“Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì,” Làìhónà, Oṣù Kẹ́rin, 2023.
Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà, Oṣù Kẹ́rin 2023
Ìgbàgbọ́ Nínú Jésù Krístì
Níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni àkọ́kọ́ ẹ̀kọ́ ìpìẹ̀ ti ìhìnrere (wo Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:4). Ìgbàgbọ́ wa yíò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àṣàyàn tí yíò darí wa padà sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run. A lè ṣiṣẹ́ láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun ní gbogbo ìgbé ayé wa.
Kíni Ìgbàgbọ́ Jẹ́?
Ìgbàgbọ́ jẹ́ níní ìgbàgbọ́ dídúró-ṣinṣin tàbí ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ohun kan. Láti ní ìgbàgbọ́ ní níní ìrètí nínú fún àti gbígbàgbọ́ nínú àwọn ohun tí ó jẹ́ òtítọ́, àní nígbàtí a kò lè rí wọn tàbí ní òye wọn tán pátápátá (wo Hébérù 11:1; Álmà 32:21).
Ìgbàgbọ́ tí ó Dálé Jésù Krístì
Láti darí sí ìgbàlà, ìgbàgbọ́ wa gbọdọ̀ dálé Jésù Krístì gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì túmọ̀ sí níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀. Ó túmọ̀ sí gbígbé ara lé E tán pátápátá—gbígbẹ́kẹ̀lé agbára, ìmòye, àti ìfẹ́ Rẹ̀. Bákannáà ó ní gbígbàgbọ́ àti títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ nínú.
Mímú Ìgbàgbọ́ Wa Pọ̀si
Ìgbàgbọ́ ni ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n a gbọdọ̀ lépa fún un kí a sì ṣiṣẹ́ láti paà mọ́ bí alágbára. A lè mú ìgbàgbọ́ wa pọ̀si nípa gbígba àdúrà àti ṣíṣe àsàrò àwọn ìwé-mímọ́ àti ìkọ́ni àwọn wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn. Bákannáà a nfún ìgbàgbọ́ wa lókun bí a ti ngbé ìgbé ayé òdodo tí a sì npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́.
Gbígbé nípa Ìgbàgbọ̀
Ìgbàgbọ́ ju kí a kàn gbàgbọ́ lọ. Ó ní ṣíṣe ìṣe lórí gbígbàgbọ́ náà nínú. À nfi ìgbàgbọ́ wa hàn nínú ọ̀nà ìgbé ayé wa. Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì nwú wa lórí láti tẹ̀lé àpẹrẹ pípé Rẹ̀. Ìgbàgbọ́ wa ndarí wa láti gbọ́ran sí àwọn òfin, ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí a sì dá àti kí a pa àwọn májẹ̀mú mọ́.
Ìgbàgbọ́ Lè Darí sí àwọn Iṣẹ́ Ìyanu
Ìgbàgbọ́ òtítọ́ nmú àwọn iṣẹ́ ìyanu wá, èyí tí ó lè ní àwọn ìran, àwọn àlá, àwọn ìwòsàn, àti àwọn ẹ̀bùn míràn tí ó nwá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nínú. Àwọn ìwé mímọ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìtàn àwọn ènìyàn nínú tí wọ́n gba àwọn iṣẹ́ ìyanu láti ọ̀dọ̀ Olúwa nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú Rẹ̀. Wo “Iṣẹ́ ìyanu” nínú Ìtọ́sọ́nà sí àwọn Ìwé mímọ́ fún àwọn àpẹrẹ.
Ìgbàgbọ́ Lè Mú Àláfíà Wá
Níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ètò ìgbàlà lè fún wa lókun ní àkokò àwọn ìpènijà wa. Ìgbàgbọ́ lè fún wa lókun láti tẹ̀síwájú kí a sì dojúkọ àwọn ìṣòro wa pẹ̀lú ìgboyà. Àní nígbàtí ọjọ́ ọ̀la bá dàbí àìdánilójú, ìgbàgbọ́ wa nínú Olùgbàlà lè fún wa ní àláfíà.
Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Ndarí sí Ìgbàlà
Lílo ìgbàgbọ́ nínú Krístì yíò darí sí ìgbàlà wa. Krístì ti múra ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti gba ìyè ayérayé. Bí a ti ngbé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀, a lè gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a sì padà láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kansi.
© 2023 nípasẹ̀ Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ní a pamọ́. A tẹ̀ẹ́ ní USA. Àṣẹ Èdè Gẹẹsì: 6/19. Àṣẹ Ìyírọ̀padà: 6/19. Ìyírọ̀padà ti Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kẹ́rin 2023. Language. 19006 779