2021
Dàgbà sínú Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ ti Ìfihàn
Oṣù Kínní (ṣẹrẹ) 2021


“Dàgbà sínú Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ ti Ìfihàn,” Làìhónà, Oṣù Ìkínní (Ṣẹrẹ) 2021

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Ìkínní (Ṣẹrẹ) 2021

Dàgbà sínú Ẹ̀kọ́ Ìpìlẹ̀ ti Ìfihàn

Mo gbà yín níyànjù láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó ṣeéṣe láti gbọ́ ohùn Olúwa dáradárajù àti léraléra si ki ẹ lè gba òye tí Ó nfẹ́ láti fuń yín.

Àwòrán
gbìn

Fọ́tò láti inú àwọn àwòrán Getty.

Ní Ọgbọ̀n Ọjọ́ Oṣù Kẹsan, 2017, títẹ̀lé abala ọ̀sán ìpàdé àpapọ gbogbogbò, mo dúró ní ilé-ìwòsàn láti bẹ́ àyànfẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ iyejù mi wò Alàgbà Robert D. Hales. Ó ti wà ní ilé-ìwòsàn láti ìgbà tí ó ti njìyà àtakò ọkàn ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ ṣíwájú.

A ní ìbẹ̀wò tó yanilẹ́nú, ó sì dàbí ẹnipé ara rẹ̀ nyá si. Òun tilẹ̀ nmí fúnrarẹ̀, èyí tí ó jẹ́ àmì rere.

Ṣùgbọ́n, ní ìrọ̀lẹ́ yí, Ẹ̀mí bá ọkàn àti iyè-inú mi sọ̀rọ̀ pé kí èmí padà sí ilé-ìwòsàn ní Ọjọ́-ìsinmi. Ní abala òwúrọ̀ Ọjọ́-ìsinmi ti ìpàdé àpapọ gbogbogbò, ìtẹ̀mọ́ra líle náà padà wá. Mo ní ìmọ̀lára pé kí nfo oúnjẹ ọ̀sán kí nsì kánjú lọ sí ẹ̀gbẹ́ ìbùsùn Alàgbà Hales ní kété bí abala òwúrọ̀ bá ti parí, èyí tí mo ṣe.

Nígbàtí mo débẹ̀, mo ri pé ipò Alàgbà Hales ti yípada sí bíburú si. Pẹ̀lú ìbànújẹ́, ó papòdà ní ìṣẹ́jú mẹwa lẹ́hìn tí mo débẹ̀, ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ pé mo wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìyàwò rẹ̀ dídára, Màríà, àti àwọn ọmọkùnrin wọn méjì nígbàtí ó kúrò ní ayé yí.

Ìmoore mi ti pọ̀ tó pé àwọn ìkùnsíni Ẹ̀mí Mímọ́ ṣí mi létí láti ṣe ohun kan tí èmi kì bá ti ṣe bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìmoore mi sì ti pọ̀ tó fún òdodo ìfihàn àti pé àwọn ọ̀run ti ṣí lẹ́ẹ̀kan si.

Ní ọdún yí àwọn ìfojúsùn wa fún àṣàrò ti ara ẹni àti ti yàrá-ìkẹ́kọ̀ọ́ yíò jẹ́ Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú. “Àwọn ìfihàn àtọ̀runwá àti ìkéde ìmísí” wọ̀nyí lè bùkún gbogbo ẹni tí ó bá ṣe àṣàrò wọn tí wọ́n sì ṣe ìṣe lórí àwọn ìdarí àtọ̀runwá wọn. Wọ́n pe “gbogbo ènìyàn níbigbogbo láti gbọ́ ohùn Olúwa Jésù Krístì,”1 nítorí lotitọ “ohùn Olúwa wà fún gbogbo ènìyàn” (Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 1:2).

Ewu, Òkùnkùn, Ẹ̀tàn

Àwọn ìjì-líle ti-ara àti ti-ẹ̀mí jẹ́ ara ìgbé ayé ní orí ilẹ̀-ayé, bí àjàkàlẹ̀ àrùn COVID-19 ti rán wá létí. Nípa àkokò ṣíwájú Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀, Olùgbàlà sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọjọ́ ìpọ́njú nlá. Ó wípé, “Àwọn ìyan yíò wà, àti àwọn àjàkálẹ̀-àrùn, àti àwọn ìṣẹ́lẹ̀, ní onírurú ibi” (Joseph Smith—Matthew 1:29).

Mímu irú ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ le si ni òkùnkùn àti ìtànjẹ pùpọ̀ síi tí ó yí wa ká. Bí Jésù ti wí fún àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ yíò pọ̀ si” ṣíwájú ìpadàbọ̀ Rẹ̀ (Joseph Smith—Matthew 1:30).

Sátánì ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ̀ ogun rẹ̀ ó sì nbú ramúramù ní ìlòdì sí iṣẹ́ Olúwa àti àwa tí a wà nínú rẹ̀. Nítorí àwọn ewu púpọ̀si tí a ndojùkọ, ìnílò wa fún ìtọ́nisọ́nà ti ọ̀run kò ti ga julọ rí, àti pé àwọn ìtiraka wa láti gbọ́ ohùn Jésù Krístì—Olùlàjà, Olùgbàlà, àti Olùràpadà wa—kò tíi jẹ́ kánjúkánjú jùlọ rí.

Bí mo ti sọ ní kété lẹ́hìn tí a pè mí bí Ààrẹ Ìjọ, Olúwa ti ṣetán láti fi inú Rẹ̀ hàn sí wa. Ìyẹn ni ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tìtòbì Rẹ̀ jùlọ sí wa.2

Ní ọjọ́ wa, Ó ti ṣe ìlérí pé, “Bí a bá bèèrè, a ó gba ìfihàn lórí ìfihàn, ìmọ̀ lórí ìmọ̀” (Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 42:61).

Mo mọ̀ pé Òun yíò dáhùn sí àwọn ẹ̀bẹ̀ wa.

Bí A Ti Ngbọ́ Tirẹ̀

Mímọ̀ bí Ẹ̀mí ṣe nsọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì ní òní. Láti gba ìfihàn araẹni, láti rí àwọn ìdáhùn, àti láti gba ààbò àti ìdarí, a ní láti rántí àwọn àwòṣe tí Wòlíì Joseph Smith gbé kalẹ̀ fún wa.

Àkọ́kọ́, kí a ri ara wa sínú àwọn ìwé mímọ́. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nṣí inú àti ọkàn wa sí àwọn ìkọ́ni òtítọ́ Olùgbàlà. Àwọn ọ̀rọ̀ Krístì “sọ ohun gbogbo tí [a] níláti ṣe fún [wa]” (2 Néfì 32:3), nípàtàkì ní àwọn ọjọ́ àìní-ìrètí àti ìṣòro wọ̀nyí.

Èyítí ó kàn kí a gbàdúrà. Àdúra gba ọgbọ́n, kí a rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, kí a wá ibi dídákẹ́ jẹ́jẹ́ kan níbití a lè lọ lémọ́lemọ́, kí a sì tú ọkàn wa jáde sí I.

Olúwa wípé, “Sún mọ́ mi Èmi yíò sì sún mọ́ ọ; wá mi taratara ìwọ yíò sì rí mi; bèèrè, ìwọ yíó sì rí gbà; kànkù, a ó sì ṣí sílẹ̀ fún ọ” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:63).

Sísún mọ́ Olúwa nmú ìtùnú àti ìgbàni-níyànjú, ìrètí àti ìwòsàn wa. Nítorínáà, a ngbàdúra ní orúkọ Rẹ nípa àwọn ìdàmú wa àti àwọn àìlera wa, àwọn ìfojúsí wa àti àwọn olólùfẹ́ wa, àwọn ìpè wa àti àwọn ìbèèrè wa.

Nígbànáà a nfetísílẹ̀.

Bí a bá dúró lórí eékún wa fún ìgbà díẹ̀ lẹ́hìn tí a ti parí àdúra wa, àwọn èrò, àwọn ìmọ̀lára, àti ìdarí yíò wá sí inú wa. Kíkọ àwọn ìtẹmọ́ra wọnnì sílẹ̀ yíò ràn wá lọ́wọ́ láti rántí àwọn ìgbésẹ̀ tí Olúwa yíò fẹ́ kí a gbé.

Àwòrán
obìnrin tó nṣe-àṣàrò

Bí a ti nṣe àṣetúnṣe ètò yí, nínú ọ̀rọ̀ Wòlíì Joseph Smith, a ó “dàgbà sínú ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ìfihàn.”3

Yíyẹ láti Gba Ìfihàn

Títún okun wa ṣe láti dá ìkùnsíni Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀ àti mímú agbára wa láti gba ìfìhàn pọ̀ si nílò kíkàyẹ. Kíkàyẹ kò túmọ̀ sí pípé, ṣùgbọ́n ó nílò kí a làkàkà fún púpọ̀si ìwà-mímọ́.

Olúwa nretí ìtiraka ojojúmọ́, àtúnṣe ojojúmọ́, ìronúpìwàdà ojojúmọ́. Kíkàyẹ nmú ìwà-mímọ́ wá, àti pé ìwà-mímọ́ nmú wa yege fún Ẹ̀mí Mímọ́. Bí a ti nmú kí “Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ atọ́nà [wa]” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 45:57), a yege fún ìfihàn araẹni.

Bí ohun kan bá ndí wa lọ́wọ́ láti sí ilẹ̀kùn sí ìdárí tọ̀run, a lè nílò láti ronúpìwàdà. Ìrònúpìwàdà nfi ààyè gbà wá láti ṣí ilẹ̀kùn kí a lè gbọ́ ohùn Olúwa ní léraléra àti ní kedere si.

“Òṣùwọ̀n náà hàn kedere,” ni Alàgbà David A. Bednar ti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá kọ́ni. “Bí ohun kan tí a rò, tí a rí, tí a gbọ́, tàbí tí a ṣe bá mú wa jìnnà sí Ẹ̀mí Mímọ́, nígbànáà a gbọ́dọ̀ dúró ní ríronú, rírí, tàbí ṣíṣe ohun náà. Bí ohun èyí tí a bá rò láti dánilára yá, fún àpẹrẹ, bá mú wa kúrò lọ́dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, nígbànáà, dájúdájú irú ìdárayá bẹ́ẹ̀ kìí ṣe fún wa. Nítorí Ẹ̀mí kò lè gbé ní ibi èyí tí ó ní ìwà-ìríra, tí ó nro-ibi, tàbí àìsí-ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, nígbànáà irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ kò sí fún wa ní kedere.”4

Nígbàtí àwa tọkọ-taya bá mú ìwà-mímọ́ àti ìgbọràn pọ̀ si pẹ̀lú àwẹ̀, fífi taratara wá rí, ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè, àti tẹ́mpìlì àti iṣẹ́ ìtàn ẹbí, ọ̀run yíò ṣí sílẹ̀. Ní àbábọ̀, Olúwa, yío mú ìlérí Rẹ̀ ṣẹ pé: “Èmi yío fi fún yín lára Ẹ̀mi mi,èyí tí yío fi òye sí inú yín” (Ẹ̀kọ̀ àti àwọn Májẹ̀mú 11:13).

A lè nílò sùúrù, ṣùgbọ́n Ọlọ́run yíò bá wa sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ara Rẹ̀ àti ní àkòkò ti ara Rẹ̀.

Ẹ̀mi ti Ìmọ̀ kan

Jóbù kéde pé, “Ẹ̀mí kan wà nínú ènìyàn: ìmìsí Elédùmare sì nfún wọn ní ìmọ̀” (Job 32:8). Nínú ọdún titun yí, mo gbà yín níyànjù láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó ṣe dandan láti gbọ́ ohùn Olúwa dáradára àti léraléra si ki ẹ lè gba òye tí Ó nfẹ́ láti fifuń yín.

Ṣíwájú ikú Alàgbà Hales ní ọjọ́ náà ní Oṣù Kẹwa 2017, ó ti pèsè ọ̀rọ̀ kúkurú kan sílẹ̀ fún ìpàdé àpapọ gbogbogbò èyítí òun kò lè fifúnni. Nínú ọ̀rọ̀ náà, ó kọ pé, “Ìgbàgbọ́ wa nmúra wa sílẹ̀ láti wà níwájú Olúwa.”5

Nígbàtí a bá gbà ìfihàn, à nlo àkokò ní iwájú Ọlọ́run bí Òun ti nfi inú, ìfẹ́, àti ohùn Rẹ̀ hàn sí wá (wo Ẹkọ àti Àwọn Májẹmú 68:4). Njẹ́ kí a le fi ìgbàgbọ́ wa sínú ìṣe, ní kíké pè É, gbígbé ìgbé ayé yíyẹ fún ìmísí Rẹ̀ tí Ó ṣèlérí, àti ṣíṣé ìṣe lórí ìtọ́nisọ́nà tí a gbà.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́.

  1. Ọ̀rọ̀ Ìṣaájú sí Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú.

  2. Russell M. Nelson, “Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún àwọn Ìgbé-Ayé Wa,” Làìhónà, May 2018, 94.

  3. Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith (2007), 132.

  4. David A. Bednar, “Kí Ẹ̀mí Rẹ̀ Lè Wà Pẹ̀lú Wa Nígbàgbogbo,” Làìhónà, May 2006, 30.

  5. Nínú “Ohùn Olúwa” Neil L. Andersen, Làìhónà, Nov. 2017, 125.

Tẹ̀