Ìwé ti Jákọ́bù
Arákùnrin Ti Néfáì
Àwọn ọ̀rọ̀ ìwãsù rẹ̀ sí àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó dãmú ọkùnrin kan ẹnití ó wá ọ̀nà láti ti ẹ̀kọ́ ti Krístì ṣubú. Ọ̀rọ̀ ṣókí nípa ìtàn ará Nífáì.
Orí 1
Jákọ́bù àti Jósẹ́fù wá ọ̀nà láti yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà láti gbàgbọ́ nínú Krístì kí nwọ́n sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́—Nífáì kú—Ìwà búburú gbilẹ̀ l’ãrín àwọn ará Nífáì. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Nìtorí kíyèsĩ, ó sì ṣe pé ãdọ́ta ọdún ó lé mãrún ti kọjá láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù; nígbànã, Nífáì fún èmi, Jákọ́bù ní òfin kan nípa àwọn àwọn àwo kékeré nnì, lórí èyítí a gbẹ́ àwọn nkan wọ̀nyí lé.
2 Ó sì fún èmi, Jákọ́bù, ní òfin kan pé kí èmi kí ó kọ ọ́ lé orí àwọn àwo wọ̀nyí díẹ̀ nínú àwọn nkan tí mo kãkún pé ó jẹ́ iyebíye jùlọ; pé kí èmi máṣe fi ọwọ́ kàn, àfi ní ṣòkí, nípa ìtàn àwọn ènìyàn yĩ tí à npè ní àwọn ènìyàn Nífáì.
3 Nítorítí ó sọ̀ wípé kí a fín ìtàn àwọn ènìyàn rẹ̀ sí orí àwọn àwo rẹ̀ míràn, pé kí èmi kí ó sì pa àwọn àwo wọ̀nyí mọ́ kí èmi kí ó sì fi wọ́n lé ọwọ́ èso mi, láti ìran dé ìran.
4 Tí ìwãsù tí ó jẹ́ mímọ́, tàbí ìfihàn tí ó tóbi, tàbí ìsọtẹ́lẹ̀ bá wà, pé kí èmi kí ó fín àwọn èyí tí ó ṣe kókó nínú wọn sí orí àwo wọ̀nyí, kí èmi kí ó sì kọ nípa wọn bí ó ti pọ̀ tó, nítorí ti Krístì, àti fún ànfãní àwọn ènìyàn wa.
5 Nítorípé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti àníyàn jọjọ, a ti fihàn wá nítòọ́tọ́ nípa àwọn ènìyàn wa, ohun tí yíò ṣẹlẹ̀ sí nwọn.
6 A sì ní àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfihàn pẹ̀lú àti ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ púpọ̀; nítorí-èyi, a mọ̀ nípa Krístì àti ìjọba rẹ̀ èyítí nbọ̀wá.
7 Nítorí-èyi a ṣiṣẹ́ taratara ní ãrín àwọn ènìyàn wa, kí àwa kí ó lè yí wọn l’ọ́kàn padà láti wá sọ́dọ̀ Krístì, kí wọ́n sì ní ìpín nínú ire Ọlọ́run, kí nwọ́n wọ inú ìsinmi rẹ̀, bí bẹ̃kọ́ ní ọ̀nà kọnà òun ó búra nínú ìbínú rẹ̀ pé kí wọ́n má wọlé, gẹ́gẹ́bí ìmúnibínú ti ìgbà ìdánniwò nígbàtí àwọn ọmọ Ísráélì wà ní aginjù.
8 Nítorí-èyi, àwa nfẹ́, nípa õre ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa lè yí ọkàn gbogbo ènìyàn padà kí nwọn máṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, láti pẽ ní ìjà sí ìbínú, ṣùgbọ́n kí gbogbo ènìyàn gbàgbọ́ nínú Krístì, kí wọ́n sì gba ikú rẹ̀ rò, ki nwọn ro ìjìyà rẹ̀ lórí àgbélèbú, àti kí wọ́n faradà ìtìjú ayé; nítorí-èyi, èmi Jákọ́bù, pinnu láti mú òfin arákùnrin mi Nífáì ṣẹ.
9 Nísisìyí Nífáì bẹ̀rẹ̀sí di arúgbó, ó sì ríi pé òun yíò kú láìpẹ́; nítorí-èyi ó ṣe ìfòróró yàn fún ọkùnrin kan láti jẹ́ ọba àti alãkóso lórí àwọn ènìyàn rẹ̀, gẹ́gẹ́bí ìjọba àwọn ọba.
10 Àwọn ènìyàn nã nítorítí nwọ́n fẹ́ràn Nífáì lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorítí òun ti jẹ́ alãbò nlá fún wọn, nítorítí ó fi agbára lo idà Lábánì ní ìdãbò fún wọn àti nítorítí ó ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ fún àlãfíà nwọn—
11 Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn nã ní ìfẹ́ láti jẹ́ orúkọ rẹ̀ sí ìrántí. Ẹnití yíò bá sì jọba rọ́pò rẹ̀ ni àwọn ènìyàn pè ní Nífáì èkejì, Nífáì ẹ̀kẹ́ta, àti bẹ̃bẹ̃ lọ, nípa ìjọba àwọn ọba nã; báyĩ sì ni àwọn ènìyàn nã pè nwọ́n, èyíkẽyí orúkọ tí wọn ìbã fẹ́ láti jẹ́.
12 Ó sì ṣe tí Nífáì kú.
13 Ní báyĩ àwọn ènìyàn tí nwọn kĩ ṣe ará Lámánì, jẹ́ ará Nífáì; bíótilẹ̀ríbẹ̃, a pè wọ́n ní ará Nífáì, ará Jákọ́bù, ará Jósẹ́fù, ará Sórámù, ará Lámánì, ará Lémúẹ́lì, àti ará Íṣmáélì.
14 Ṣùgbọ́n èmi, Jákọ́bù kò ní ṣe ìyàtọ̀ sí wọn nípasẹ̀ orúkọ wọ̀nyí, ṣùgbọ́n èmi yíò pè wọ́n ní ará Lámánì èyítí ó lépa láti pa àwọn ènìyàn Nífáì run, àti àwọn tí wọ́n bá sì bá Nífáì ṣe ọ̀rẹ́ ni èmi yíò pè ní ará Nífáì, tàbí àwọn ènìyàn Nífáì gẹ́gẹ́bí ìṣe àwọn ìjọba àwọn ọba.
15 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí àwọn ará Nífáì, ní ábẹ́ ìjọba ọba èkejì, bẹ̀rẹ̀sí sé aya nwọn le, nwọ́n sì nhu àwọn ìwà búburú, gẹ́gẹ́bí Dáfídì ti ìgbà nnì tí ó nfẹ́ láti ní ìyàwó àti àlè púpọ̀, àti Sólómọ́nì pẹ̀lú, ọmọkùnrin rẹ̀.
16 Bẹ̃ni, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà àti fàdákà pẹ̀lú, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sĩ gbé ojú sókè nínú ìwà ìgbéraga.
17 Nítorí-èyi èmi, Jákọ́bù, fún wọn ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí mo ṣe kọ́ wọ́n nínú tẹ́mpìlì, nítorítí èmi ti kọ́kọ́ gba iṣẹ́ mi lọ́dọ̀ Olúwa.
18 Nítorí, èmi, Jákọ́bù, pẹ̀lú arákùnrin mi Jósẹ́fù, ni a ti yà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́bí àlùfã àti olùkọ́ni fún àwọn ènìyàn yĩ, láti ọwọ́ Nífáì.
19 Àwa sì ṣe ìmútóbi ipò tí a pè wá sí, wa sí Olúwa, ní siṣe ojuse wa, ki a si dáhùnsí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí sori wa tí àwa kò bá kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọkàn-tọkàn; nítorí-èyi, nípa ṣíṣe iṣẹ́ pẹ̀lú agbára wa, ẹ̀jẹ̀ wọn kò ní wá sí ára aṣọ wa; bíbẹ̃kọ́, ẹ̀jẹ̀ wọn yíò wá sí ára aṣọ wa, a kò sì ní wà ní mímọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn.