2023
Mímúrasílẹ̀ láti Lọ sí Tẹ́mpìlì
Oṣù Kejìlá 2023


“Mímúrasílẹ̀ láti Lọ sí Tẹ́mpìlì,” C, Oṣù Kejìlá 2023.

Ọ̀rọ̀ Oṣooṣù Làìhónà , Oṣù Kejìlá 2023

Mímúrasílẹ̀ láti Lọ sí Tẹ́mpìlì

àwọn ènìyàn nrìn lọ sí Tẹ́mpìlì Ogden Utah

Àwòrán Tẹ́mpìlì Ogden Utah láti ọwọ́ Mark Brunson

Nínú àwọn tẹ́mpìlì Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn a lè gba àwọn májẹ̀mú mímọ́ àti ìlànà fún arawa àti àwọn babanla wa. À nlọ sí tẹ́mpìlì láti fi ìfẹ́ wa hàn àti ìmoore fún Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì. A lè múrasílẹ̀ láti lọ sí tẹ́mpìlì nípa kíkọ́ àti gbígbé ìhìnrere Jésù Krístì. Fún ìwífúnni si nípa àwọn tẹ́mpìlì, wo àtẹ̀kọ awọn Kókó Ìhìnrere “Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì” nínú àtẹ̀jáde ti Làìhónà Oṣù Kẹwa.

àwọn ọ̀rọ̀ ní ìtà Tẹ́mpìlì Durban Gúsù Áfríkà

Àwòrán Tẹ́mpìlì Durban Gúsù Áfríkà láti ọwọ́ Matthew Reier

Ilé Olúwa Náà

Àwọn Tẹ́mpìlì ni à npè ní “ilé Olúwa.” Wọ́n jẹ́ àwọn ibi mímọ́ níbití a ti lè ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa. Bákannáà wọ́n jẹ́ àwọn ibi tí a ti lè dá àwọn májẹ̀mú kí a sì gba àwọn ìlànà pàtàkì tí yíò múra wa sílẹ̀ láti ní ìyè ayérayé. (Àwọn májẹ̀mú jẹ́ ìlérí mímọ́ ní àárín Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀.) Jíjẹ́ olotitọ sí àwọn májẹ̀mú wa àti gbígba àwọn ìlànà wọ̀nyí nràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbáṣepọ̀ pàtàkì pẹ̀lú Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì.

ọ̀dọ́ ndúró ní ìta Tẹ́mpìlì Guayaquil Ecuador

Àwòrán Tẹ́mpìlì Guayaquil Ecuador láti ọwọ́ Janae Bingham

Tani Ó Lè Lọ sí Tẹ́mpìlì?

Àwọn ọmọ Ìjọ lè ṣe ìrìbọmi fún àwọn òkú bíbẹ̀rẹ̀ ní ọdún tí wọ́n di ọmọ ọdún méjìlá. Ọmọ ìjọ kan lè gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì bí ọkùnrin tàbí obìnrin bá jẹ́ ọdún méjìdínlógún ó keréjù, ti jẹ́ ọmọ ìjọ fún ọdún kan ó kéréjù, àti ìfẹ́ láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì wa mọ́ (wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn Nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, 27.2.2, ChurchofJesusChrist.org). Ọkùnrin àti obìnrin kan tí ó ti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì wọn lè ṣe èdidì (gbéyàwó) fún àìlópin nínú tẹ́mpìlì.

Àwọn Májẹ̀mú àti àwọn Ìlànà

Ẹ ó dá àwọn májẹ̀mú ẹ ó sì gba àwọn ìlànà nínú tẹ́mpìlì. “Wíwọ inú májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nso wa pọ̀ Mọ́ Ọ ní ọ̀nà tí ó nmú ohungbogbo nípa ìgbé ayé rọrùn” (Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Rí Ìsinmi,” Liahona, Oṣù Kọ́kànlá 2022, 97). Ìlànà ìṣe mímọ́ àfojúrí kan ti a nṣe nípa àṣẹ́ oyè-àlùfáà. Àwọn ìlànà ní ìtumọ̀ ìjìnlẹ̀ ti-ẹ̀mí. Fún àpẹrẹ, nígbàtí ẹ bá kópa nínú ìlànà, ẹ nfihan Ọlọ́run pé ẹ nifẹ láti gbà àti láti pa àwọn májẹ̀mú Rẹ̀ mọ́.

Mímúrasílẹ̀ Araẹni

Ìmúrasílẹ̀ ti-ẹ̀mí nípa títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì àti pípa àwọn májẹ̀mú tí ẹ ti ṣe pẹ̀lú Ọlọ́run níbi ìrìbọmi mọ́. Bákannáà ẹ lè ṣe àṣàrò àwọn ohun-èlò Ìjọ, bí irú àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Temples.ChurchofJesusChrist.org npèsè ìwífúnni nípa ohun tí à nretí nígbàtí a bá lọ sí tẹ́mpìlì. Bákannáà ó pẹ̀lú àwọn àlàyè si nípa àwọn májẹ̀mú, ìlànà, àti àmì tẹ́mpìlì.

níta Tẹ́mpìlì Nauvoo Illinois

Àwòrán Tẹ́mpìlì Nauvoo Illinois láti ọwọ́ Eve Tuft

Àmì

Nígbakugbà Olúwa máa nkọni ní lílo àwọn àmì. Fún àpẹrẹ, ìrìbọmi—lílọ sábẹ́ omi àti wíwá sókè lẹ́ẹ̀kansi—dàbí kíkú ara àtijọ́ àti àtúnbí ara titun (wo Rómù 6:3–6). Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì tọ́ka sí Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Ó lè nira láti ní òye gbogbo àmì ní ìgbà àkọ́kọ́ tí ẹ lọ sí tẹ́mpìlì, ṣùgbọ́n ẹ lè tẹ̀síwájú ní kíkọ̀ bí ẹ ó ṣe padà sí tẹ́mpìlì ní gbogbo ayé yín.

Ìkaniyẹ Tẹ́mpìlì

Láti wọ tẹ́mpìlì, ẹ níláti múrasílẹ̀ kí ẹ sì wà ní yíyẹ. Ẹ lè gba ìkaniyẹ láti wọnú tẹ́mpìlì lẹ́hìn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù yín tàbí ààrẹ ẹ̀ka àti pẹ̀lú ààrẹ èèkàn àti míṣọ̀n. Àwọn olórí wọ̀nyí yíò bèèrè àgbékalẹ̀ àwọn ìbèèrè láti mu dájú pé ẹ̀ ngbé ìgbé-ayé ìhìnrere Jésù Krístì. Àwọn olórí yín lè sọ̀rọ̀ sí yín nípa àwọn ìbèèrè wọ̀nyí ṣíwájú àkokò.

Pípadà sí Tẹ́mpìlì fún àwọn Babanla Yín

Baba Ọ̀run nfẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀ dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀ àti kí a gba àwọn ìlànà mímọ́. Àwọn ìlànà wọ̀nyí, bí irú ìrìbọmi àti ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, ni a gbúdọ̀ ṣe nínú tẹ́mpìlì fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti kọjá lọ láì gba ìhìnrere. Ẹ lè padà sí tẹ́mpìlì láti ṣe àwọn ìlànà fún àwọn olóògbé ọmọ ẹbí yín.