Àwọn Ìwé Mímọ́
Mórónì 7


Orí 7

A fún ni ní ìpè láti bọ́ sínú ìsimi Olúwa—Kí a má a gbàdúrà tọkàn-tọkàn—Ẹmí Krístì a máa jẹ́ kí ènìyàn ó mọ̀ rere yàtọ̀ sí búburú—Sátánì a máa tàn ènìyà láti sẹ́ Krístì àti làti ṣe búburú—Àwọn wòlĩ fi bíbọ̀ Krístì hàn—Nípa ìgbàgbọ́, iṣẹ́ ìyanu jẹ́ ṣíṣe àwọn Ángẹ́lì sì njíṣẹ́ ìránṣẹ́—Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ nírètí fún ìyè àìnípẹ̀kun kí wọn ó sì rọ̀ mọ́ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Ní ìwọ̀n ọdún 401–421 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí emí, Mórónì, kọ díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ bàbá mi Mọ́mọ́nì, èyítí ó sọ nípa ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́; nítorí ni ọ̀nà yĩ ni ó bá àwọn ènìyàn nã sọ̀rọ̀, bí ó ti nkọ́ wọn nínú sínágọ́gù èyítí wọ́n ti kọ́ fún ibi íjọ́sìn.

2 Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, sọ fún yín, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́; àti pé nípasẹ̀ õre-ọ̀fẹ́ Olọ́run tí i ṣe Bàbá, àti Olúwa wa Jésù Krístì, àti ìfẹ́-inú rẹ̀ mímọ́, nítorí ẹ̀bùn pípè rẹ̀ tí ó fi pè mí, ni a ṣe gbà fún mi láti bá yín sọ̀rọ̀ ní àkókò yĩ.

3 Nítorí èyí, èmi yíò bá ẹ̀yin tí í ṣe ti ìjọ sọ̀rọ̀, tí í ṣe oníwàpẹ̀lẹ́ ènìyàn tí ntẹ̀lé Krístì, àti tí ó ti gbà ìrètì ti o to, nipa èyítí ẹyin yíò fi lè bọ́ sínú ìsimi Olúwa, láti ìgbà yí lọ títí dé ìgbà tí ẹ̀yin yíò simi pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run.

4 Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, mo ṣe ìdájọ́ fún yin nípa àwọn ohun wọ̀nyí nítorí ìwàpẹ̀lẹ́ ti ẹ̀yín fi nbá àwọn ọmọ ènìyàn lò.

5 Nitori èmi rànti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó sọ wípé nípa iṣẹ́ wọn ní ẹ̀yin ó mọ̀ wọ́n; nítorítí bí iṣẹ wọn bá jẹ́ rere, nígbànã ni àwọn nã yíò jẹ́ rere pẹ̀lú.

6 Nítorí ẹ kíyèsĩ, Ọlọ́run ti sọ wípé ẹnití ó bá jẹ́ búburú kò lè ṣe èyítí ó jẹ rere; nítorí bí ó bá fún ní ní ẹ̀bún kan, tàbí kí ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, afi bí ó bá ṣe é tọkàn-tọkàn kò jẹ èrè kan fúnun.

7 Nítorí ẹ kíyèsĩ, à kò kã sí òdodo fún un.

8 Nítorí ẹ kíyèsĩ, bí ènìyàn tí ó jẹ́ búburú bá fún ni ní ẹ̀bùn kan, a máa ṣeé pẹ̀lú ìkùnsínu; nítorí èyí a kà á fún un ní ọ̀nà kannã bí èyítí ó fi ọwọ́ mú ẹ̀bùn nã; nítorí èyí a kã sí ènìyàn búburú níwájú Ọlọ́run.

9 Bákannã pẹ̀lú ni a kã sí búburú fún ènìyàn, bí ó bá gbàdúrà ṣùgbọ́n tí kò ṣe e tọkàn-tọkàn; bẹ̃ni, kò sì jẹ èrè kankan fún ún, nítorítí Ọlọ́run kò gbà irú ènìyàn bẹ̃.

10 Nítorí èyí, ẹnití ó bá jẹ́ búburú kò lè ṣe èyítí í ṣe rere; bẹ̃ni kò lè fúnni ní ẹ̀bùn rere.

11 Nítorí kíyèsĩ, orisun omi kíkorò kò lè sun omi dáradára jáde, bẹ̃ ni orísun omi dáradára kò lè sun omi kikorò jáde; nítorí èyí, ẹnití i bá í ṣe ìránṣẹ́ èṣù kò lè tẹ̀lé Krístì; bí ó bá sì tẹ̀lé Krístì kò lè jẹ́ iránṣẹ́ èṣù.

12 Nítorí èyí, ohun gbogbo tí ó dára wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run; èyítí ó sì jẹ́ búburú wá láti ọ̀dọ̀ èṣù; nítorítí èṣù jẹ ọ̀tá Ọlọ́run, a sì mã bá a jà títí, a sì mã pè, àti fà láti ṣẹ̀ àti láti ṣe èyítí ó burú títí.

13 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, èyítí íṣe ti Ọlọ́run a mã pè, àti fà láti ṣe rere títí; nítorí èyí, ohun gbogbo tí ó bá npè, tí ó sì nfà láti ṣe rere, àti láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run, àti láti sìn ín, ni ìmísí Ọlọ́run.

14 Nítorí èyí, ẹ kíyèsára, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, kí ẹ̀yin ó máṣe dájọ́ pé èyítí ó burú jẹ́ ti Ọlọ́run, tabi pé èyítí ó dára tí í sì í ṣe tí Ọlọ́run jẹ́ ti èṣù.

15 Nitorí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yín arákùnrin mi, a ti fún yín láti dájọ́, kí ẹ̀yin ó lè mọ́ rere yàtọ̀ sí búburú; ọ̀nà ṣíṣe ìdájọ́ sì jẹ́ èyítí ó ṣe kedere, kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pípé, gẹ́gẹ́bí ìmọ́lè ojúmọmọ ti yàtọ̀ sí òkùnkùn àṣálẹ́.

16 Nítorí ẹ kíyèsĩ, a fún olukúlùkù ènìyàn ní Ẹ̀mí Krístì kí ó lè mọ̀ rere yàtọ̀ sí búburú; nítorí èyí, èmi yíò fihàn yin bí a ti í ṣè idájọ́; nítorítí ohun gbogbo tí í bá npè ènìyàn láti ṣe rére, àti láti yí ènìyàn lọ́kàn padà láti gbà Krístì gbọ́ ni a rán jáde nípa agbára àti ẹ̀bùn Krístì; nítorínã ẹ̀yin lè mọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pípé pé ti Ọlọ́run ni íṣe.

17 Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá yí ènìyàn lọ́kàn padà láti ṣe búburú, àti kí ó má gbà Krístì gbọ, kí ó sì sẹ́ ẹ, kí ó má sì sìn Olọ́run, nígbànã ni ẹ̀yin yíò mọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ pípé pé ti èṣù ní í ṣe; nìtoriti ní ọ̀nà yĩ ni èsù ngbà ṣiṣẹ́, nítorítí kò lè yí ẹnikẹ́ni lọ́kàn padà láti ṣe rere, rárá, àní ẹnikẹ́ni; tàbí àwọn ángẹ́lì rẹ̀; tàbí àwọn tí wọ́n fi ara wọn sí ábẹ́ rẹ̀.

18 Àti nísisìyí, ẹyin arákùnrin mi, bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ ìmọ́lẹ̀ nípa èyítí ẹ̀yin ó ṣe ìdájọ́, ìmọ́lẹ̀ èyítí í ṣe ìmọ́lẹ̀ Krístì, kí ẹ ríi pé ẹ̀yin kò ṣe ìdájọ́ ní ọ̀nà tí kò tọ́; nitori irú ìdájọ́ tí ẹ̀yin bá ṣe ní a ó sì ṣe fún yín pẹ̀lú.

19 Nítorí èyí, mo bẹ̀ yin, ẹ̀yin arákùnrin, pé kí ẹ̀yin ó wákiri tọkàntara nínú ìmọ́lẹ̀ Krístì kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ rere yàtọ̀ sí búburú; bí ẹ̀yin ó bá sì dì ohun gbogbo tí í ṣe rere mú, kí ẹ ma sì dáa lẹ́bi, dajúdajú ẹ̀yin yíò jẹ́ ọmọ Krístì.

20 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, báwo ni ó ha ṣeéṣe fún yín láti lè dì ohun gbogbo tí í se rere mu?

21 Àti nísisìyí èmi dé ibi ìgbàgbọ́ nnì, nípa èyítí mo sọ wípé èmi yíò sọ̀rọ̀; èmi yíò sì sọ fún yín níti ọ̀nà tí ẹ̀yin yíò gbà dì ohun gbogbo tí í ṣe rere mú.

22 Nítorí ẹ kíyèsĩ, Olọ́run mọ̀ ohun gbogbo, nítorípé ó wà láti ayérayé dé ayérayé, kíyèsĩ, ó rán àwọn àngẹ́lì láti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ọmọ ènìyàn, láti mú kí bíbọ̀ Krístì di mímọ̀; àti pe nínú Krístì ní ohun rere gbogbo yíò dé.

23 Ọlọ́run pẹ̀lú wí fún àwọn wòlĩ, láti ẹnu rẹ̀, pé Krístì yíò dé.

24 Ẹ sì kíyèsĩ, onírúurú ọ̀nà ni ó fi fi àwọn ohun hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn, àwọn èyítí ó dara; gbogbo àwọn ohun tí ó sì dara ni o wá láti ọ̀dọ̀ Krístì; bíkòjẹ́bẹ̃ àwọn ènìyàn wà ní ìṣubú, kò sì sí ohun rere tí ó lè wá bá wọn.

25 Nítorí èyí, nípà iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí àwọn ángẹ́lì nṣe, àti nipa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Ọlọ́run jáde wa, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀sí fí ìgbàgbọ́ bá Krístì lò; àti nípa ìgbàgbọ́, wọn sì di ohun gbogbo tí í ṣe rere mú; báyĩ ní ó sì rí títí dì àkókò tí Krístì dé.

26 Àti lẹ́hìn tí ó dé a gbà àwọn ènìyàn là pẹ̀lú nípa ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; àti nípa ìgbàgbọ́, wọ́n di ọmọ Ọlọ́run. Bí o si ti daju pe Krístì wà lãyè ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn baba wa, wípé: Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orukọ mi, èyítí ó jẹ́ rere, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí ẹ sì gbàgbọ́ pe ẹ̀yin yio rí gbà, ẹ kíyèsĩ, á ó fifún yin.

27 Nítorí èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ àwọn isẹ́ ìyanu ha dópin nítorípé Krístì tí gòkè lọ sí ọ́run, àti tí ó sì ti jóko ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, láti gbà ẹ̀tọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ Bàbá èyítí ó ní nípa síṣe ãnú fún àwọn ọmọ ènìyan?

28 Nítorítí ó ti ṣe ìdáhùn sí àwọn ohun tí ofin bẽrè fún, ó sì ti gbà gbogbo àwọn ti ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀; àwọn tí ó sì gbàgbọ́ nínú rẹ̀ yíò rọ̀ mọ́ ohun rere gbogbo; nítorí èyí a mã ṣe alágbàwí fún èyítí í ṣe tí àwọn ọmọ ènìyàn; ó sì ngbé nínú àwọn ọ̀run títí ayérayé.

29 Àti nítoripé ó tí ṣe èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, njẹ́ iṣẹ́ ìyanu ha ti dópin bi? Ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, Rárá; bẹ̃ni àwọn ángẹ́lì kò dáwọ́dúró nínú iṣẹ ìránṣẹ́ ṣíṣe fún àwọn ọmọ ènìyan.

30 Nítorí ẹ kíyèsĩ, abẹ́ rẹ̀ ní wọ́n wà, láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ó ti pàṣẹ, àti láti fi ara wọn hàn sí àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ púpọ̀ àti ọ̀kan ti ó dúróṣinṣin nínú ìwà-bí-Ọlọ́run.

31 Ipò iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn sì wà láti pè àwọn ènìyan sí ìrònúpìwàdà, àti láti mú àwọn májẹ̀mú ṣẹ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ nípa ti àwọn májẹ̀mú Bàbá, èyítí ó ti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn, láti pèsè ọ̀nà nã lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, nípa sísọ ọ̀rọ̀ Krístì fún àwọn ohun èlò tí Olúwa yàn, láti lè jẹ̃rí nípa rẹ̀.

32 Àti nípa ṣíṣe eleyĩ, Olúwa Ọlọ́run pèsè ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn yókù láti lè ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, kí Ẹ̀mí Mímọ́ ó lè rí ãye nínú ọkan wọn, gẹ́gẹ́bí agbára rẹ̀; ní ọna yĩ sì ni Baba mú wọn ṣẹ, àwọn májẹ̀mú èyítí ó tí ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn.

33 Krístì sì ti wípé: Bí ẹ̀yin ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi ẹ̀yin yíò ní agbára láti ṣe ohunkóhun tí ó tọ́ nínú mi.

34 Ó sì ti wípé: Ẹ ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀yin ìkangun ayé, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí a sì rì yín bọmi ní orúkọ mi, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú mi, kí a bã lè gbà yín là.

35 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, bí ó bá rí bẹ̃ pé òtítọ́ ni àwọn ohun wọ̀nyí èyítí mo ti wí fún yín, Ọlọ́run yíò sì fi hàn sí yin, pẹ̀lú agbára àti ògo nlá ní ọjọ́ ìkẹhìn, pé òtítọ́ ni wọ́n í ṣe, bí wọn bá sì jẹ́ òtítọ́ njẹ́ ọjọ́ àwọn iṣẹ́ ìyanu ha ti dópin bí?

36 Àbí àwọn ángẹ́lì ha ti síwọ́ láti fi ara han sí àwọn ọmọ ènìyàn bí? Àbí ó ha ti ká agbára Ẹ̀mí Mímọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn bí? Àbí yíò ha ṣe èyí bí, níwọ̀n ìgbà tí àkókò yíò wà, tàbí tí yíò kù ẹnìkanṣoṣo lórí rẹ̀ tí a ó gbàlà?

37 Ẹ kíyèsĩ mó wí fún yín, Rárá; nítorítí nípa ìgbàgbọ́ ní àwọn iṣẹ́ ìyanu a máa ṣẹ̀; àti nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn ángẹ́lì a máa fì ara hàn àti tí wọn a máa jiṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn; nítorí èyí, bí àwọn ohun wọ̀nyí bá ti dáwọ́dúró ègbé ní fún àwọn ọmọ ènìyàn nítorítí èyí nnì rí bẹ̃ nítorí àìgbàgbọ́, gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ asán.

38 Nítorítí a kò lè gbà ẹnikẹ́ni là, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Krístì, àfí bí wọ́n bá ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorí èyí, bí àwọn ohun wọ̀nyí bá ti dáwọ́dúró, nígbànã ní ìgbàgbọ́ ti dáwọ́dúró pẹ̀lú; ìpò búburú sì ni ènìyàn wà, nítorítí wọ́n wà bí èyítí a kò ṣe ìràpadà fún wọn.

39 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin arákùnrin mí àyànfẹ́, mo ṣe ìdájọ́ nípa èyítí ó dára jù fún yín, nítorítí èmi ṣe ìdájọ́ pé ẹ̀yin ní ìgbàgbọ́ nínú Krístì nitori ìwà tútù yín; nítorítí bí ẹ̀yin kò bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nígbànã ní kò tọ́ kí a kà yín mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ rẹ̀.

40 Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, emí yíò bá yín sọ̀rọ̀ nípa ìrètí. Báwo ní ẹ̀yin ṣe lè ri ìgbàgbọ́ gbà, bíkòṣepé ẹ̀yin ní ìrètí?

41 Kí sì ni ẹ̀yin yíò ní ìrètí fún? Ẹ́ kíyèsĩ mo wí fún yín pe ẹ̀yin yio ní ìrètí nípasẹ̀ ètùtù Krístì àti agbára àjínde rẹ̀, kí a gbé yín dìde sí ìyè tí kò nípẹ̀kun, èyítí ó sì rí bẹ̃ nítorí ìgbàgbọ́ yín nínú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀.

42 Nítorí èyí, kí ẹnikẹ́ni ó lè ní ìgbàgbọ́ ó níláti ní ìrètí; nítorí láìsí ìgbàgbọ́ kò lè sí ìrètí rárá.

43 Àti pẹ̀lú, ẹ̀ kíyèsĩ mo wí fún yín pé òun kì yíò ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí, àfi bí ó bá jẹ́ oníwàtútù ènìyàn, àti onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ènìyàn.

44 Bí ó bá rí bẹ̃, asán ni ìgbàgbọ́ àti ìrètí rẹ̀, nítorítí ẹnikẹ́ni kò jẹ́ ìtẹ́wógbà níwájú Ọlọ́run àfi oníwà tútù àti onírẹ̀lẹ́-ọkàn ènìyàn; bí ẹnikẹ́ni bá sì jẹ́ oníwàtútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, tí ó sì jẹ́wọ́ nípa agbara Ẹ̀mí Mímọ́ pé Jésù ni Krístì nã, ó nílàti ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́; nítorítí bí kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ asán ní í ṣe; nítorí èyí ó níláti ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́.

45 Ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ a máa mú sũrù, a sì máa ṣeun, kì í sì íṣe ìlara, kì í sì í fẹ̀, kì íwá ohun tí ara rẹ̀, a kĩ múu bínú, kĩ gbèrò ohun búburú, kì í sì í yọ̀ nínú àìṣedẽdé, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ nínú òtítọ́, a máa faradà ohun gbogbo, a máa gbà ohun gbogbo gbọ́, a máa reti ohun gbogbo, a sì máa fọkàn rán ohun gbogbo.

46 Nítorí èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, bí ẹ̀yin kò bá ní ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, òfo ni ẹ̀yin íṣe, nítorítí ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kì í yẹ̀. Nítorí èyí, ẹ rọ̀mọ́ ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, èyítí ó tóbi jù ohun gbogbo, nítorítí ohun gbogbo gbodọ̀ kùnà—

47 Ṣùgbọ́n ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ní ìfẹ́ Krístì tí kò ní àbàwọ́n, ó sì wà títí láe; ẹnikẹ́ni tí a bá sì rí ti ó ní i ní ọjọ́ ìkẹhìn, yíò dára fún un.

48 Nítorí èyí, ẹ̀yin arákùnrin mi àyànfẹ́, ẹ gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo agbára tí ó wà nínú yín, pé kí ìfẹ́ yì í ó kún inú yín, èyítí ó ti fi jínkí gbogbo àwọn tí wọn jẹ́ olùtẹ̀lé Ọmọ rẹ̀, Jésù Krístì; kí ẹ̀yin ó lè dì ọmọ Ọlọ́run; pé nígbàtí o bá fi ara hàn, a ó dàbí rẹ̀, nítorí àwa yio ríi àní bí ó ti ri; kí àwa ó lè ní ìrètí; kí Ọlọ́run ó lè sọ wá di mímọ́ àní bí òun ti mọ́. Àmín.