Orí 3
Àwọn àgbàgbà yàn àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni nípa gbígbé ọwọ́ lé wọn lórí. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.
1 Báyĩ ni ọ̀nà ti àwọn ọmọ ẹ̀hìn, àwọn tí a npè ní àwọn àgbàgbà ìjọ, ṣe yàn àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni—
2 Lẹ́hìn tí wọ́n ti gbàdúrà sí Bàbá ní orukọ Krístì, wọ́n gbé ọwọ́ wọn lé wọn, wọ́n sì wípé:
3 Ní orukọ Jésù Krístì, mọ̀ yàn ọ́ láti jẹ́ àlùfã (tàbí bí ó bá jẹ́ olùkọ́ni, mọ̀ yàn ọ́ láti jẹ́ olùkọ́ni) láti wãsù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Krístì, nípa ìfaradà ìgbàgbọ́ nínú orukọ rẹ̀ títí dé òpin. Àmín.
4 Àti ní ọ̀nà yĩ ni wọ́n yàn àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ni, gẹ́gẹ́bí àwọn ẹ̀bùn àti àwọn ìpè tí Ọlọ́run pè ènìyàn; wọ́n sì yàn wọ́n nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí ó wà nínú wọn.