2022
Oúnjẹ Olúwa: Ọ̀nà Kan Láti Rántí Olùgbàlà
Oṣù Kẹrin 2022


“Oúnjẹ Olúwa: Ọ̀nà Kan Láti Rántí Olùgbàlà,” Liahona, Oṣù Kẹrin 2022.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹ́rin 2022

Oúnjẹ Olúwa: Ọ̀nà Kan Láti Rántí Olùgbàlà

Àwòrán
placeholder altText

Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn, láti ọwọ́ Simon Dewey

Ní àṣálẹ́ ṣíwajú kí a tó kàn án mọ́ àgbélèbú, Jesu Kristi ṣè ìpàdé pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀ níbi Oúnjẹ-alẹ́ Ìkehìn. Níbẹ̀ ni Ó fún wọn ní oúnjẹ Olúwa fún ìgbà àkọ́kọ́. Ó ṣe àlàyé pé ó jẹ́ ọ̀nà fún wọn láti ránti Òun. Oúnjẹ Olúwa ni ìlànà kan níbi tí a ti nṣe àbápín búrẹ́dì àti omi láti rántí Ètùtù. Búrẹ́dì jẹ́ àpẹrẹ ara Kristi, àti pé omi jẹ́ àpẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀.

À ńjẹ oúnjẹ Olúwa ní ọjọjọ́ Ìsinmi nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa. A kọ orin kan nigba ti àwọn tí ó di oye-àlùfáà mú já búrẹ́dì sí àwọn ẹ̀là kékèké.

Àwọn tí ó di oyè-àlùfáà mú tí wọ́n já búrẹ́dì sọ àwọn adura pataki. A rí àwọn àdúrà wọ̀nyí nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 20:77, 79. Àwọn àdúrà náà ránwa létí ohun tí a ti ṣe ìlérí fún Baba Ọ̀run àti ohun tí Ó ṣe ìlérí rẹ̀ fún wa.

Àwọn míràn tí ó di oyè-àlùfáà mú gbe oúnjẹ Olúwa fún àwọn ọmọ wọ́ọ̀dù tabi ẹka. Bí a ṣe njẹ oúnjẹ Olúwa, à nrántí Olùgbàlà àti ìrúbọ Rẹ̀ fún wa. Bákannáà à ńṣe àtúnfarajì sí pípa àwọn májẹ̀mú (àwọn ìlérí) tí a ṣe pẹ̀lú Baba Ọ̀run mọ́.

Àwòrán
Ọmọbìnrin nṣe àbápín búrẹ́dì nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa

À wà ní ọ̀wọ̀ nígbàtí a bá nbùkún tí a sì nfúnni ní oúnjẹ Olúwa. Ó jẹ́ àkókò láti ronú nípa ìgbé-ayé, ẹ̀kọ́ àti Ètùtù Jésù Krístì. Bákannáà a lè ronú lórí bí a ṣe lè tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀.

Tẹ̀