2013
Àwọn Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Fún Ìgbà Tiwa
November 2013


Àwọn Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Fún Ìgbà Tiwa

Àwọn Ẹ̀kọ́ fún Oyè àlùfáà Mẹlkisédẹ́kì àti Ẹgbẹ́ Arannilọ́wọ́ ní ọjọ́ ìsinmi kẹ́rin ni a ó yà sọ́tọ̀ sí “Àwọn Ẹ̀kọ́ Kíkọ́ Fún Ìgbà Tiwa.” A lè pèsè ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan láti inú ọ̀rọ̀ kan tàbí jù bẹ̃ lọ tí a fífúnni nínú ìpàdé gbogboògbò tí ó súnmọ́ jù (rí àpẹrẹ àwòrán ìsàlẹ̀) Àwọn ààrẹ èèkàn àti agbègbè lè yàn àwọn ọ̀rọ̀ sísọ èyí tí wọ́n nilati lò, tàbí wọ́n lè fi ojúṣe yí lé àwọn bíṣọ́ọ̀pù àti àwọn olùdarí ẹ̀ka lọ́wọ́. Àwọn Olórí tẹnumọ́ pàtàkì kí àwọn arákùnrin Oyè àlùfáà Mẹlkisédẹ́kì àti àwọn arábìnrin Ẹgbẹ́ Aranilọ́wọ́ kọ́ nipa àwọn ọ̀rọ̀ kannáà ní ọjọ́ ìsinmi kannáà.

Àwọn wọnnì tí wọ́n ńwá sí ẹ̀kọ́ ọjọ́ ìsinmi kẹ́rin ní a gbà níyànjú láti ṣe àṣàrò nínu àtẹ̀jáde ìwé ìròhìn ìpàdé gbogboògbò tí ó tuntun jùlọ àti láti mú un wá sí ilé ìkàwé.

Àwọn Àmọ̀ràn fún Mímúrasílẹ̀ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn Ọrọ̀.

Gbàdúrà pé kí Ẹ̀mí Mímọ́ wà pẹ̀lú rẹ bí o ṣe ńṣe àṣàrò tí o sì ńkọ́ni ní (àwọn) ọ̀rọ̀ náà. O lè gbìdánwò láti fẹ́ ṣe ìmúrasílẹ̀ ẹ̀kọ́ náà ní lílo àwọn ohun èlò míràn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ ti ìpàdé jẹ́ àwọn ìwé lílò tí a fọ́wọ́ sí. Iṣẹ́ tí a fi lé ọ lọ́wọ́ ni láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti gbé ìgbé ayé ìhìnrere bí a se kọ́ni ní ìpàdé gbogboògbò Ìjọ ti àìpẹ́ jùlọ.

ṣe àtúnyẹ̀wò (àwọn) ọ̀rọ̀ náà, ní wíwá àwọn ìpilẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ tí ó bá àìní àwọn ọmọ ilé ìkàwé mu. Bákannáà wá àwọn ìtàn, àwọn atọ́ka ìwé mímọ́, àti awọn àgbékalẹ̀ lati ínú (àwọn) ọ̀rọ̀ náà tí yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ lati kọ́ni ní àwọn òtítọ́ wọ̀nyí.

Ṣe ìlànà kan bí o ṣe lè kọ́ni ní àwọn ìpìlẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ náà. Gbèrò lati fi àwọn ìbèèrè tí yíò ran àwọn ọmọ ilé ìkàwé lọ́wọ́ sínú rẹ̀.

  • Wá àwọn ìpìlẹ̀ àti àwọn ẹ̀kọ́ nínú (àwọn) ọ̀rọ̀ sísọ náà.

  • Ronú nípa ìtumọ̀ wọn.

  • Ṣe àbápín òye, iyè inú, àwọn ìrírí, àti àwọn ẹ̀rí.

  • Lo àwọn ìpìlẹ̀ wọ̀nyí àti àwọn ẹ̀kọ́ nínú ìgbé ayé wọn.

À Nkọ́ni Ní àwọn Ẹ̀kọ́ Oṣõṣù

Àwọn Ohun Èlò Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi Kẹ́rin

Oṣù Kẹwã ọdún 2013–Oṣù Kẹrin Ọdun 2014

Àwọn ọ̀rọ̀ sísọ tí a fúnni ní ìpàdé gbogboògbò ní oṣù Kẹwã Ọdún 2013*

Oṣù Kẹrin Ọdun 2014– Oṣù Kẹwã ọdún 2014

Àwọn ọ̀rọ̀ tí a fúnni ní ìpàdé gbogboògbò ní oṣù kẹrin ọdún 2014*

  • Fún ẹ̀kọ́ ọjọ́ Ìsinmi kẹ́rin ti Oṣù Kẹ́rin àti Ìkẹ́wá, a lè ṣe àṣàyàn àwọn ọ̀rọ̀ láti inú ìpàdé gbogbògbò àtẹ̀hìnwá tàbí láti inú èyí tí ó súnmọ́ jùlọ. Àwọn ọ̀rọ̀ sísọ yí jẹ́ àrọ́wọ́tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ní conference.lds.org

Tẹ̀