2022
Kíni Ìpàdé Ilé Ìrọ̀lẹ́?
Oṣù Kẹ́jọ 2022


“Kíni Ìpàdé Ilé Ìrọ̀lẹ́?” Làìhónà, Oṣù Kẹ́jọ 2022

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹ́jọ 2022

Kíni Ìpàdé Ilé Ìrọ̀lẹ́?

Àwòrán
Baba, ìyá, àti ọmọdébìnrin kékeré joko ní ìta

Ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́ ni àkokò kan tí a gbékalẹ̀ ní àárín ọ̀sẹ̀ fún ẹbí yín láti kórajọ. Ní àkokò yí, ẹ lẹ̀ “kọ́ ìhìnrere, fún àwọn ẹ̀rí lókun, gbé ìrẹ́pọ̀ ga, àti láti gbádùn ara wa” (Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn Nínú Ìjọ Jésù Kristi ti Àwọn eniyàn Mímọ́ Ojọ́-ìkẹhìn, 2.2.4, ChurchofJesusChrist.org). Ìpàdé Ilé ìrọ̀lẹ́ dàbí ó rí bákan fún ẹbí kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n àbájáde rẹ̀ ni láti lo àkokò yí láti súnmọ́ra papọ̀ si àti láti súnmọ́ Olùgbàlà si.

Ìmúrasílẹ̀

Ẹ ronú nípa ìṣe kan tí ẹbí yín gbádùn àti àkọlé ìhìnrere kan tí ẹ yíò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ lé kí ẹ sì kọ́ nípa rẹ̀ papọ̀. Bákannáà, ẹ yan ọjọ́ kan àti àkokò ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nígbàtí púpọ̀jù tàbí gbogbo ọmọ ẹbí lè pàdé. Ìjọ gba àwọn ọmọ-ìjọ níyànjú láti ṣe ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́ ní alẹẹlẹ́ ọjọ́-ajé. Ṣùgbọ́n àwọn ẹbí lè pàdé nígbàtí ó bá ṣiṣẹ́ jùlọ fún wọn.

Àwòrán
ẹbí ngbàdúrà

Àdúrà

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí nbẹ̀rẹ̀ wọ́n sì nparí ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́ pẹ̀lú àdúrà. Èyí npé Ẹ̀mí Mímọ́ sínú ilé wọn. Ìpàdé Ilé ìrọ̀lẹ́ ni àkokò tó dára fún àwọn ọmọdé àti àgbà láti kọ́ láti gbàdúrà pẹ̀lú ẹgbẹ́ kékerè kan.

Orin

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí bákannáà nní orin ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí. Wọ́n nsábà yan orin kan láti iwé-orin tàbí ìwé-orin Alakọbẹrẹ. Ìjọ ní àwọn àtẹ̀sílẹ̀ dùrù ti àwọn orin ní music.ChurchofJesusChrist.org. Bákannáà ẹ lè wo àwọn fídíò ti Akọrin Àgọ́ ní Ìgun-mẹ́rin Tẹ́mpílí. Kíkọrin nínú ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́ nran àwọn ọmọ-ẹbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn orin tí a nkọ ní ilé-ìjọsìn.

Ẹ̀kọ́

Ìjọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun èlò tí ó lè ṣèrànwọ́ pẹ̀lú ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́. Ẹ lè mú ìṣẹ́jú díẹ̀ láti ka àti láti sọ̀rọ̀ lórí àtẹ̀jáde látinú Làìhónà, Fríẹ̀ndì náà, tàbí Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́. Bákannáà èyí lè jẹ́ àkokò láti wò àti láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn fídíò Ìjọ. Tàbí ẹ lè ka ọ̀rọ̀ kan látinú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò, ka àwọn ìwé-mímọ́, tàbí sọ̀rọ̀ lórí ìwé-kíka ọ̀sẹ̀ náà nínú Wá, Tẹ̀lé Mi.

Àwòrán
àwọn ọmọdé nṣe àkàrà-òyìnbó

Àwòrán àwọn ọmọdé tí wọ́n nṣe àkàrà-òyìnbó láti ọwọ́ Michelle Loynes

Lílọ́wọ́sí Ẹbí

Àwọn ọmọdé lè kópa nínú ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́. Wọ́n lè ṣèrànwọ́ láti ṣètò àwọn ìṣe, gbàdúrà, tàbí yàn kí a sì darí àwọn orin. Àní wán lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́. Ṣíwájú ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́, ẹ lẹ̀ ran ọmọdé yín lọ́wọ́ láti ka ìtàn nínú iìwé ìròhìn Fríẹ́ndì tàbí ààyò ìtàn ìwé-mímọ́. Ọmọdé náà nígbànáà lè sọ ìtàn náà fún ẹbí bí ẹ̀kọ́. Bákannáà ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọdé fẹ́ràn láti máa ṣe eré látinú àwọn ìtàn iwé-mímọ́ fún ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́. Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé ṣètò ẹ̀kọ́ tàbí yan ọ̀rọ̀ kan látinú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò tí wọ́n fẹ́ láti kà. Lẹ́hìnnáà ẹ jẹ́ kí wọ́n darí ìbárasọ̀rọ̀ náà.

Àwọn ṣíṣe

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹbí gbádùn ṣíṣe àwọn ìṣe bí ara ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́. Àwọn ìṣe inú-ilé lè pẹ̀lú ìṣeré ìdárayá, ṣíṣé àwọn ọnà, tàbí dídáná papọ̀.

Fún àwọn ìṣe inú-ilé ẹ lè rìnká, lọ fún gígun-òkè ẹbí, tàbí ṣe eré ìdárayá kan níta papọ̀. Wá ìṣe kan tí gbogbo ọmọ ẹbí lè ṣe, kí ẹ sì gbádùn papọ̀. Ẹ yẹra fún àkokò ìdíje tí ó lè mú Ẹ̀mí kúrò.

Iṣẹ́-ìsìn

Ìpàdé ilé ìrọ̀lẹ́ ni àkokò nlá fún àwọn ẹbí láti sin àwọn ẹlòmíràn. Ẹ lè ran àwọn aladugbo àgbà díẹ̀ lọ́wọ́, pín oúnjẹ ní ilé aláìní kan, kọ̀wé sí òjíṣẹ́ ìhìnrere, tàbí ṣa ìdọ̀tí, fún àpẹrẹ.

Tẹ̀