2021
Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ẹbí Nran Àwọn Babanlá Wa Lọ́wọ́
Oṣù Kejìlá 2021


“Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ẹbí Nran Àwọn Babanlá Wa Lọ́wọ́,” Làìhónà, Oṣù Kejìlá 2021.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kejìlá 2021

Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ẹbí Nran Àwọn Babanlá Wa Lọ́wọ́

Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ẹbí jẹ́ síṣe àwárí àti kíkọ́ nípa àwọn ọmọlẹ́bi wa, Bákannáà a nkó àwọn ìwífúnni jọ nípa àwọn babanlá wa kí a le ṣe iṣẹ́ tẹ́mpìlì fún wọn.

Àwòrán
yí ọ̀rọ̀ kíkọsílẹ̀ padà

Àwọn ẹbí jẹ́ ààrin gbùngbùn sí ètò ìdùnnú ti Bàbá Ọ̀run. Ó ti pèsè ọ̀nà kan fún àwọn ẹbí láti tẹ̀síwájú títíláé. Bí a ti nṣe àwọn àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹbí àti iṣẹ́ tẹ́mpìlì wa, a nṣe ìrànwọ́ láti mú àwọn mọ̀lẹ́bí wa, méjèèjì ààyè àti òkú, papọ̀. (“Iṣẹ́ tẹ́mpìlì” túmọ̀ sí gbígba àwọn ìlànà tẹ́mpìlì fún ara wa, bíi jíjẹ́ fífi èdidi dì sí ọkọ tàbí aya wa, àti bákannáà bíi ṣíṣe àwọn ìlànà nínú tẹ́mpìlì fún àwọn babanlá wa.)

Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ẹbí àti Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì

Olúkúlùkù ènìyàn tí ó ti gbé tàbí tí yío gbé ní orí ilẹ̀ ayé nílò àwọn ìlànà ìhìnrere. Bí àwọn babanlá wa kò bá ní ànfàní náà, a le ṣe àwọn ìlànà fún wọn nínú tẹ́mpìlì. Ìkan nínú àwọn ìlànà wọ̀nyí ni jíjẹ́ fífi èdìdi dì mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bi. Jíjẹ́ “fifi èdìdi dì” túmọ̀ sí pé a ó lè gbé pẹ̀lú àwọn ẹbí wa títíláé bí a bá jẹ́ olódodo. A lè jẹ́ fífi èdìdi dì mọ́ àwọn ẹbí wa nínú àwọn tẹ́mpìlì nìkan.

Àwọn Ìbùkún Iṣẹ́ Àkọọ́lẹ̀-ìtàn Ẹbí

Àwòrán
ẹbí

Àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹbí le ràn wá lọ́wọ́ láti fi okun fún àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí wọ́n wà láàyè. Bí a ti nṣe àbápín àwọn ìtàn, àwọn fọ́tò, àti àwọn ìrántí míràn pẹ̀lú ara wa, a nṣe àgbékalẹ̀ àwọn àṣepọ̀ ẹbí. Bákannáà a nfi okun fún ìfẹ́ ti a ní sí ara wa. Àwọn wòlíì ti ṣe ìlérí bákannáà pé ṣíṣe iṣẹ́ lórí àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹbí wa yío mú wa súnmọ́ Jésù Krístì síi.

Wíwá Àwọn Babanlá Wa

Àwòrán
àwọn àkọsílẹ̀ ní èdè Chinese

Bàbá Ọrun nfẹ́ kí a jẹ́ fífi èdìdi dì mọ́ àwọn ẹbí wa lọ́wọ́lọ́wọ́ àti mọ́ àwọn babanlá wa. Kí a tó le jẹ́ fífi èdìdi dì mọ́ àwọn babanlá wa, a nílò láti wá àti láti ṣe ìpamọ́ ìwífúnni nípa wọn. Ṣùgbọ́n ìtàn ẹbí ju kí a kan ṣe ìwádìí àwọn orúkọ, àwọn ònkà ọjọ́, àti àwọn ibi ìṣẹ̀lẹ̀. Bí a ṣe nkọ́ nípa àwọn babanlá wa, a ó ní ìmọ̀lára sísomọ́ wọn síi.

Tẹ̀