Àwọn Ọmọdé
Àwọn Ìsopọ̀ ti Ìfẹ́
Jẹ́ kí àgbàlagbà kan ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gé ìwé ìlà tínrín méjìdínlọ́gbọ̀n síta, ìkọ̀ọ̀kan bíi ínṣì kan (kilómità méjì àti àbọ̀) gbígbòòrò àti bíi ínṣì mẹ́jọ (kilómítà ogún) gígùn. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní oṣù yí, ṣe ṣíṣe kan ti iṣẹ́ ìsìn láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn fún ẹnìkan. O lè ran àwọn òbí rẹ lọ́wọ́ láti fọ ilé yín mọ́ tàbí kọ ìwé inú rere kúkúrú kan sí aládúgbò kan.
Kọ sílẹ̀ bí ìwọ ṣe ńsìn ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lórí ìkan lára àwọn ìlà ìwé rẹ, àti pé nígbànáà kí o sópọ̀ tàbí lẹ̀ẹ́ mọ́ àwọn ìparí ti ìlà sísopọ̀ láti ṣe òbíríkítí kan. O lè so àwọn òbíríkítí rẹ papọ̀ nípa yíyọ́ ìparí ìkan ti ìlà ìwé tuntun nínú òbíríkítí kúrò ní ọjọ́ tó kọjá ṣíwájú kí o tó sópọ̀ tàbí lẹ̀ẹ́ mọ́ àwọn ìparí ìlà tuntun náà papọ̀. Wò bí àwọn ìsopọ̀ ìfẹ́ rẹ ṣe ńdàgbà! O lè tẹ̀síwájú pàápàá láti fikún ọ̀wọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ lẹ́hìn tí oṣù kejì bá parí.