Àwọn Ìwé Mímọ́
Jákọ́bù 2


Orí 2

Jákọ́bù ṣe ìkọ̀sílẹ̀ ọrọ̀, ìgbéraga, àti àìpa-ara-ẹni-mọ́—àwọn ènìyàn lè lépa ọrọ̀ fún ìrànlọ́wọ́ àwọn arákùnrin nwọn—Jákọ́bù fi ẹnu ẹ̀tẹ́ bá fífẹ́ aya púpọ̀ tí kò ní àṣẹ nínú—Olúwa ní ìyọ́nú sí wíwà-ní-mímọ́ àwọn obìnrin. Ní ìwọ̀n ọdún 544 sí 421 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jákọ́bù, arákùnrin Nífáì, bá àwọn ará Nífáì sọ, lẹ́hìn ikú Nífáì:

2 Nísisìyí, ẹ̀nyin arákùnrin mi àyànfẹ́, èmi, Jákọ́bù, gẹ́gẹ́bí ipò tí mo wà ní ìhà Ọlọ́run, láti ṣe ìmútóbi ipò tí a pè mi sí mi pẹ̀lú ìwà ìfarabalẹ̀, àti pẹ̀lú pé kí èmi kí ó lè wẹ ẹ̀wù mi mọ́ ní ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nyín, èmi wá sí tẹ́mpìlì ní òní kí èmi kí ó lè sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún nyín.

3 Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ pé títí di ìsisìyí pé mo ti ṣe ãpọn nípa ìpè mi; ṣùgbọ́n ní òní yĩ, ọkàn mi wúwo púpọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àníyàn àti ãjò fún wíwà ní àlãfíà ẹ̀mí nyin ju ti àtẹ̀hìnwá.

4 Nítorí kíyèsĩ, ní báyĩ, ẹ̀nyin ti ṣe ìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Olúwa, èyítí mo ti fi fún un nyín.

5 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ẹ fetísílẹ̀ sí mi, kí ẹ sì mọ̀ pé nípa ìrànlọ́wọ́ ẹni-alágbára-jùlọ, Ẹlẹ́dã Ọ̀run òun aiyé èmi lè sọ fún nyín nípa èrò ọkàn nyín, bí ẹ̀yin ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀sẹ̀ èyítí ó jẹ́ ìríra jùlọ níwájú mi, bẹ̃ni, àti tí ó jẹ́ ìríra jùlọ níwájú Ọlọ́run.

6 Bẹ̃ni, ó jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún ọkàn mi, ó sì jẹ́ kí èmi kí ó súnrakì pẹ̀lú ìtìjú ní iwájú Ẹlẹ́da mi, pé èmi gbọ́dọ̀ j’ẹ̀rí síi nyín nípa búburú ọkàn nyín.

7 Àti pẹ̀lú ó sì jẹ́ ohun ẹ̀dùn fún mi pé mo níláti fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa nyín, níwájú àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ nyín, tí ọ̀pọ̀ èrò ọkàn púpọ̀ nínú wọn jẹ́ ọ̀dọ́ àti wíwà-ní-mímọ́ àti ẹlẹgẹ́ níwájú Ọlọ́run, èyítí ó jẹ́ ohun ìdùnnú fún Ọlọ́run;

8 Ó sì jẹ́ ohun tí èmi rò pé wọ́n wá sí ìhín láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run èyítí ó tuni nínú, bẹ̃ni, ọ̀rọ̀ tí í ṣe ìwòsàn fún ọkàn tí ó gbọgbẹ́.

9 Nítorí-èyi, ó jẹ́ ohun ìnira fún ọkàn mi pé mo níláti mú u ní dandan, nítorí òfin tí ó múná èyítí èmi ti gbà láti ọ́wọ́ Ọlọ́run, láti rọ̀ yín níti ìwà búburú nyin, èyítí o dá kun ìrora àwọn tí a ti dá lóró, kàkà kí ẹ̀nyin ìbá tù wọ́n nínú, kí ẹ sì wo awọn ọgbẹ́ wọn san; àti àwọn tí ọkàn nwọn kò ì tĩ gb’ọgbẹ́, kàkà kí ẹ̀nyin ó fi ọ̀rọ̀ ìtùnú Ọlọ́run bọ́ nwọn, ẹ̀nyin fi ọ̀kọ̀ gún wọn ní ọkàn tí ẹ sì ṣá iyè inú ẹlẹgẹ́ wọn lọ́gbẹ́.

10 Ṣùgbọ́n, l’áìṣírò títóbi iṣẹ́ nã, èmi níláti ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn òfin tí ó múná ti Ọlọ́run, kí èmi kí ó sì sọ fún nyín nípa ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra yín, níwájú ẹnití ọkàn rẹ mọ́, tí ó sì gbọgbẹ́, àti lábẹ́ ìwárìrì ojú Ọlọ́run Olódùmarè tí ó rí ohun gbogbo.

11 Nítorí-èyi, mo níláti sọ òtítọ́ fún nyín nípa kedere ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí kíyèsi, bí èmi ṣe ṣe ìwádĩ lọ́dọ̀ Olúwa, bẹ̃ni ọ̀rọ̀ nã tọ̀ mi wa, tí ó sọ wípé: Jákọ́bù, dìde lọ sínú tẹ́mpìlì ní ọ̀la, kí o sì sọ ọ̀rọ̀ nã èyítí èmi yíò fi fún ọ fún àwọn ènìyàn yí.

12 Àti nísisìyí kiyesì, ẹ̀nyin arákùnrin mi, èyí ni ọ̀rọ̀ ná tí èmi sọ fún nyín, wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nyín ti bẹ̀rẹ̀sí ṣe àférí wúrà, àti fún fàdákà, àti fún oríṣiríṣi àwọn irin aìpò olówó iyebíye, nínú ilẹ̀ yìi, èyítí í ṣe ilẹ̀ ìlérí fún ẹ̀nyin àti àwọn irú ọmọ nyin, èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú rẹ.

13 Àti pẹ̀lú pé òjò ìbùkún sì ti rọ̀ lé nyín lórí lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ẹ̀yin sì ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; àti nítorípé àwọn míràn nínú nyín ti gbà lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn arákùnrin nyín lọ, a gbé yín sókè nínú ìgbéraga ọkàn nyín, ẹ̀ nṣe ọkàn líle àti orí kunkun nítorí aṣọ olówó iyebíye yín, ẹ sì npẹ̀gàn àwọn arákùnrin nyín nítorítí ẹ̀nyin rò wípé ẹ dára jú nwọ́n lọ.

14 Àti nísisìyí, ẹ̀nyin arákùnrin mi, njẹ́ ẹ rò wípé Ọlọ́run dá nyín láre nínú nkan yĩ? Kíyèsĩ, mo wí fún nyín, rara. Ṣùgbọ́n ó dá nyin lẹ́bi, tí ẹ̀nyin bá sì tẹramọ́ ṣíṣe ohun wọ̀nyí, ìdájọ́ rẹ níláti tọ́ nyín wà kánkán.

15 A! òun ìbá sì fi hàn nyín pé òun lè gún yín, àti pé, pẹ̀lú wíwo ìṣẹ́jú akàn pẹ̀lú ojú rẹ̀, òun leè lu nyín bolẹ̀ mọ́ eruku.

16 A! òun ìbá sí gbọ̀n yín nù kúrò nínú àìṣedẽdé àti ohun ìríra yĩ. Àti pé, A! ẹ̀nyin ìbá sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ìpaláṣẹ rẹ, kí ẹ má sì jẹ́ kí ìgbéraga ọkàn nyín yí pa ẹ̀mí nyín run!

17 Ẹ rò nípa àwọn arákùnrin nyín gẹ́gẹ́bí ara yín. Kí ẹ sì fifúnni nínú ohun ìní nyín, kí nwọ́n lè ní ọrọ̀ bí ẹ̀yin.

18 Ṣugbọ́n kí ẹ̀nyin tó lépa ọrọ̀, ẹ lépa ìjọba Ọlọ́run.

19 Àti lẹ́hìn tí ẹ̀nyin bá ti gba ìrètí nínú Krístì, ẹ̀nyin yíò gba ọrọ̀, tí ẹ bá lépa nwọn; ẹ̀nyin yíò sì lépa wọn fún èrò láti ṣe rere—láti wọ aṣọ fún ẹnití ó wà ní áìbò, àti áti bọ́ ẹnití ebi npa, àti láti tú ẹnití ó wà ní ìgbèkùn sílẹ̀, àti láti ṣe ìtọ́jú aláìsàn àti ẹnití ìyà njẹ.

20 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ti sọ̀rọ̀ fún nyín nípa ìgbéraga; àti ẹ̀nyin tí ẹ ti fi ìyà jẹ aládũgbò nyín, tí ẹ sì ṣe inúnibíni síi nítorípé ẹ̀nyin gbéraga ni ọ́kàn nyín, nínú àwọn ohun tí Ọlọ́run ti fún nyín, kíni ẹ̀nyin sọ nípa rẹ?

21 Ẹ̀yin kò ha rò wípé àwọn nkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìríra sí ẹnití ó da gbogbo ẹlẹ́ran-ara? Àti pé ẹ̀dá kan níye lórí ní ojú rẹ̀ gẹ́gẹ́bí èkejì. Àti pé erùpẹ̀ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara; àti fún ara rẹ̀ kan nã ni ó ṣe dá nwọn, pé kí wọn lè pa awọn òfin òun mọ́, kí wọ́n sì máa yìn òun títí láé.

22 Àti nísisìyí, èmi dẹ́kun bíbá nyín sọ̀rọ̀ nípa ìgbéraga yĩ. Bí kò bá sí ṣe pé mo níláti sọ̀rọ̀ fún nyín nípa ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ga ju t’àtẹ̀hìnwá, ọkàn mi kì bá yọ̀ púpọ̀ nítorí yín.

23 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ mí lọ́rùn nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ nyín èyítí ó ga ju ti àtẹ̀hìnwá. Sì kíyèsĩ, báyĩ ni Olúwa wí: Àwọn ènìyàn wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀ nínú àìṣedẽdé; ìwé-mímọ́ kò yé wọn, nítorítí nwọ́n nífẹ́ láti dá ara wọn láre nínú ìwà àgbèrè, nítorí àwọn nkan tí a kọ nípa Dáfídì, àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀.

24 Kíyèsĩ, Dáfídì àti Sólómọ́nì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya pẹ̀lú àlè nítõtọ́, èyítí ó jẹ́ ohun ìríra níwájú mi, ni Olúwa wí.

25 Nítorí-èyi, báyĩ ni Olúwa wí, èmi ti darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, nípa agbára apá mi, kí èmi lè gbe ẹ̀ka olódodo kan dìde sí èmi láti inú èso ti ìhà Jósẹ́fù.

26 Nítorí-èyi, èmi Olúwa Ọlọ́run kò ní gbà kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe bí àwọn ará ìgbà nnì.

27 Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ gbọ́ mi, kí ẹ sì fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ Olúwa: Bẹ̃ni ẹnì kan nínú nyín kò gbọ́dọ̀ ní ju aya kan; kò sì gbọ́dọ̀ ní àlè kankan;

28 Nítorípé èmi, Olúwa Ọlọ́run, dunnú sí wíwà-ní-mímọ́ àwọn obìnrin. Àwọn ìwà àgbèrè sì jẹ́ ohun-ìríra níwájú mi; báyĩ ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wi.

29 Nítorí-èyi, àwọn ènìyàn yĩ yíò pa àwọn òfin mi mọ́, ní Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, l’áìjẹ́ bẹ̃, a ó fi ilẹ̀ nã bú nítorí nwọn.

30 Nítorípé bí èmi bá fẹ́, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, gbé irú-ọmọ dìde fún mi, èmi yíò paṣẹ fún àwọn ènìyàn mi; bíbẹ̃kọ́ nwọn yíò fetísílẹ̀ sí àwọn ohun wọ̀nyí.

31 Nítorí kíyèsĩ, èmi, Olúwa, ti rí ìrora-ọkàn nã, mo sì ti gbọ́ ìbinújẹ́ àwọn ọmọbìnrin dáradára àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, bẹ̃ni, àti ní gbogbo ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi, nítorí ìwà búburú àti ìwà ìríra àwọn ọkọ wọn.

32 Àti pé, èmi kò ní gbà, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí, pé kí igbe àwọn ọmọbìnrin dáradára àwọn ènìyàn yĩ, tí mo ti sin jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, gòkè tọ̀ mí wá, ní ìkọlù àwọn okùnrin àwọn ènìyàn mi, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wi.

33 Nítorítí wọn kò ní mú àwọn ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi jáde lọ sí ìgbèkùn nítorí ìwàpẹ̀lẹ́ wọn, láìjẹ́bẹ́ẹ̀ èmi yíò bẹ̀ wọ́n wò pẹ̀lú ègún kíkan, àní sí ìparun; nítorítí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè, gẹ́gẹ́bí àwọn ará ìgbãnì, ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wi.

34 Àti nísisìyí kìyésĩ, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ̀yin mọ̀ pé a fi àwọn òfin wọ̀nyí fún bàbá wa, Léhì; nítorí-èyi, ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n láti àtẹ̀hìnwá; ẹ̀yin sì ti dé ibi ìdálẹ́bi tí ó ga; nítorítí ẹ̀yin ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí tí kò yẹ kí ẹ̀yin ṣe.

35 Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti ṣe àìṣedẽdé èyítí ó ga jù ti àwọn Lámánì, àwọn arákùnrin wa, lọ. Ẹ̀yin mú ìrètí àti ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ìyàwó yín oníwàpẹ̀lẹ́ kíó ṣákì, ẹ̀yin sì ti pàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ọmọ yín nínú nyín, nítorí àpẹrẹ ìwà búburú yín níwájú wọn; ẹkún wọn sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ ní ìdojúkọ nyín. Àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó múná, èyítí ó wá ní ìdojúkọ yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn ni ó kú nínú ipò ìrora ọgbẹ́ jíjìn.