2013
Ọ̀rọ̀ Kan fún Aṣiyèméjì Òjíṣẹ́ Ìhìnrere
February 2013


Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kejì Ọdún 2013

Ọ̀rọ̀ Kan fún Aṣiyèméjì Òjíṣẹ́ Ìhìnrere

Ààrẹ Dieter F. Uchtdorf

Àwọn ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì ti má nwà nígbàgbogbo lábẹ́ ojúṣe láti mú ìhìnrere Rẹ̀ lọ sí àgbáyé (rí Marku 16:15–16). Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, nígbà kànkan ó maá nṣòro láti la ẹnu wa àti kí a sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wa sí àwọn tí ó wà ní àyíká wa. Nígbàtí àwọn ọmọ Ìjọ kan bá ní ẹ̀bùn abínibí fún bíbá ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn, àwọn míràn ní iyèméjì díẹ̀ tàbí ní àìrọrùn, dàmú, tàbí pàápàá níbẹ̀rù nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀.

Sí òpin yìí, jẹ́ ki ndámọ̀ràn ohun mẹ́rin kan tí ẹnikẹ́ni lè ṣe láti tẹ̀lé ìfifúnni ti Olùgbàlà láti wàásù ìhìnrere náà “sí gbogbo ẹ̀dá alààyè” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 58:64).

Jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Kan

Ọ̀rọ̀ sísọ mi kan tí mo fẹ́ràn tí a má nkà sí St. Francis ti Assisi ígbà púpọ̀ kà báyí, “Wàásù ìhìnrere náà ní ìgbà gbogbo àti tí ó bá nílò, lo àwọn ọ̀rọ̀.”1 Dájú nípa sísọ yìí ní òye wípé nígbà púpọ̀ àwọn ìwàásù tí ó lágbára jùlọ kìí ṣe sísọ.

Nígbà tí a bá ní ìwà títọ́ àti ìgbé ayé àìyẹsẹ̀ nípa àwọn ìdìwọ̀n wa, àwọn ènìyàn nṣàkíyèsi. Nígbàtí a bá ntan ayọ̀ àti ìdùnnú, wọn yíó túnbọ̀ ṣàkíyèsí síi.

Gbogbo ẹ̀nìyàn fẹ́ láti ní ìdùnnú. Nígbàtí àwa ọmọ Ìjọ bá tan ìmọ́lẹ̀ ti ìhìnrere, àwọn ènìyàn yíó rí ìdùnnú wa wọn yíò sì fura sí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó nkún àti tí ó nkún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ayé wa. Wọ́n á fẹ́ mọ ìdí rẹ̀. Wọ́n á fẹ́ ní òye nípa àṣírí wa.

Ẹléyí yíó darí wọn sí bíbi àwọn ìbéèrè bíi ti “Kílóde tí inú rẹ ṣe dùn báyí?” tàbí “Kílóde tí o má nní ìṣesí tí ó dájú tó bẹ́ẹ̀ nígbà gbogbo?” Àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, dájúdájú, ndárí ní pípé sí àjọsọ nípa ìhìnrere ti Jésù Krístì tí a mú padà.

Jẹ́ Alájọsọ

Mímú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wá — pàápàá sí àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn àyànfẹ́ wa — lè rí bí ohun ìdàláàmú àti ìpeniníjà. Kò ní láti jẹ́ bẹ́ẹ̀. Mí mẹ́nu ba àwọn ìrírí ẹ̀mí tàbí sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ojú ṣe tàbí ṣíṣe Ìjọ nínú àjọsọpọ̀ àìronú tẹ́lẹ̀ lè jẹ́ àìṣòro àti dídùn tí a bá ṣe àfikún ìgboyà díẹ̀ àti ọgbọ́n orí.

Ìyàwó mi, Harriet, jẹ́ àpẹrẹ ìyanu kan ti èyí. Nígbàtí àá ngbé ní Germany, òhun yíó wá àyè láti fí àwọn àkọlé tí ó tan mọ́ Ìjọ sínú àwọn àjọsọpọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òrẹ́ àti àwọn ojúlùmọ̀. Fún àpẹrẹ, nígbàtí ẹnìkan bá bií nípa ìparí ọ̀sẹ̀ rẹ̀, òhun yíó wípé, “Ní ọjọ́ Ìsimi yìí a ní ìrírí ìkan-ni-lára kan nínú ìjọ wa! Ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọdún mẹ́rìndínlógún kan sọ ọ̀rọ̀ ẹlẹ́wà kan níwájú igba ènìyàn nínú àpèjọ wa nípa gbígbé ìgbé ayé mímọ́.” Tàbí, “Mo kọ́ nípa ògbó arábìnrin ọmọdún bíi àádọ́rún kan tí ó hun ju ọgọ́rún márún ìbora tí ó sì fún ètò ìkáánú fún ènìyàn ti Ìjọ wa láti fi ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí ó ṣe àìní káàkiri gbogbo àgbáyé.”

Nígbà púpọ̀ ju bẹ́ẹ̀kọ́, àwọn ènìyàn tí ó gbọ́ èyí fẹ́ mọ̀ ju bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n bi àwọn ìbéèrè. Àti èyí sí tọ́ni sí àwọn ànfàní láti sọ̀rọ̀ nípa ìhìnrere ní ọ̀nà adánidá, dídájú, aláìní títì.

Pẹ̀lú wíwá Ayélujára àti ẹ̀rọ èlò ti ẹgbẹ́, ó rọrùn láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nkan wọ̀nyí ní ọ̀nà àjọsọ̀rọ̀ ju ti tílẹ̀ lọ. Ohun tí a nílò nìkan ni ìgboyà láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Kún fún Ore-Ọ̀fẹ́

Láìlóríre, ó rọrùn láti jẹ́ àìbáradé. Ó nṣẹlẹ̀ nígbà púpọ̀ nígbà tí a bá jiyàn, kà sí bíntí, àti ṣe ìdálẹ́bi. Nígbàtí a bá di oníbínú, arínifín, tàbí apanilára pẹ̀lú àwọn ènìyàn, ohun tó kẹ́hìn tí wọ́n fẹ́ ni láti ní ẹ̀kọ́ si nípa wa. Ó ṣòro láti mọ ye ẹnití wọ́n yálà fi Ìjọ sílẹ̀ tàbí láí kò darapọ̀ láí mọ́ Ìjọ nítorí ẹnìkan sọ nkan tí ó pa wọ́n lára tàbí ṣẹ̀ wọ́n.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìmọyì wà nínú ayé lóní. Nítorí àìdánimọ̀ ti Ayélujára, ó rọrùn ju ìgbà láí lọ láti sọ àwọn ohun olóró tàbí àìbójúmu ní orí ìlà. Njẹ́ àwa, ọmọ ẹ̀hìn onírètí ti onírẹ̀lẹ̀ Krístì wa, kò yẹ kí a ní ìdìwọ̀n gíga, onífẹ́ àìlẹ́gbẹ́ jùlọ? Àwọn ìwé mímọ́ kọ́, “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ nyín kí ó dàpọ̀ mọ́ ore-ọ̀fẹ́ nígbàgbogbo, èyítí a fí iyọ̀ dùn, kí ẹ̀nyin lí ó lè mọ̀ bí ẹ̀nyin ó ti máa dá Olúkúlùkù ènìyàn lóhùn” (Kolosse 4:6).

Mo fẹ́ràn iyè inú ti àwọn ọ̀rọ̀ wa ń mọ́ bí ojú ọ̀run oòrùn àti kún fún ore-ọ̀fẹ́. Njẹ́ o lè gbèrò ohun tí àwọn ìdílé, àwọn ẹ̀ka nlá, àwọn orílẹ̀ èdè, àti pàápàá àgbáyé yíó ti rí tí a bá lè gbá ìpinlẹ̀ṣẹ̀ onírọrùn yí?

Kún fún Ìgbàgbọ́

Nígbà míràn a má nfún ara wa ní ọ̀pọ̀ àre tàbí ìdálẹ́bi nígbàtí ó bá kan àwọn ẹlòmíràn ńgba ìhìnrere. Ó ṣe pàtàkì láti rántí pé Olúwa kò nírètí sí wa láti ṣe ìyípadà náà.

Ìyípadà kìí wá nípa àwọn ọ̀rọ̀ wa bíkòṣe nípa àwọn ìmísí ọ̀run ti Ẹ̀mí Mímọ́. Nígbà míràn ohun tí ó gbá ni gbólóhùn kan nípa ẹ̀rí wa tàbí ìrírí kan láti ṣe ìbẹ̀rẹ̀ mímú ọkàn kan rọ̀ tàbí ṣíṣí ilẹ̀kùn kan tí ó lè tọ́ àwọn ẹlòmíràn láti ní ìrírí àwọn òtítọ́ gíga nípasẹ àwọn ìtọ́ni ti Ẹ̀mí.

Ààrẹ President Brigham Young (ọdún 1801–77) wípé òun mọ̀ pé ìhìnrere jẹ́ òtítọ́ nígbá tí òun “rí ọkùnrin kan tí kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, tàbí ní ẹ̀bùn fún sísọ̀rọ̀ ní ìta, tí ó kàn lè sọ wípé, ‘Mo mọ̀, nípa agbára ti Ẹ̀mí Mímọ́, wípé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́, wípé Joseph Smith ní Wòlíì ti Olúwa kan.’” Ààrẹ Young wípé nígbàtí òun gbọ́ ẹ̀rí ìrẹ̀lẹ̀ yẹn, “Ẹ̀mí Mímọ́ tí ón tọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni yẹn tan ìmọ́lẹ̀ sí òye mi, àti ìmọ́lẹ̀, ògo, àti àìkú wà níwájú mi.”2

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ ní ìgbàgbọ́. Olúwa lè ṣe àmútóbi àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹ sọ àti mú wọn lágbára. Ọlọ́run kò ní kí ẹ ṣe àyípadà bíkòṣe kí ẹ la àwọn ẹ̀nu yín. Ìṣẹ́ yíyípadà kìí ṣe ti yín — ìyẹn jẹ́ ti ẹnití ó ngbọ́ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Gbogbo Ọmọ Ẹgbẹ́ ni Òjíṣẹ́ Ìhìnrere

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, lóní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ló wà jú ìgbà láí lọ fún wa láti la àwọn ẹnu wa àti láti ṣalábápín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ìròhìn ayọ̀ ti ìhìnrere ti Jésù Krístì. Ọ̀nà kan wà fún gbogbo ènìyàn — pàápàá fún aṣiyèméjì òjíṣẹ́ ìhìnrere — láti kópa nínú iṣẹ́ nlá yí. Olúkúlùkù wa lè wá ọ̀nà kan láti lo àwọn ẹ̀bùn àti ohun ànífẹ́sì wa gan ní ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fún iṣẹ́ nla ti kíkún àgbáye pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ yìí. Bí a tí nṣe bẹ́ẹ̀, a ó rí ayọ̀ tí ó nwá sí àwọn tí ó jẹ́ olóótọ́ àti onígboyà tó “láti dúró gẹ́gẹ́bí àwọn ẹlẹ́rí Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà” (Mòsíàh 18:9).

Àwọn Àkọsílẹ̀ Ránpẹ́

  1. Ẹ̀nìyàn Mímó Francis ti Assisi, ní William Fay and Linda Evans Shepherd, Ṣe Alábápín Jésù Láì Bẹ̀rù (1999), 22.

  2. Ìdánilẹ́kọ́ ti Àwọn Olùdarí Àgbà ti Ìjọ: Brigham Young (1997), 67.

Ìdánilẹ́kọ́ láti Inú Iṣẹ́ Yìí

Ọ̀nà ìyọrísí kan láti kọ́ni ni láti “gba àwọn tí ò ó nkọ́ níyànjú láti yan … àwọn ìpinnu tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àmúṣẹ ìpinlẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọ́” (Kíkọ́ni, Kò sí Ìpè tí ó Ju Èyí Lọ [1999], 159). Ronú sí pípe àwọn tí ò ó nkọ́ láti fi àdúrà yan ìpinnu láti ṣe alábápín ìhìnrere pẹ̀lú ẹnìkan tàbí ju bẹ́ẹ̀ lọ nínu oṣù yí. Àwọn òbí lé ṣe àjọsọ àwọn ọ̀nà tí àwọn ọmọdé kékeré lẹ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́. O tún lè ran àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìdílé lọ́wọ́ láti ṣe ìforíkorí tàbí ṣe ìfara ẹni sípò àwọn ọ̀nà tí a lè dá ọ̀rọ̀ ìhìnrere sílẹ̀ nínú àjọsọ déedée àti kí wọ́n ronú nípa àwọn ìṣe Ìjọ́ tí ó mbọ̀ tí wọ́n lè pe ọ̀rẹ́ wọn kan sí.