2013
Èmi Kò Ní Já Ọ kulẹ̀, tàbí Kọ̀ Ọ́ Sílẹ̀
November 2013


Iṣẹ́ Àjọ Olùdarí Gbogbogbòò, Oṣù Kọkànlá Ọdún 2013

Èmi Kò Ní Já Ọ kulẹ̀, tàbí Kọ̀ Ọ́ Sílẹ̀

Bàbá wa ọ̀run … mọ̀ pé à ńkẹ́kọ́, à ńdàgbà, à sì ńdi alágbára si bí a ṣe ń ní ìdojúkọ tí a sì ńyọ nínú awọn àdánwò nínú èyí tí a gbọ́dọ̀ gbà kọjá.

Nínú ìwé àkọpamọ́ mi lálẹ́ yí, èmi yíò kọ pé, “Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn abala tí ó ní ìmísí jùlọ ní èyíkéyìí ìpàdé gbogboògbò tí mo ti wà rí. Gbogbo nkan lọ nipa ti ẹ̀mí ati ìṣẹ̀dá tí ó tóbi jùlọ

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ọṣù mẹ́fà sẹ́hìn bí a ṣe wá papọ̀ ní ìpàdé gbogbògbò wa, ìyàwó mi tí ó ládùn, Frances, dùbúlẹ̀ sí ilé ìwòsàn, lẹ́hìn tí ó ti jẹ̀rora ìṣubú tí ó burú ní ọjọ́ díẹ̀ ṣaájú. Nínu oṣù karũn, lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ méló kan tí ó ti fi akíkanjú tiraka láti ṣẹ́gun àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó yọ̀ gẹ̀rẹ́ lọ sí ayérayé. Àdánù rẹ̀ jẹ́ jinlẹ̀. Òun àti èmí ṣe ìgbéyàwó ní Tẹ́mpìlì ti Salt Lake ní ọjọ́ kéje, oṣù kẹ́wá, ọdún 1948. Ọ̀la ni ìbá jẹ́ ayẹyẹ ìrántí ọgọ́ta ọdún ó lé márún ìgbeyàwó wa. Òun ni ìfẹ́ ayé mi, olùgbẹ́kẹ̀lé aláfẹ̀hìntì mi, àti ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ jùlọ. Láti sọ pé mo dárò rẹ̀ kò lè sọ ìjìnlẹ̀ ìmọ̀lára tí mo ní.

Ìpàdé yí ni ó sàmì àádọ́ta ọdún láti ìgbà tí a ti pè mí sí Àjọ Àwọn Àpọ́stélì Méjìlá lati ọwọ́ Ààrẹ David O.Mckay. Ní gbogbo awọn ọdún wọ̀nyí kò sí ìgbà kan tí mo ní ìmọ̀lára kankan jù àtìlẹhìn kíkún tí ó sì péye ti ẹnìkejì mi tí ó dùn. Àìníye ni àwọn ìyọ̀ọ̀da tí ó ṣe kí èmi lè ṣe ojúṣe ìpè mí. Èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìráhùn kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ rí bí mo ṣe máa ńfi ìgbà púpọ̀ lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ wa. O jẹ́ angẹ́lì, nítòótọ́.

Mo fẹ́ láti ṣe ọpẹ́ mi, pẹ̀lú ti àwọn ẹbí mi, fún títújáde ìfẹ́ tí ó pọ̀ èyí tí ó wá sọ́dọ̀ wa láti ìgbà tí Frances ti kọjá lọ. Ọgọgọ́rún àwọn káàdì àti lẹ́tà ni wọ́n firánṣẹ́ káakiri àgbáyé tí wọn ńsọ̀rọ̀ oríyìn fún un àti ìbákẹ́dùn sí ẹbí wa. A gba awọn dọ́sìnnì ètò òdòdó ẹlẹ́wà. A fi ìmoore hàn fún onírurú ìrànlọ́wọ́ èyí tí a fúnni lórúkọ rẹ̀ sí owó iṣẹ́ ìránṣẹ́ gbogbògbò ti Ìjọ. Ní orúkọ gbogbo àwa wọ̀nnì tí ó fisílẹ̀, mo fi ìmoore tí ó jìnlẹ̀ hàn fún inúrere àti ìsọ̀rọ̀ àtọkànwá yín.

Ohun tí ó jẹ́ ìtùnú sí mi jù ní àsìkò ẹ̀dùn ọkàn ìpinyà yí ni ẹ̀rí mi nípa ìhìnrere Jésù Krístì àti ìmọ̀ tí mo ní pé Frances mi ọ̀wọ̀n ṣì wà láàyè síbẹ̀. Mo mọ̀ pé fún ìgbà díẹ̀ ni ìpínyà wa. Wọ́n ti so wá pọ̀ nínú ilé Olúwa nípasẹ̀ ẹnìkan tí ó ní aṣẹ láti dì lórí ilẹ̀ ayé àti ní ọ̀run. Mo mọ̀ pé a ó ní ìdàpọ̀ lẹ́ẹ̀kansi ní ọjọ́ kan tí a kò sì ní pínyà mọ́ láéláé. Èyí jẹ́ ìmọ̀ tí ó ńṣè ìmúdúró fún mi.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ó le jẹ́ àìléwu lati rò pé kò sí ẹni tí ó tí gbé ìgbé ayé òmìnira rí pátápátá kúrò lọ́wọ́ ìkorò àti ìjìyà, tàbí njẹ́ a ti rí ìgbà kan nínú ìtàn ènìyàn tí kò ní ìpín kíkún ti ìrora àti ìrúkèrúdò tirẹ̀.

Nígbàtí ọ̀nà ayé bá gbé àyípadà burúkú wá, àdánwò máa ńwà láti bèèrè ìbéèrè “Kíló ṣe jẹ́ èmi?” Ní àwọn ìgbà míràn ó mã ń farahàn bíi pé kò sí ìmọ́lẹ̀ ní òpin ọ̀nà tí ó là, kò sí ìlà oòrùn láti parí òkùnkùn ti òru. Ìmọ̀lára mã ń yíwa ká nipa ìjákulẹ̀ awọn àlá tí kò wá sí ìmúṣẹ ati ìrẹ̀wẹ̀sì àwọn ìrètí tí ó di asán. A ńdarapọ̀ ní sísọ ẹ̀bẹ̀ ti inú bíbélì, “Ṣé kò sí ìkúnra kankan ní Gíléádì ni?”1 A ńní ìmọ̀lára ikọ̀sílẹ̀, ìrora ọkàn, dídáwà. A ní ìfẹ́ láti wo àwọn òfò ti ara wa nípa èrò ibi ti iyèméjì wa sí awọn nkan. A ńdi aláìnísùúrù fún ojútũ sí àwọn ìṣòro wa, ní ìgbàgbé pé léraléra ní a nílò ìwà sùúrù àtọ̀runwá.

Àwọn ìṣòro tí ó mã ńwá sí ọ̀dọ̀ wa mã ńgbé ìdánwò tòótọ́ nipa agbára wa láti ní ìfaradà wá sí iwájú wa. Ìbèèrè ìpilẹ̀sẹ̀ kan tí ìkọ̀ọ̀kan wa ní lati dáhùn ni: Njẹ́ èmi ó kọsẹ̀, tàbí èmi ó parí? Àwọn míràn ńkọsẹ̀ bí wọ́n ṣe ńrí ara wọn láìlè borí àwọn ìpèníjà wọn. Lati parí nĩ ṣe pẹlú fífaradà títí dé òpin ayé fúnra rẹ̀ gan an.

Bí a ṣe ńṣe àṣàrò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó lè ṣubú lu gbogbo wa, a lè sọ pẹ̀lú Jobù ìgbà àtijọ́, “A bí ènìyàn sínú ìdàmú.”2 Job jẹ́ “olóótọ́ àti ènìyàn pípé tí ó “bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì kóríra ibi.”3 Olódodo nínu ìwà rẹ̀, àṣeyege nínú ọlà rẹ̀, Job níláti dojúkọ ìdánwò kan èyí tí ó lè pa ẹnikẹ́ni run. Ó pàdánù gbogbo ohun ìní rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pẹ̀gàn rẹ̀, ó nírora nípa ìjìyà rẹ̀, ó níbànújẹ́ nípa pípàdánu ẹbí rẹ̀, ó ní ẹ̀dùn ọkàn láti “fi Ọlọ́run ré, kí ó sì kú.”4 Ó tàpá sí àdánwò yí, ó sì kéde láti ìsàlẹ̀ inú rẹ̀ tí a bíire:

“Kíyèsi, ẹ̀rí mi wà ní ọ̀run, àti pé àwọn àkọsílẹ̀ mi wà lókè.”5

“Mo mọ̀ pé Olùràpadà mi wà láàyè.”6

Jobù pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ mọ́. Njẹ́ àwa yíò ṣe bákannáà bí a ṣe ńdojúkọ àwọn ìpèníjà èyí tí yíò jẹ́ tiwa?

Ìgbàkugbà tí a bá nífẹ́ láti ní ìmọ̀lára àjàgà pẹ̀lú àwọn jàmbá ayé, ẹ jẹ́ kí a rántí pé àwọn míràn ti kọjá the ọ̀nà yí kannáà, wọ́n ti ní ìfaradà, àti pé nígbà náà wọ́n ṣẹ́gun.

Ìwé ìtan ti ìjọ nínú ìgbà ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àsìkò yi, kún pẹ̀lú ìrírí àwọn wọnnì tí ó ti tiraka àti pé síbẹ̀síbẹ̀ tí wọ́n sì dúróṣinṣin, tí wọ́n sì ní ọ̀yàyà rere. Ìdí rẹ̀? Wọ́n ti fi ìhìnrere ti Jésù Krístì ṣe ọ̀gangan ayé wọn. Èyí ni ohun tí yíò mú wa la ohunkóhun tí ó lè wá sí ọ̀nà wa já Síbẹ̀ a ó ṣì ní ìrírí ìṣòro àwọn ìpèníjà, ṣùgbọ́n a ó lè dojúkọ wọ́n, láti fi ìgboyà kòwọ́n lójú, àti láti jade bĩ aṣẹ́gun.

Láti ibùsùn ìrora, láti orí ìrọ̀rí tí ó tutu fún omijé, a gbé wa ga lọ sí ọ̀nà ọ́run nípa ìdánilójú àtọ̀runwá nã àti ìlérí iyebíye: “Èmi kò ní já ọ kulẹ̀, tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”7 Ìrú ìtùnú bẹ̃ jẹ́ àìdíyelé.

Bí mo ṣe ńrìnrìn àjò kákiri ní gbogbo àgbáyé ní mímú ojúṣe ìpè mi ṣẹ, mo ti wá mọ̀ àwọn ohun púpọ̀—èyí tí ó kéré jù ninu wọn kọ́ ni pé ìbànújẹ́ ati ìjìyà wà jákèjádò orí ilẹ̀ ayé. Èmi kò lè wọn gbogbo ọgbẹ́ ọkàn àti ìkorò tí mo ti jẹ́rí rẹ̀ bí mo ṣe ńṣè ìbẹ̀wò pẹ̀lú àwọn wọnnì tí nwọ́n ń bá ìbànújẹ́ yí, ń ní ìrírí àìsàn, ńdojúkọ ìpinyà ìgbeyàwó, ńtiraka pẹ̀lú ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí kò gbọràn, tàbí ńjìyà àyọrísí ti ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn àtòsílẹ̀ yí lè máa lọ síwájú àti síwájú si, nítorí àìníyé awọn ìdàmú ni ó wà èyí tí ó lè kọlù wá. Lati mú àpẹrẹ kan jáde ṣòro, àti pé síbẹ̀síbẹ̀ nígbàtí mo bá ronú nípa àwọn ìpèníjà, èrò ọkàn mi mã ń lọ sí ọdọ arákùnrin Brems, ìkan lára àwọn Olùkọ́ Ilé Ìwé ọjọ́ ìsinmi nígbà ọmọdékùnrin mi. Ó jẹ́ olóótọ́ ọmọ ìjọ kan, ọkùnrin kan pẹ̀lú ọkàn wúrà. Òun àti ìyàwó rẹ̀, Sadie, ní àwọn ọmọ mẹ́jọ, ọ̀pọ̀ lára wọn ni wọ́n jẹ́ ọjọ́ orí kannáà bí àwọn tinú ẹbí wa.

Lẹ́hìn tí Frances àti èmí ṣè ìgbéyàwó tí a sì kúrò ní ẹ̀ka náà, a mã ńrí Arákùnrin àti Arábìnrin Brems àti àwọn ọmọlẹ́bí wọn ní àwọn ìgbeyàwó àti ìsìnkú, bákannáà ní àwọn ìdàpọ̀ ẹ̀ka lẹ́hìn ìyapa díẹ̀.

Ní ọdún 1968 Arákùnrin Brems pàdánù ìyàwó rẹ̀, Sadie. Méjì lára àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́jọ tún kọjá lọ bákannã bí àwọn ọdún ṣe ńre kọjá.

Lọ́jọ́ kan ní bíi ọdún mẹ́tàlá sẹ́hìn, ọmọdébìnrin tí ó jẹ́ ọmọ ọmọ Arákùnrin Brems tí ó dàgbà jù pè mí lórí ẹ̀rọ tẹlẹfónù. Ó ṣe àlàyé pé bàbá bàbá rẹ̀ ti de ọgọ́ọ̀rún ọdun ó lé márun ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ó sọ pé, “Ó ńgbé ní ilé ìtọ́jú kékeré kan ṣùgbọ́n ó ńpàdé gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀ ní ọ́jọjọ́ ìsinmi, níbi tí ó ti ńfun wọn ní ẹ̀kọ́ ìhìnrere.” Ó tẹ̀síwájú, “Ní Ọjọ́ ìsinmi tí ó kọjá yí Bàbá bàbá náà kéde sí wa pé, ‘ẹ̀yin olólùfẹ́ mi, èmi yíò kú ní ọ̀sẹ̀ yí. Jọ̀wọ́ njẹ́ ẹ̀yin yíò ha pe Tommy Monson. Yíò mọ ohun tí yíò ṣe.”’

Mo bẹ Arákùnrin Brems wò ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tó tẹ̀le gan. Èmi kò tíì ri fún ìgbà díẹ̀. Emi kò lè ba sọ̀rọ̀, nítorí kò gbọ́ran mọ́. Emi kò lè kọ ọ̀rọ̀ kan fun láti kà, nítorí kò lè ríran mọ́. Mo gbọ́ pé àwọn ẹbí rẹ̀ máa ńba sọ̀rọ̀ nípa mímú ìka ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún àti pé nígbànáà wọn yíò tọ̀sẹ̀ rẹ̀ lórí àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ òsì láti kọ orúkọ ẹni tí ó ńṣe ìbẹ̀wò. Ọ̀nà yĩ kannáà ni wọ́n fi ńfun ní èyíkéyĩ ọ̀rọ̀. Mo tẹ̀lé ìṣísẹ̀ náà nípa mímú ọwọ́ rẹ̀ láti kọ orúkọ mi “TOMMY MONSON,” orúkọ èyí tí ó ti mọ̀ mí mọ́ nígbà gbogbo. Arákùnrin Brems dunní ó sì mú ọwọ́ mi mejẽjì ó gbé wọn lé orí rẹ̀. Mo mọ pé ìfẹ́ rẹ ni láti gba ìbùkún oyè àlùfáà. Awakọ̀ tí ó gbé mi lọ sí ile ìtọ́jú darapọ̀ mọ́ mi bí a ṣe gbé ọwọ́ wa le orí Arákùnrin Brems, a sì pèsè ìbùkún tí ó fẹ́ náà. Lẹ́hìnnáà, omi ńjáde nínú ojú rẹ̀ tí kò ríran. Ó di ọwọ́ wa mú ní ìmoore. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò gbọ́ ìbùkún tí a fún un, a ní ìmọ̀lára gidi, àti pé mo gbàgbọ́ pé ó ní ìmísí láti mọ̀ pé a ti pèsè ìbùkún èyí tí ó nílò. Arákùnrin tó ládùn yí kò lè ríran mọ́. Kò lè gbọ́ran mọ́. Wọ́n ńdée mọ́ yàrá kékeré kan ní ilé ìtọ́jú lóru àti lọ́sán. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀rín tí ó wà lójú rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ńsọ fi ọwọ́ tọ́ ọkàn mi. “O ṣéun,”ni ó sọ, Bàbá mi Ọ̀run ti dára sí mi gidi.”

Láárín ọ̀sẹ̀ kan, gẹ́gẹ́bí Arákùnrin Brems ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀, ó kọjá lọ. Kò ronú jù nípa ohun tí kò ní; dípò bẹ́ẹ̀, ó máa ńfi ìmoore tí ó jìnlẹ̀ hàn fún ọ̀pọ̀ àwọn ìbùkún rẹ̀.

Bàbá wa Ọ̀run, tí ó fúnwa ní ọ̀pọ̀ láti gbádùn, ti mọ̀ bákannáà pé à ńkẹ́kọ́ à sì ńdàgbà à sì ńdi alágbára nígbàtí à ńdojúkọ tí a sì ńyọ nínú àwọn ìdánwò inú èyí tí a gbọ́dọ̀ là kọjá. A mọ̀ pé àwọn ìgbà míràn wà nígbàtí a ó ní ìrírí ìkorò ẹ̀dùn ọkàn, nígbàtí a ó ní ìbànújẹ́, àti nígbàtí a lè ní àdánwò dé góńgó agbára wa. Bí o tilẹ̀ rí bẹ̃, irú àwọn ìṣòro yí ńfi àyè gbà wá láti yípadà fún rere, láti ṣe àtúnṣe ayé wa ní ọ̀nà tí Bàbá wa Ọ̀run kọ́ wa, àti láti di ohun kan ti ó yàtọ̀ kúrò ní ohun tí a jẹ́–dára ju bí a ti wà, ní òye ju bí a ti wà, ní àánú ju bí a ti wà, pẹ̀lú àwọn ìjẹ́rí tí ó ní agbára ju bí a ti ní tẹ́lẹ̀.

Èyí ni ó yẹ kó jẹ́ èrò wa–lati ní ìfaradà ati ìforítì, bẹẹni, ṣùgbọ́n bakannã kí a le di ẹni ẹ̀mí mímọ́ si, bí a ṣe ńgbé ní ìgbà rere àti búburú. Tí kìí bá ṣe ti àwọn ìpèníjà láti borí àti àwọn ìṣòro láti yanjú, a ó dúró bí a ṣe wà báyìí, pẹ̀lú ìlọsíwájú díẹ̀ tàbí kò má sí rárá ní sísúnmọ́ ètò wa ti ìyè ayérayé. Akéwì náà sọ̀rọ̀ púpọ̀ ní èrò kannáà ní àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí:

Igi dáradára kìí dàgbà pẹ̀lú ìrọ̀rùn,

Ìjì líle náà, àwọn igi tó lágbára jù.

Bí òfúrufú ṣe ga lókè, bẹ́ẹ̀ni gígùn rẹ̀ ṣe pọ̀ si tó.

Bí ìjì ṣe ńpọ̀ si, bẹ́ẹ̀ni agbára náà ńpọ̀si

Nípa òòrùn àti òtútù, nípa òjò àti yìnyín,

Nínú igi àti ènìyàn ni igi ńlá rere ńdàgbà.8

Olùgbàlà nìkan ni ó mọ ìjìnlẹ̀ awọn àdánwò wa, ìrora wa, àti ìjìyà wa. Òun nìkan ni ó lè fún wa ní àláfíà ayérayé ní àwọn ìgbà ìpọ́njú. Òun nìkan ni ó fọwọ́ kan inú wa tí a dálóró pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú Rẹ̀:

“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.

“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmí; ẹ̀yin ó sì ní ìsinmi.

“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”9

Bóyá ó jẹ́ ìgbà tó dára gan tàbí ìgbà tó burújù. Ó wà pẹ̀lú wa. Ó ti ṣèlérí fún wa pé èyí kò ní yípadà láyé.

Ẹ̀yin arákùbrin àti arábìnrin mi, njẹ́ kí a le ní ìfọkànsìn sí Bàbá wa ọ̀run ti kò le yòrò kí ó sì ṣàn lọ pẹlú awọn ọdún tàbí ìyọnu ilé ayé wa. A kò níláti ní ìrírí àwọn ìṣòro fún wa láti rántí Rẹ̀, àti pé a kò nilati fi ipá mú wa láti ní ìrẹ̀lẹ̀ ṣíwájú fífún Un ní ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé wa.

Njẹ́ kí a le fi ìgbà gbogbo gbìyànjú láti súnmọ́ Bàbá wa Ọ̀run. Láti ṣe bẹ̃, a gbọdọ̀ gbàdúrà sí I kí a sì fetísílẹ̀ sí I lójojúmọ́. A nílo Rẹ̀ nítòótọ́ ní gbogbo wákàtí, bóyá wọ́n jẹ́ wákàtí ti òòrùn tàbí ti òjò. Njẹ́ kí ìlérí Rẹ̀ jẹ́ atọ́nà wa: “Èmi kò ní já ọ kulẹ, tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”10

Pẹ̀lú gbogbo agbára ti inú mi, mo jẹ́rí pé Ọlọ́run wà láàyè àti pé Ó fẹ́ràn wa, pé Ọmọ bíbí Rẹ nìkanṣoṣo gbé ayé Ó sì kú fún wa, àti pé ìhìnrere ti Jésù Krístì ni orísun ìmọ́lẹ̀ tó ńfún wa ní ìrètí àti agbára tí ó ńrànwá lọ́wọ́ láti farada àwọn ìgbà ìṣòro tí ó jù nínú ayé wa. Njẹ́ kí ó rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ni mo gbàdúrà ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.