2023
Gẹ́tsémánì
Oṣù Kẹfà 2023


“Gẹ́tsémánì,” Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́, Oṣù Kẹfà 2023.

Àwọn ibìkan láti inú Àwọn Ìwé-mímọ́

Gẹ́tsémánì

Kẹkọ si nípa ibi tí àwọn ìjìyà Olùgbàlà ti bẹ̀rẹ̀ ní ìtìlẹhìn wa.

Àwòrán
igbó-ṣúúrú ólífì

Ibo Ló Wà?

Ní orí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Ólífì, ní ìlà-òrùn Jérúsálẹ́mù (ọ́wọ́ ọ̀tún nínú ìjúwé, tí a fi àmì sí nípa igi tí ìwọ̀n rẹ̀ tóbijù).

Àwòrán
Àwòrán Jérúsálẹ́mù àtijọ́

Àwòrán ìjúwe Jérúsálẹ́mù láti ọwọ́ Jim Madsen

Kíni Ó Wà Níbẹ̀?

Igbó-ṣúúrú ti àwọn igi ólífì kan àti bóyá ìtẹ̀ kan fún gbígba òróró láti inú àwọn òlífì.

Àwòrán
ìtẹ̀ òlífì

Kíní Ó Ṣẹlẹ̀ Nihin?

Lẹ́hin Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹhìn, Jésù Krístì lọ pẹ̀lú mọ́kànlá nínú àwọn Àpóstẹ́lì Rẹ̀ sí Gẹ́tsémánì. Lẹ́hìnnáà Ó lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan láti gbàdúrà ó sì mú Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù pẹ̀lú Rẹ̀.

Ó “bẹ̀rẹ̀ sí ní ìyàlẹ́nú gidigidi, àti láti di rírẹ̀wẹ̀sì gan-an.” Ó wípé, “Ọkàn mi kẹ́dùn gidigidi dé ikú” (Márkù 14:33–34).

Ó gbàdúrà, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, gba ago yí lọ́wọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmí kọ́, bíkòṣe tìrẹ, ni kí a ṣe.

“Ángẹ́lì kan si yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ngbà á níyànjú.

“Bí ó sì ti wà ní ìwàyà-ìjà ó ngbàdúrà sí i kíkankíkan: òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ́ nlá, ó sì nkán sílẹ̀” (Luku 22:42–44).

Lẹ́hìn ìjìyà líle yí láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, a fi I hàn nípasẹ̀ Júdásì ó sì di mímú nípasẹ̀ àwọn olóye Júù àti ọ̀gbà àwọn ológun Rómù.

Àwòrán
Jésù Krístì ní Gẹ́thsémánì

Gẹ́tsémánì, láti ọwọ́ Michael Malm

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Ìtọ́sọ́nà sí àwọn Ìwé Mímọ́, “Gẹ́tsémánì.”

  2. Jeffrey R. Holland, ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2016 (Ẹ́nsáìnì tàbí Làìhónà,, Oṣù Kọkànlá, 2018, 50).

Tẹ̀