Ọ̀dọ́
Ṣíṣe Alábápín Pẹ̀lú Ọ̀rẹ́ Kan
Ní ọjọ́ kan nígbàtí mòó nṣe àṣàrò fún kílásì seminary mi, mo ní ìmísí ẹléwà àti yíyàtọ̀ kan. Bí mo tí nka ẹ̀kọ́ fún ọjọ́ òla, mo rí ojú ọ̀rẹ́ mi kan láti ilé ìwé mo sì ní ìmọ̀ inú alágbára pé kíi ṣe alábápín ẹ̀rí mi pẹ̀lú rẹ̀.
Bíótilẹ̀ jẹ́ wípé ìmísí yìí rí kedere, ẹ̀rù bà mí. Mo ní àìníyàn pé ọ̀rẹ́ mi lè kọ̀ mí, pàápàá nítorí kò jọ ìrú ọmọbìnrin tí yíó ní ìfẹ́ sí dídarapọ̀ mọ́ Ìjọ.
Mo ronú padà sí ọ̀rọ̀ kan nípasẹ Arábìnrin Mary N. Cook ti Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò tí Ọ̀dọ́mọbìnrin nínú èyí tí ó pè wá níjà láti ṣíṣẹ líle àti sì jẹ́ akíkanjú.1 Mo fẹ́ láti jẹ́ bí èyí, nitorí náà mo kọ ìwé sí ọmọbìnrin yìí mo sì jẹ́rí sí òtítọ́ ti Ìjọ àti ti ìfẹ́ mi fún Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní ọjọ́ kẹjì mo fi ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan, pẹ̀lú ìwé mi, sínú àpò rẹ̀.
Sí ìyàlẹ́nu mi, ọ̀rẹ́ mi gbà ìhìnrere sínú gan. Bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ yẹn, yíó sọ fún mi ohun tí ó ti kọ́ nínú ṣíṣe àṣàrò rẹ̀ ti Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ní ọ̀sẹ̀ méló kan lẹ́hìn yẹn, mo ṣe àfihàn rẹ̀ sí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere. Àni bíi lọ́gán, ó gba ìdánilójú láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ pé ohun tí òun nkọ́ jẹ́ òtítọ́. Àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere àti èmí ké nígbatí ó sọ àwọn ìmọ̀ inú rẹ̀ fún wa. Ọ̀rẹ́ mi láìpẹ́ ṣe ìrìbọmi, àti àwọn òbí rẹ̀ ní ìyàlẹ́nu láti rí àwọn àyipadà tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ayé rẹ̀.
Inú mi dùn wípé mo lè borí àwọn ìjayà mi àti sì ṣe ìrànlọ́wọ́ láti mú ìhìnrere wá sínú ayé rẹ̀.