Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 5


Orí 5

Wọn ṣe àlàyé nípa ọ̀nà tí a fí nfí wáìnì àmì májẹ̀mú fún ni. Ní ìwọ̀n ọdún 401 sí 421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Báyĩ ni ọ̀nà tí a fi nfí wáìnì fún ni—Ẹ kíyèsĩ, wọ́n mú àgo, wọ́n sì wípé:

2 A! Olọ́run, Bàbá Ayérayé, àwa bẽrè lọ́wọ́ yín, ní orúkọ Ọmọ yín, Jésù Krístì, pé kí ẹ bùkún kí ẹ sì yà wáìnì yĩ sí mímọ́ fún ọkàn gbogbo àwọn tí ó mu nínú rẹ̀, láti lè ṣe é ní ìrántí ẹ̀jẹ̀ Ọmọ yín, èyítí a ta sílẹ̀ fún wọn; láti lè jẹ̃rí sí yín, A! Ọlọ́run, Bàbá Ayérayé, pé wọ́n nṣe ìrántí rẹ̀ nígbàgbogbo, kí wọn ó lè ní Ẹ̀mi rẹ̀ pẹ̀lú wọn. Àmín.

Tẹ̀