Iṣẹ́ Abẹniwò Kíkọ́ni, Oṣù 2013
Yíyípadà sí Olúwa
Fi àdúrà ṣàṣàrò lórí ohun yìí àti, bí ó bá bójú mu, ṣe àjọsọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arábìnrin tí ò ó mbẹ̀ wò. Lo àwọn ìbéèrè náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìfúnlókun àwọn arábìnrin rẹ àti láti mú Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ jẹ́ ipá tí ó láapọn nínú ayé rẹ. Fún ìmọ̀ síi, lọ sí reliefsociety.lds.org.
Àwọn arábìnrin titun ti Ìjọ — pẹ̀lú àwọn Ọ̀dọ́mọbìnrin tí wọ́n nwọ Ẹ̀gbẹ́ Aranilọ́wọ́, àwọn arábìnrin tí wọ́n npadà sí ìṣe, àti àwọn titun tí a jèrè ọkàn wọn — nílò ìdúrótì àti ìbáṣọ̀rẹ́ àwọn olùkọ́ni abẹniwò. “Ìbáṣepọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ jẹ́ kókó sí mímú dúró àwọn tí a jèrè ọkàn wọn àti ní mímú àwọn ọmọ ẹgbẹ tí wọ́n nṣòjòjò padà sí ìṣe kíkún,” ni Alàgbà M. Russell Ballard ti Àpéjọpọ̀ Àwọn Àpóstélì Méjìlá wí. “Di ìran náà mú wípé Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ … lè di [ọ̀kan nínú] àwọn èlò ìbániṣọ̀rẹ́ tí ó lágbára jùlọ tí a ní nínú Ìjọ. Tètè nawọ́ sí àwọn tí àá nkọ́ àti múpadà sí ṣíṣe, sì fẹ́ràn wọn sínú Ìjọ nípasẹ ẹgbẹ́ rẹ.”1
Gẹ́gẹ́bíi ọmọ ẹgbẹ́ Ẹ̀gbẹ́ Aranilọ́wọ́, a lè ran àwọn ọmọ ẹgbẹ́ titun lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ ìṣe Ìjọ, bíi:
-
Sí sọ̀rọ̀.
-
Ṣíṣe ìjẹ́rí.
-
Gbígbé ayé òfin ti àwẹ̀.
-
Sísan ìdámẹ́wá àti àwọn ọrẹ.
-
Kíkópá nínú iṣẹ́ ìtàn ìdílé.
-
Síṣe àwọn ìrìbọmi àti àwọn ìmú ẹsẹ̀ dúró fún àwọn ìran wa tí wọ́n ti kú.
“A nílò àwọn ọ̀rẹ́ tí ó fetísílẹ̀ láti mú àwọn ọmọ Ìjọ titun ní ìfarabalẹ̀ àti ìkíni káàbọ̀ ní Ìjọ,” ni Alàgbà Ballard sọ.2 Gbogbo wa, ṣùgbọ́n pàápàá jùlọ àwọn olùkọ́ni abẹniwò, ní ojúṣe pàtàkì láti ṣe àmúwá ìbáṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìjọ titun gẹ́gẹ́bíi ọ̀nà kan láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà ní ìdúróṣinṣin ní “yíyipada sí ọ̀dọ̀ Olúwa” (Álmà 23:6).
Láti Àwọn ìwé Mímọ́
Láti Inú Ìtàn Wa
“Pẹ̀lú oye àwọn tí a jèrè ọkàn wọn tí ó ṣáà npọ̀si,” Ààrẹ Gordon B. Hinckley (1910–2008) wípé, “a gbọ́dọ̀ túnbọ̀ sa ipá tí ó jọjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà wọn. Olúkúlùkù wọn nílò àwọn ohun mẹ́ta: ọ̀rẹ́ kan, ojúṣe kan, àti títọ́jú pẹ̀lú ‘ọ̀rọ̀ dídára ti Ọlọ́run’ (Mórónì 6:4).”3
Àwọn olùkọ́ni abẹniwò wà ní ipò láti ṣè rànlọ́wọ́ fún àwọn tí wọ́n nṣọ́nà fún. Ìbáṣọ̀rẹ́ ní ó maá kọ́kọ́ wá, bí ó ti ṣe fún ọ̀dọ́bìnrin Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ kan tí ó jẹ́ olùkọ́ni abẹniwò fún àgbàlagbà arábìnrin kan. Wọ́n ti lọ́ra láti ṣe ìbáṣọ̀rẹ́ di ìgbà tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ́ ara wọn lórí iṣẹ́ ìmọ́tótó kan. Wọ́n di ọ̀rẹ́, àti bí wọ́n tí ṣe sọ̀rọ̀ nípa Ìṣẹ́ Olùkọ́ni Abẹniwò, àwọn méjìjì jọ gba okun nípa “ọ̀rọ̀ dídára ti Ọlọ́run.”
Ààrẹ Joseph Fielding Smith (1876–1972) wípé Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ “jẹ́ ipa kókó lára ìjọba Ọlọ́run ní aye ó sì … nran àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ olóótọ́ láti jèrè iyè ayérayé nínú ìjọba Bàbá wa.”4
© Ọdún 2013 by Intellectual Reserve, Inc. Gbogbo ẹ̀tọ́ ni a fi pamọ́. Tí a tẹ̀ ní USA. Àṣẹ Gẹ̀ẹ́sì: 6/12. Àṣẹ Àyípadà èdè: 6/12. Àyípadà èdè ti Visiting Teaching Message, February 2013. Yoruba. 10662 779