2022
Sísìn nínú Àwọn Ìpè Ìjọ
Oṣù Kẹ́ta 2022


“Sísìn nínú Àwọn Ìpè Ìjọ,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́ta 2022

Ọ̀rọ̀ Oṣoòṣù Làìhónà , Oṣù Kẹta 2022

Sísìn nínú Àwọn Ìpè Ìjọ

Àwọn olórí Ìjọ máa nsọ fún àwọn ọmọ ìjọ láti sìn ní àwọn ìpò ìfiṣẹ́rán pàtó tí a mọ̀ sí “àwọn ìpè.” Àwọn ìpè nfún àwọn ọmọ ìjọ ní ààyè láti sin àwọn ẹlòmíràn kí wọn ó sì súnmọ́ Ọlọ́run síi.

Àwòrán
ọkùnrin lórí àga-ìfirìn kan nkọ́ni ní kíláàsì Ìjọ kan

Àwòrán láti ọwọ́ David Bowen Newton

Nígbàtí a bá sìn nínú àwọn ìpè wa, a nṣe ìrànwọ́ láti mú iṣẹ́ Ọlọ́run di síṣe. A nkọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Baba Ọrun àti Jésù Krístì a sì nran àwọn tí a nkọ́ lọ́wọ́ lati súnmọ́ Wọn. Àwa bákannáà ngba ìbùkún bí a ti nsìn pẹ̀lú òtítọ́.

Gbígba Àwọn Ìpè

Àwòrán
Ọ̀dọ́mọkùnrin ndúró níwájú ìpéjọpọ̀ Ijọ kan

Àwọn tí wọ́n njọ́sìn nínú Ìjọ ni a pè láti ọwọ́ Ọlọ́run Àwọn olùdarí Ijọ máa ngbàdúrà fún ìmísí láti mọ ẹnití wọn le sọ fún láti sìn nínú ìpè kọ̀ọ̀kan. Olórí kan nígbànáà á sọ fún ọmọ ìjọ kan láti sìn yío sì ṣe àlàyé àwọn ojúṣe ti ìpè náà Àwọn ọmọ ìjọ ni a máa nmúdúró nínú ipàdé Ìjọ kan níbití àwọn ọmọ ijọ ní wọ́ọ̀dù tàbí ẹka yío ti fi ìbò ìmúdúró lélẹ̀. Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n ṣetán láti ṣe àtìlẹ́hìn fún ẹni náà tí a pè. Lẹ́hìnnáà ni a ó fún ọmọ ijọ náà ní ìbùkún láti ọwọ́ olùdarí olóyè àlùfáà kan. Èyí ni a pè ní jíjẹ́ yíyà sọ́tọ̀. Ọmọ ijọ náà ni a ó fún ní àṣẹ láti ṣiṣẹ́ nínú ìpè náà àti àwọn ìbùkún míràn láti ran ọkùnrin tàbí obìnrin náà lọ́wọ́ lati sìn.

Àwọn bíṣọ́ọ̀pù

Bíṣọ́ọ̀pù ni olórí wọ́ọ̀dù kan. (Ní ẹ̀ka kan, ààrẹ ẹ̀ka dàbíi bíṣọ́ọ̀pù) Ààrẹ èèkàn ni ó máa ndábàá olùdìmúi oyè àlùfáà yíyẹ kan láti jẹ́ pípè bíi bíṣọ́ọ̀pù. Àjọ Ààrẹ Kínní máa nfi ọwọ́ sí ìpè náà. Lẹ́hìnnáà à nṣe ìmúdúró Bíṣọ́ọ̀pù náà àti yíyà á sọ́tọ̀ láti sìn. Òun bákannáà yío gba àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè àlùfáà, èyítí ó túmọ̀ sí pé ó ní àṣẹ láti darí wọ́ọ̀dù náà. Bíi bíṣọ́ọ̀pù, ó nsìn ó sì ndarí gbogbo àwọn ọmọ ijọ ti wọ́ọ̀dù náà.

Àwọn Àjọ Ààrẹ

Àwọn ìkójọ iyejú Oyè Àlùfáà ati Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, Àwọn Ọdọ́mọbìnrin, Alákọ́bẹ̀rẹ̀, àti Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ni a ndarí nípasẹ̀ àwọn àjọ ààrẹ, bí àtẹ̀hìnwá ààrẹ kan àti olùdámọ̀ràn méjì. Àwọn àjọ ààrẹ iyejú àwọn alàgbà ni a npè tí a sì nyasọ́tọ̀ láti ọwọ́ ajọ ààrẹ èèkàn. Àjọ bíṣọ́ọ̀pù nsọ fún àwọn ọmọ ijọ láti sìn nínú àwọn àjọ ààrẹ míràn nínú wọ́ọ̀dù wọn á sì yà wọ́n sọ́tọ̀. Gbogbo àwọn olórí nsin àwọn ọmọ ijọ nínú àwọn iyejú tàbí àwọn ìkójọ wọn. Wọ́n nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àìní àwọn ọmọ ijọ wọ́n sì nràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run.

Àwòrán
obìnrin ngbé oúnjẹ wá fún ìyá kan tí ó gbé ọmọ lọ́wọ́

Àwọn Ìpè Míràn

Nínú àwọn ìpè Ìjọ míràn ni ìkọ́ni, ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú orin, ìpamọ́ àwọn àkọsílẹ̀, ṣíṣe ètò àwọn ìṣe ìdárayá fún àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọmọdé, àti sísìn ní àwọn ọ̀nà míràn. Ìpè kọ̀ọ̀kan nínú Ìjọ ṣe pàtàkì ó sì nfún àwọn ọmọ ìjọ ní ààyè láti sin àwọn ẹlòmíràn àti láti sin Ọlọ́run. Bí gbogbo wa ti nṣiṣẹ́ papọ̀ láti mú àwọn ìpè wa ṣẹ, a nfún àwọn ẹlòmíràn lókun a sì nran Ìjọ lọ́wọ́ láti dàgbà.

Tẹ̀