ àjọsọ pẹ̀lú ìrọ̀rùn Ẹ nlẹ́ “Báwo ni ẹ ṣé wà?” lè ṣe ìyàtọ̀ kan.
-
Darapọ̀ nínú àjọyọ̀ wọ́n nígbàtí o bá yẹ. Kérésìmesì lè jẹ́ àkókò nlá láti kọ́ nípa àwọn ìgbàgbọ́ tí a ní papọ̀. Nígbàtí ẹ bá pín àwọn ìgbàgbọ́ tí ẹ sì fẹ́tísí àwọn ẹlòmíràn, ẹ ṣí ilẹ̀kùn sí òye tó gajù.
-
Ẹ gbàdúrà fún wọ́n nípasẹ̀ orúkọ. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ Bàbá Ọ̀run kí wọn ràn yín lọ́wọ́ láti ronú àwọn ọ̀nà tí o lè mú wọ́n súnmọ́ Ọmọ Rẹ̀ si.
-
Àwọn ẹ̀bùn rírọrùn ni ó dára jùlọ láti rántí. Kò pọndandan kí ẹ̀bùn tóbí kí a tó fẹ́ràn wọ́n. Ẹ̀bun ti àkókò, ẹ́bun ti fífetísílẹ̀, pínpín fótò tàbí ìrántí kan—gbogbo ìwọ̀nyí lè jẹ́ ẹ̀bùn ti ọkàn.
-
Fúnni ní ẹ̀bun ìjẹ́rí. Ẹ wí fún wọn kí wọ́n pín ìfẹ́ Olùgbàlà pẹ̀lú yín, kí ẹ sí gba láti pín ìfẹ́ rẹ sí I pẹ̀lú wọn.
-
Ẹ pe àwọn ẹlòmíran láti wá sí ìsin Kérésìmesì kan. Àwọn kan fẹ́ jọ́sìn ṣùgbọ́n wọn kò mọ ibi tí wọ́n lè lọ. Ẹ pè wọn kí wọ́n wá jọ́sìn pẹ̀lú yín.
-
Ẹ kún inú ilé wọ́n pẹ̀lú àlàáfíà. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere ní ọ̀rọ̀ Kérésìmesì pàtàkì tí wọ́n lè pín, èyí tí yìó mú ìrètí àti ìfẹ́ wá sí ọkàn wọn.
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ sí Gbogbo Ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìjọ
Gbogbo ǹkan tí ìjọ nílò jẹ́ àìléfiwé. Àwọn àǹfàní tó wà nínú ṣíṣètò àwọn ìṣe tó tóbí. Àwọn ìjọ míràn lè jèrè láti inú ǹkan kékeré tí o sì rọrùn. Àwọn tí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣètò àti títo àwọn iṣe fi tàdúràtàdúrà gbèrò bí wọ́n ṣe lè bá àìní àwọn to wà pàdé.
-
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti èèkàn mẹ́ta ní Paris, France, ṣèrànwọ́ láti ṣàtìlẹ́hìn fún Tan Ìmọ́lẹ̀ Agbáyé kan nínú àpéjọ-àṣálẹ́pẹ̀lú eré ẹ̀bùn kan àti eré aṣaralóge. Wọ́n múra àwọn ohun-èlò sílẹ̀ fún àwọn rẹfují àti àwọn ènìyàn tí wọ́n nní ìrírí àìní ilé lórí.
-
Èèkàn Charlotte North Carolina Central ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ “Kérésìmesì káàkiri Àgbáyé” kan fún ìletò, pẹ̀lú àwùjọ láti ṣe àjọyọ Krístì nípasẹ̀ óúnjẹ, àwọn àṣehàn Kérésìmesí láti ìlú òkèrè, orin, ṣíṣeiṣẹ́-ìsìn, àti bíbí àwọn ọmọdé.
-
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Èèkàn Vero Beach Florida darapọ̀ mọ́ ìletò kan ní ìrántí ìdí tí a fi nṣe àjọyọ̀ Kérésìmesì. Wọ́n fún àwọn ilé-àánú ìletò ní àwọn ohun ìṣeré. Àwọn àkọrin àlákọ́bẹ̀rẹ̀ kan kọrin, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìjọ ṣe ìfihàn àlàyé.
-
Èèkan Jacksonville Florida South gbéẹ̀bùn àtèjáde Olùgbàlà ti Àgbáyé fún ìletò kalẹ̀.
© 2020 by Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ni a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà èdè: 6/19. Ìyírọ̀pada éde Iṣẹ́ Ìránṣẹ́, Oṣù Kejìlá (Ọ̀pẹ) 2020. Yoruba. 16727 000