Àwọn Ìlànà àti àwọn Ìkéde
Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́


Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́
ti Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn

1 A gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, àti nínú Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, àti nínú Ẹ̀mí Mímọ́.

2 A gbàgbọ́ wípé gbogbo ènìyàn yíó jìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ ara wọn láìṣe fún ìrékọjá Ádámù.

3 A gbàgbọ́ wípé nípasẹ̀ ètùtù Krístì, gbogbo ènìyàn lè ní ìgbàlà, nípa ìgbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà ìhìnrere.

4 A gbàgbọ́ wípé àwọn ìpìnlẹ̀ àti àwọn ìlànà ìhìnrere àkọ́kọ́ ni: Èkíní, Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì; Èkejì, Ìrònúpìwàdà; Ẹ̀kẹta, Baptísímù nípá ìrìbọmi fún ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀; Ẹ̀kẹrin, ìgbọ́wọ́ lé lórí fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.

5 A gbàgbọ́ wípé ènìyàn gbọ́dọ̀ gba ìpè Ọlọ́run, nípa àsọtẹ́lẹ̀, àti nípa gbígbọ́wọ́ lé lórí nípasẹ àwọn tí ó wà nípò àṣẹ, láti ṣe ìwàásù ìhìnrere àti láti kópa nínú àwọn iṣẹ́ ìlànà inú rẹ̀.

6 A gbàgbọ́ nínú àkójọpọ̀ kannã tí ó wà nínú Ìjọ Àtijọ́, olórúkọ bíi, àwọn àpóstélì, àwọn wòlĩ, àwọn olùṣọ́-àgùntàn, àwọn olùkọ́ni, àwọn ẹ̀fángẹ́lístì àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

7 A gbàgbọ́ nínú ẹ̀bùn ìfèdèsòrò, àsotẹ́lẹ̀, ìfihàn, àwọn ìran, ìwòsàn, ìtúmọ̀ èdè àti bẹ̃bẹ̃ lọ.

8 A gbàgbọ́ wípé Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣe ìtúmọ̀ rẹ̀ ní pípé; A gbàgbọ́ bákannã pé Ìwé Ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

9 A gbàgbọ́ nínú gbogbo ohun ti Ọlọ́run ti fihàn, gbogbo ohun tí Ó ńṣe ìfihàn rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, a sì gbàgbọ́ wípé Ó yì mã ṣe ìfihàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ńlá àti pàtàkì tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìjọba Ọlọ́run.

10 A gbàgbọ́ nínú ìkọ́jọpọ̀ Ísráẹ́lì gãn àti nínú ìmúpadà àwọn Ẹ̀yà Mẹ́wá; pé Síónì (Jerúsálẹ́mù titun nì) yíó jẹ́ kíkọ́ lórí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà; pé Krístì yíó jọba fúnra rẹ̀ lórí ayé; àti pé ayé yíó di ìsọdititun yíó sì gba ògo párádísè rẹ̀.

11 Àá nṣe ìbéèrè ẹ̀tọ́ láti sin Ọlọ́run Atóbijùlọ gẹ́gẹ́ bĩ ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí ọkàn wa, a sì gba gbogbo ènìyàn láàyè fún irú ẹ̀tọ́ bẹ̃, jẹ́ kí wọ́n jọ́sìn bí, níbi, ohun tí wọ́n lè ṣe.

12 A gbàgbọ́ nínú títẹríba fún àwọn ọba, àwọn ãrẹ, àwọn alákóso, àwọn onídájọ́, ní gbígbọ́nràn sí, bíbọ̀wọ̀ fún àti ṣíṣe ìmúdúró òfin.

13 A gbàgbọ́ nínú síṣõtọ́, jíjẹ́ olóótọ́, aláì ní ẽrí, onínúrere, oníwà ọ̀wọ̀ àti ní ṣíṣe rere sí gbogbo ènìyàn; nítõtọ́, a lè sọ wípe à á ntẹ̀lé ìmọ̀ràn Páùlù — A gba ohun gbogbo gbọ́, a nírètí nínú ohun gbogbo, a ti farada ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun, a sì nírètí pé a ó lè farada ohun gbogbo. Tí a bá rí nkankan tí ó níwà ọ̀wọ̀, tí ó dára, tàbí tí ó ní ìròyìn rere tàbí yẹ fún ìyìn, à á nwá nkan wọ̀nyí.

Joseph Smith

Tẹ̀