2022
Ìṣubú Náà Jẹ́ Ara Ètò ti Ọlọ́run
Oṣù Kínní 2022


“Ìṣubú Náà Jẹ́ Ara Ètò ti Ọlọ̀run,” Làìhónà, Oṣù Ìkínní 2022

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Ìkínní 2022

Ìṣubú Náà Jẹ́ Ara Ètò ti Ọlọ́run

Nítorí Ìṣubú náà, a níláti wá sí ilẹ̀-ayé kí a lè padà ní ọjọ́ kan láti gbé pẹ̀lú Baba wa ní Ọ̀run.

Àwòrán
Ádámù àti Éfà

Ádámù àti Éfà nínú Ọgbà Édénì, nípasẹ̀ Robert T. Barrett

Nínú Ọgbà Édénì, Ọlọ́run pàṣẹ fún Ádámù àti Éfà kí wọ́n máṣe jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Lẹ́hìnnáà Ó wí fún wọn pé, “Ìwọ lè yàn fúnrarẹ, … ṣùgbọ́n, rántí pé mo káá léèwọ̀” (Mósè 3:17). Sátánì dán Éfà wò láti jẹ́ èso igi náà. Ó wí fun pe, “ìwọ yíò sì dàbí àwọn Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú” (Mósè 4:11). Ó jẹ èso náà lẹ́hìnnáà ó sì pín in pẹ̀lú Ádámù. Ọlọ́run lé wọn jáde kúrò ní Ọgbà Edeni.

Ìṣubú Náà

Àwòrán
Ádámù àti Éfà

A Lé Ádámù àti Éfà Jáde Nínú Ọgbà, nípasẹ̀ Gary L. Kapp, a kò lè ṣe ẹ̀dà rẹ̀

Nígbàtí Ádámù àti Éfà kúrò ní Ọgbà Edeni, wọn kò sí níwájú Ọlọ́run mọ́. Ìyapa kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yí ni a pè ní ikú ẹ̀mí. Kíkúrò nínú ọgbà bákannáà túmọ̀ sí pé Ádámù àti Éfà ti di kíkú àti pé báyìí wọ́n lè kú. Àní bíótilẹ̀jẹ́pé Ádámù àti Éfà kò sí pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ tí wọ́n sì jẹ́ kíkú nísisìyí, wọ́n ní ìdùnnú àti ìrètí nígbàtí wọ́n rí pé wọ́n lé ní ìlọsíwájú (wo Mósè 5:10–11). “Ádámù ṣubù kí àwọn ènìyàn lè wà; àwọn ènìyàn sì wà, kí wọ́n ó lè ní ayọ̀” (2 Néfì 2:25).

Àkokò Dídánwò Kan

Nígbàtí a bí wa, a gbé yàtọ̀ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ádámù àti Éfà ti ṣe lẹ́hìn Ìṣubú. Sátánì ndán wa wò láti ṣe àwọn àṣàyàn búburú. Àwọn àdánwò wọ̀nyí fi ààyè gbà wá láti gbìdánwò àti láti yàn ní àárín títọ́ àti àṣíṣe (wo Álmà 12:24). Ìgbà kọ̀ọ̀kan tí a bà dẹ́ṣẹ̀ tí a kò sì ronúpìwàdà, à ndàgbà ní kíkúró lọ́dọ̀ Baba Ọ̀run síwájú si. Ṣùgbọ́n bí a bá ronúpìwàdà, a ndàgbà súnmọ́ Baba wa ní Ọ̀run si.

Ikú Ara

Àwòrán
Itẹ́ ìsìnkú

A ti dá ilẹ̀-ayé fún wa (wo 1 Nefi 17:36). Ìṣubú náà mu ṣeéṣe fún Ádámù àti Éfà láti pa òfin Ọlọ́run mọ́ láti ní àwọn ọmọ, ní fífi ààyè gbà wá láti wá sí ilẹ̀-ayé nínú ẹran ti-ara. Àwọn ẹran-ara wa yíò kú níjọ́kan, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀mí wa yíò tẹ̀síwájú ní yíyè. Àwọn ẹran-ara wa àti ẹ̀mí yíò tún-darapọ̀ nígbàtí a bá jínde.

Gbàlà nípasẹ̀ Jésù Krístì

Àwòrán
Àjínde Jésù Krístì

Àjínde, nípasẹ̀ Harry Andersen

Nípa agbára ètùtù Jésù Krístì, a lè borí ikú ara àti ti-ẹ̀mí. Nítorí Krístì jínde, gbogbo ẹni tí a bí ní orí ilẹ̀-ayé yíò jínde wọ́n ó sì gbé títíláé. Àti pé nítorí Krístì jìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a lè ronúpìwàdà kí a sì gba ìdáríjì kí a lè gbé pẹ̀lú Baba ní Ọ̀run lẹ́ẹ̀kansi.

Tẹ̀